Damilola Adeparusi: N kò bá Hilda Baci ta kàngbọ̀n tàbí díje fún Guinness World Records
Ni aipẹ yii ni ariwo gbode nipa ọmọge kan, Hilda Baci to wa se ounjẹ fun ọgọrun wakati lai dawọ duro nilu Eko, eyi ti okiki rẹ gbalẹ kan.
Afojusun ọmọbinrin naa ni lati gba ami ẹyẹ ẹni to le dana julọ fun ọpọlọpọ wakati jakejado agbaye eyi ti ẹgbẹ Guinness World Records n se agbatẹru rẹ.
Lọjọ Isẹgun,ọjọ Kẹtala osu Kẹfa ọdun 2023 si ni ajọ Guinness World Records kede pe Hilda Baci yii lo gba ami ẹyẹ bii ẹni akọkọ to le dana fun ọpọ wakati lagbaye.
- Ìdùnnú subú lu ayọ̀ ní Ekiti, Damilola se oúnjẹ fún ọgọ́fà wákàtí látí gba àmì ẹ̀yẹ
- Wo ipa tí áṣẹ CBN fún àwọn báńkì olókoòwò láti ta dọ́là ní iye tó wù wọ́n yóò ní lórí rẹ
- -Ọmọbìnrin mi mẹ́ta tí wọn kò ní pẹ́ lọ sílé ọkọ ló bómi lọ ní Kwara-
- Agura tí Gbagura wàjà, Ọba AbdulSabur Bakare dara pọ̀ máwọn baba ńlá rẹ̀
- Wo ìdí tí DSS ṣe gbé ọ̀gá àgbà EFCC tẹ́lẹ̀ sí àhámọ̀
Lẹyin eyi ni ọmọbinrin mii, Damilola Adeparusi, naa tun kede pe oun le dana ju ọgọrun wakati lọ, ti oun si le se ounjẹ fun wakati ọgọfa, eyi to n se araye ni haa-hin.
Fun odidi ọjọ marun ni Damilola fi se ounjẹ naa lai dawọ duro, to si pari ase naa ni owurọ Ọjọru, ọjọ kẹrinla osu Kfa ọdun 2023.
Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ ọmọbinrin naa lọ nilu Ilupeju Ekiti lati mọ idi to gba fi koja, awọn afojusun rẹ ati ọpọ ipenija pẹlu iwuri to ni lasiko isẹlẹ naa.
- Ìjọba àpapọ̀ díde ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó fara gbá nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi Kwara
- Èèyàn 160 ni agbébọn ti pa lásìkò ìjọba Tinubu, èyí burú jáì - Amnesty
- K1 rawọ́ ẹ̀bẹ́ ránṣẹ́ sí Tinubu lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ninalowo kópa nínú fíìmù Amẹ́ríkà, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kan sárá síi
- 'Àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó mi, tí a jọ ṣe ‘Hook Up’ rí, ló ń gbà á nímọ̀ràn láti kọ̀ mí sílẹ̀'
"N ko ba Hilda Baci ta kangbọn lati dije, mo fẹ tẹ awọn ololufẹ mi lọrun ni"
Nigba to n sọrọ, Damilola ni oun ko ni lero rara lati ta kangbọn pẹlu Hilda Baci nidi gbigba ami ẹyẹ ẹni akọkọ to le da ina julọ fun ọpọ wakati.
"Akẹkọọ fasiti ni mi, ẹgbẹ ti mo si wa nile ẹkọ la ti maa n se ounjẹ fun ọpọ wakati.
N ko ni lero lati dije fun Guinness World Recordski n le gba ami ẹyẹ ẹni to le dana fun igba pipẹ lọwọ Hilda Baci.
Mo ti maa n kopa ninu iru idije bayii tẹlẹ, o ti mọ mi lara, ohun to si maa n mu inu mi dun ni ounjẹ sise.
Mo fẹ tẹ awọn ololufẹ mi lọrun, ni mo se pese ounjẹ sise naa fun wakati ọgọfa gbako."
Bakan naa ni Damilola Adeparusi mẹnuba awọn ọna to gba ri iranwọ nipa ounjẹ sise naa, awọn iwuri pẹlu ipenija to ba pade fun BBC Yoruba.



