Àwọn Alfa sìnkú Ọba Gbagura nílànà ẹ̀sìn Islam, lẹ́yìn táwọn Aláwo ṣe ètùtù wọn

Isinku Agura

Ètò ìsìnkú ọba Abdul Sabur Bakare Jamolu keji, Agura tí ìlú Gbagura ni Abẹ́òkúta ipinlẹ Ógùn, tí wáyé ní ìlànà ẹṣin Mùsùlùmí ni ilé mọ́lẹ̀bi kabiyesi tí ó wà ní crown Royal Abiola way Abẹ́òkúta.

Owurọ Ọjọbọ ni Kabiyesi mi kanlẹ, to si dara pọ mawọn baba nla rẹ.

Saaju ni wọ́n gbé òkú ọba Abdul Sabur Bakare, Jamolu keji, Agura tí ìlú Gbagura lọ sí ilé mọ́lẹ̀bi rẹ tí ó wà ní crown Royal Abiola way, Abẹ́òkúta fún ìsìnkú ni ìlànà ẹṣin Mùsùlùmí.

Awọn aláwo si lo tí ṣeto ìsìnkú rẹ lowurọ oni ni afin Gbagura tí ó wà ní Ido Gbagura Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògún.

Lẹyin eyi ni awọn musulumi to tẹwọgba oku rẹ lati kirun si lara, ki wọn to sin.

Awọn olubanikẹdun

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pàtàkì ni ìlú Ẹ̀gbá, àwọn asoju ijoba, àwọn ọdọ àti oloye kàkàkí ilẹ Naijiria ni wọ́n peju lati kẹ́dùn iku ọba Gbagura kẹsàn-án, tí ó papoda náà.

Akọwe ìjọba ipinlẹ ogún, Tokunbo Talabi tí ó sójú gomina ipinlẹ Ogun àti ikọ ìjọba pẹlu awọn eniyan pàtàkì míì lorilẹ-ede Nàìjíríà, ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fún kabiyesi Agura tí Gbagura to gbesẹ yìí.

Ẹgbẹ́ itẹ òkú Baba kabiyesi, ìyẹn adajo Bakir ni wọ́n sìn ọba Abdul Sabur Bakare sì lẹ́yìn tí àwọn àgbà Mùsùlùmí nílẹ̀ Gbagura tí kirun sì òkú ọba náà tán.

Lowuro kùtùkùtù òní ni ìròyìn iku ọba náà jáde láti ẹnu ọkan lára oloye ilu Gbagura, tí ó tún jẹ́ Balógun ira Gbagura, Nurudeen Olaleye.

Asoju ijọba n kẹdun iku ọba

Akoroyin BBC news Yoruba ti o sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọkàn lára àwọn aláwò ìlú Gbagura jẹ́ kí ó di mimo pé, ẹtọ àwọn aláwò ìlú Gbagura ni lati kọ́kọ́ ṣe ìlànà oro ìsìnkú ọba náà láàfin.

O ni lẹyin eyi ni wọ́n yọnda òkú ọba náà fún àwọn mọ́lẹ̀bi rẹ láti lọ sìn ní ìlànà ẹṣin Mùsùlùmí tí ọba náà ń sìn nígbà tí ó wà láàyè.

Àkọlé fídíò, Damilola Adeparusi: N kò bá Hilda Baci ta kàngbọ̀n tàbí díje fún Guinness World Records

Agura tí Gbagura wàjà, Ọba AbdulSabur Bakare dara pọ̀ máwọn baba ńlá rẹ̀

Aworan

Kabiyesi, ọba Agura Gbagura, Ọba Abdul Sabur Bakare, Jamolu 11, ti jáde láyé.

Owurọ oni ọjọbọ ni oriade naa rewalẹ asa lẹ́yìn àìsàn ranpẹ nile ìwòsàn kan ni ilu Eko.

Gégé bí Balógun ira Gbagura, Nurudeen Olaleye ṣe fi to Akoroyin BBC Yoruba létí, nígbà tí ó ń ṣe iforowanilenuwo lórí àgó, Balógun Nurudeen Olaleye ni, ọba náà gbesẹ lowuro kùtùkùtù òní, lẹ́yìn àìsàn ranpe diẹ.

Ọba Abdul Sabur Bakare, Jamolu kejì lo gbade ni Ọjọ́ kẹjọ, Oṣù kẹjọ, ọdún 2019 gẹ́gẹ́ bí Jamolu II, Agura Gbagura.

Inú oṣù kẹjọ ọdún yìí ni yóò ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ibi ọdún 65

Wayii o, eto ìsìnkú ọba ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ni ààfin Agura Gbagura tí ó wà ní òkè ido n'ilu Abẹ́òkúta.

Akoroyin BBC news Yoruba rí gbọ pé, ó ṣeeṣe kí eto ìsìnkú ọba náà wáyé lowurọ yìí ni ìlànà ẹṣin Mùsùlùmí.

Àwọn aṣojú ọba lorigun mẹrẹẹrin ìlú Ẹ̀gbá àti agbegbe rẹ ni wọn ti wa ń ṣe ibakẹdun sì afin ọba náà.

Bakan naa ni àwọn ará ìlú, ọmọdé àti àgbà pẹlu awon eniyan pàtàkì pàtàkì ni ìlú Ẹ̀gbá tí ń wọ afin láti ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fún kabiyesi Agura tí Gbagura, ọba Abdul Sabur Bakare, Jamolu kejì.