Àwọn ọlọ́jà figbe ta ní ìpínlẹ̀ Ogun lẹ́yìn tí wọ́n dòwòpọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ayánilówó kan

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ńṣe ni ariwo gba ẹnu àwọn òǹtàjà kan ní agbègbè Lafenwa ní ìlú Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun nígbà tí wọ́n ké gbàǹjarè sí aráyé lórí àwọn kan tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé wọ́n fẹ́ lu àwọn ní jìbìtì.
Nínú fídíò kan tó wà lórí Facebook ni àwọn ìyá tí a kò lè sọ wí pé báyìí ni iye wọn ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan ló wá polówó ẹ̀yáwó sí àwọn.
Àwọn ìyá náà mú ìwé kan lọ́wọ́ èyí tó ní orúkọ iléeṣẹ́ tó ń pèsè ẹ̀yàwó náà fún wọn.
Orúkọ tó wà lórí ìwé náà gẹ́gẹ́ bí orúkọ iléeṣẹ́ ayánilówó náà ni Perennial Global Services Limited.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a gbọ́ nínú fídíò náà láti ẹnu ìyá ọlọ́jà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ajara Musa ní àwọn ènìyàn kan ló wá bá àwọn pé kí àwọn wá fún ẹ̀yàwó ní ilé iṣẹ́ àwọn.
'Nigba ti mo gbọ pe onijibiti ni wọn, mo lọ si ọfisi wọn ṣugbọn wọn ti ko lọ'
Ajara ní àwọn iléeṣẹ́ náà ní kí àwọn san ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìforúkọsílẹ̀ tí wọ́n sì ní kí àwọn kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ láti gba owó yíyá náà.
Ó ṣàlàyé pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà ni ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn dá fún àwọn iléeṣẹ́ ọ̀hún ṣùgbọ́n àwọn kò rí àbọ̀ owó tí wọ́n ní àwọn máa yá àwọn.
Ẹlòmíràn ní tirẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abosede Akiose ní àwọn mẹ́rin ni àwọn wà nínú ẹgbẹ́ àwọn tí oníkálùkù àwọn sì dá ẹgbẹ̀rún mọkàndínlọ́gọ́ta náírà (59,000).
Wọ́n ní àdéhùn tí iléeṣẹ́ náà ṣe fún àwọn ni pé àwọn máa yá àwọn ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba náírà láti fi ṣòwò àmọ́ ti wọn kò yá àwọn lówó kankan títí di àsìkò yìí.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
“Wọ́n gba #59,000 lọ́wọ́ ẹni kọ̀ọ̀kan wa, nínú ẹgbẹ́ àwa mẹ́rin, wọ́n ní àwọn fẹ́ fún wa ní #200,000.”
Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí ọ̀pọ̀ àwọn òǹtajà mìíràn ló tún fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí bí àwọn ènìyàn náà ṣe wá fi ẹ̀yàwò náà lọ àwọn.
“Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ márùn-ún sẹ́yìn ni wọ́n wá báwa pé àwọn fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ nípa yíyá wa lówó.”
“Wọ́n fún wa ní káàdì, wọ́n sì sọ wí pé láàrín ọjọ́ mẹ́ta sí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí a bá ti forúkọ sílẹ̀ ni a máa rí owó náà gbà.”
“Nígbà tí mo kó àwọn ènìyàn jọ, mó lọ ṣe ìwádìí ní ọ́fíìsì wọn láti lọ wo ibẹ̀ àti láti lọ bèèrè àwọn nǹkankan nípa wọn, tí wọ́n sì fún mi ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi kòdáibi tí wọ́n sọ wí pé olú iléeṣẹ́ àwọn wà ni mo mọ̀.”
“Nígbà tí mò ń gbọ́ awuyewuye pé oníjìbìtì ni wọ́n ni mo tún padà lọ sí iléeṣẹ́ náà ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá àmọ́ nígbà tó ma di ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìròyìn kàn mí lára pé wọ́n ti kó kúrò ní ọ́fíìsì wọn.”
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fòfin gbé àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Lára àwọn fídíò tó gba orí ayélujára Facebook tún ṣàfihàn bí àwọn ọlọ́pàá ṣe gbé lára àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ẹ̀yàwò náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ní nígbà tí àwọn rí fídíò àwọn ọlọ́jà Oke Itoku tí wọ́n figbe bọnu lórí ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ náà ni àgọ́ ọlọ́pàá Oke Itoku, Hadiza Abu Oganyi ní kí àwọn ọlọ́pàá tètè ló síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola fi léde ní ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé iléeṣẹ́ ayánilówó kan lórí ayélujára tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Legend Empowerment Services tí àwọn kò mọ̀ bóyá wọ́n forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìjọba ìyẹn CAC ló kó àwọn ènìyàn fétò ẹ̀yáwó.
Odutola ní ìròyìn tó tó àwọn létí ni pé iléeṣẹ́ náà ṣèlérí fún àwọn ènìyàn pé tí wọ́n bá san ẹgbẹ́run mẹ́jọ náirà àwọn máa yá wọn ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà.
Ó ní àwọn ọlọ́jà yìí kàn bẹ́ lu àwọn nǹkan tí wọ́n fi lọ̀ wọ́n yìí láì ṣèwádìí láti mọ̀ bóyá iléeṣẹ́ náà fìdí múlẹ̀ tàbí oníjìbìtì ni wọ́n.
‘Ọwọ ti tẹ meji ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa’
Ó ṣàlàyé pé àwọn méjì nínú àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà ló ti wà ní àhámọ́ àwọn tí àwọn sì ti ń fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.
“Adedayo Omolola tó ti ń bá iléeṣẹ́ Legend Empowerment Services ṣiṣẹ́ láti bí oṣù méjì sẹ́yìn àti Adedayo Tosin tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́sẹ̀ méjì ló ti wà ní àgọ́ wa.”
“Wọ́n ṣàlàyé pé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni wọ́n ní owó ti àwọn ọlọ́jà náà máa gbà ma tó wà nílẹ̀.”
Odutola fi kun pé àwọn gbìyànjú láti kàn sí ẹni tó ni iléeṣẹ́ náà, Lawal Akinwale lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àmọ́ nọ́mbà rẹ̀ kò lọ.
Ó tẹ̀síwájú pé ní kété tí àwọn bá ti rí ibi kàn síi ni àwọn yóò pé sí àgọ́ ọlọ́pàá láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun láti joye ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, kí wọ́n ri dájú pé àwọn kò bọ́ sọ́wọ́ àwọn oníjìbìtì ẹ̀dá níbi tí wọ́n bá ti ń wá ẹ̀yàwó.
Ó fi kun pé gbogbo agbára àwọn ni àwọn máa sà láti tú ìṣẹ̀lẹ̀ náà dé ìsàlẹ̀ kòkò.












