Mathew Akintunde one-handed artiste: Bí mo ṣe ń rí ẹsẹ̀ mi lò fi rọ́pò ọwọ́ kan tí kò sí mọ́ rèé

Àkọlé fídíò, Ẹsẹ̀ mi ni mo fi ń rọ́pò ọwọ́ mi tí kò sí mọ́ bí mo bá fẹ́ ya àwòrán – Akintunde ayàwòrán

Gbajumọ oniṣẹọna ayaworan ni Ọgbẹni Mathew Akintunde ni ilu Ilọrin.

Lati kekere lo ni oun ti ko ijamba to sọ oun di ẹni ti ko ni ri ọwọ meji lo laye mọ, lẹyin ti apoti ikonkanpamọ si kan re lu oun lọwọ mọlẹ.

Amọṣa, Akintunde ko jẹ ki eyi da omi tutu si ọkan rẹ lati de ibi ti ọkan rẹ fẹ.

O ni pẹlu ipenija yi ni oun ṣi fi ni igboya lati ṣalaye fun Baba oun pe iṣẹ ọna yiya aworan loun fẹ kọ jẹun.

O ni gbogbo oun to ba yẹ ki oun lo ọwọ mejeeji mu dani loun maa n lo ẹsẹ fi ṣe dipo ọwọ oun keji ti ko si mọ.

O ni nnkan ko rọrun fun oun lẹnu iṣẹ naa nitori atapata dide loun.

O wa rọ awọn akanda ẹda pe ko si bi nnkan ṣe le le to, sibẹ ki wọn tẹpa mọ iṣẹ nitori pe bo pẹ bo ya, ọna yoo la.