Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti ráńṣẹ́ pe Trinity Guy! "Ohun táa fẹ́ bi í léèrè nìyí"

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Fidio itanjẹ "prank" kan ti ko gbajugbaja apanilẹrin, Abdullahi Maruf si wahala bayii ti ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo si ti fi iwe pe e.
Ninu atẹjade kan loju opo ayelujara ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, wọn ni awọn ti kan si Abdullahi Maruf Adisa pe ko farahan ni ọfiisi awọn.
Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, SP Osifeso Adewale jẹ ko di mimọ pe ki awọn araalu ma ṣi awọn gbọ rara pe kii ṣe pe awọn fẹ ko ibọn ati kumọ lati fi lọ mu u biko ṣe pe ipe ni awọn pe gbajugbaja apanilẹrin naa.
O ṣalaye wipe ko wa wi tẹnu rẹ ni lori ẹsun to lọ mọ fidio kan to gbe jade ninu eyi to ti n bi ọmọde obinrin kan leere awọn ibeere to nii ṣe pẹlu ibalopọ ati nnkan ọmọkunrin eyi to fihan pe o n fi ilọkulọ ibalopọ lọ ọmọde eyi to si lodi si ofin ilẹ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Oyo Police/Twitter
Osifeso sọ fun BBC Yoruba pe: "Awọn eeyan n beere ibeere pe ki ni Ọlọpaa n ṣe yii amọ a ni ẹtọ lati ṣe e"
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo naa ni iṣẹ awọn ni awọn n ṣe tori “a pe Trinity Guy pe ko wa fi ẹnu ara rẹ ṣe alaye awọn nnkan to wa ninu fidio to fi sita yẹn ti ọdọmọbinrin kan ti ọjọ ori rẹ ko tiito ọdun mejidilogun wa ninu rẹ.
A ni gbogbo ẹtọ ati ojuṣe lati da afbo bo ọmọ kekere yẹn bẹẹ si ni awọn eeyan n beere pe ki ni a n ṣe gẹgẹ bi ọlọpaa.”
Osifeso tun sọ pe ohun ti awọn ṣe jẹ ohun to yẹ to si wa labẹ ofin torinaa ki awọn eeyan ma foju pe awọn fẹ fipa ti ọrọ jade lẹnu rẹ tabi fiya jẹ ẹ ni akoko yii.
Ṣe gbogbo fidio Trinity Guy lo lodi si ofin ni ti Ọlọpaa fi n pe e?
Agbẹnusọ ọlọpaa Osifeso sọ pe ni ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, ọrọ ti agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria sọ lawọn n tọ ipasẹ rẹ eyi to si nii ṣe pẹlu
“Iwadii yii ko tii kan gbogbo fidio Trinity Guy to ku bi ko ṣe eyi ti ọmọde wa ninu rẹ na bayii ni a fẹ beere ibeere lọwọ rẹ.
A fẹ mọ ọjọ ori ọmọdebinrin yẹn bo tilẹ jẹ pe o han gbangba ninu fidio naa pe ọmọ yẹn ko tii balaga tori naa bo ṣe n ṣe gbogbo fidio rẹ kọ lo kan wa lọwọ yii bi ko ṣe pe bo ṣe ṣi ọmọde sita gbangba lori ayelujara pẹlu awọn ibeere nipa ibalopọ ati nnkan ọmọkunrin.
Ki lo de ti ọlọpaa ko ka ẹbẹ Trinity Guy sí?
Agbẹnusọ ọlọpaa ni asiko ti adẹrinpoṣonu naa gbe fidio ẹbẹ rẹ naa jade ko tọ rara.
“A ti baba fi ipe ranṣẹ sii pe ko wa wi tẹnu rẹ. O ṣeeṣe ko jẹ pe akoko tabi wakati perete lẹyin ti ipe wa de ọdọ rẹ lo sare ṣe fidio ẹbẹ sita.
Amọ sibẹ sibẹ, ipe taa pe e ṣi duro digbi, o ṣi ni lati wa wi tẹnu rẹ”.
Ọlọpaa ni awọn eeyan n beere ibeere wọn si ni ẹtọ lati mọ ohun to ṣe ati pe “eyi yoo fa awọn to ba n gbero lati tọ ipasẹ rẹ leti pe ki wọn ṣọra tori ọna pọ gan lati pa eeyan lẹrin bi ẹnikẹni ba fẹ ṣe e amọ wọn o nilo lati maa ko ọrọ nipa ibalopọ rọ ọmọde lara tori pe wọn fẹ ṣe fidio jade”.
Trinity Guy f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí agbẹnusọ Ọlọ́pàá Muyiwa Adejobi lórí iṣẹ́ “pranks” tó ń ṣe

Gbajugbaja apanilẹrin ti ọpọlọpọ fẹran lati maa wo fidio rẹ, Abdullahi Maruf ti ọpọlọpọ mọ si “Trinity Guy ti fesi si ọrọ ti agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi sọ pe o yẹ ki ọlọpaa lọ fi ofin gbe e tori pe ọpọlọpọ fidio rẹ ninu eyi to ti maa n tan awọn eeyan jẹ lo n ṣe akoba fun ọpọlọpọ.
Bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ọpọ eeyan gba pe awọn itanjẹ rẹ ọhun maa n dun awọn eeyan to si le ṣakoba fun ẹlomiran, ṣugbọn eyi ko ni ki awọn eeyan ma maa wo fidio rẹ ti wọn yoo si maa kan sara sii fun iṣẹ takuntakun.
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ “Bàbá mi” Ọ̀gá Ọ́lọ́pàá Muyiwa Adejobi fún ipa tí wọ́n kó ‘lórí iṣẹ́ mi”.
Trinity Guy kọkọ yẹ awọn ololufẹ rẹ si to si ni oun mọ riri ifẹ ti wọn ni si oun ati iṣẹ to n ṣe.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Nidi iṣẹ apanilẹrin yii ni Trinity guy ti di gbajumọ to si ti n ri owo.
Ẹwẹ, ninu fidio to fi si oju opo ayelujara rẹ, Trinity Guy ni: “ Mo fi fi anfani yii dupẹ lọwọ gbogbo eniyan to ti n pe mi lati fi ifẹ han si awọn nkankan ti awọn eeyan ṣi mi gbọ le lori nipa iṣẹ mi ati iru eeyan ti mo jẹ”.
Trinity Guy ni oun dupẹ lọwọ ileeṣẹ ọlọpa Naijiria “paapaa julọ baba mi, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejobi” fun ipa ti wọn n ko gẹgẹ bii baba lori mi fun bi wọn ṣe pe akiyesi mi si awọn apa ibi kan ninu iṣẹ mi ti mo ni lati ṣiṣẹ le lori fun atunṣe.
O ni akitiyan agbẹnusọ Ọlọpaa, Muyiwa Adejobi lati daabo bo araalu jẹ iwuri lọpọlọpọ oun si dupẹ lọwọ rẹ gidi gan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















