Wo ìdí tí DSS ṣe gbé ọ̀gá àgbà EFCC tẹ́lẹ̀ sí àhámọ̀

Oríṣun àwòrán, Collage
Alága àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu, EFCC, Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìyẹn DSS.
Lẹ́yìn tí Ààrẹ Tinubu fọwọ́ òsì ilé júwe fún Bawa ni DSS ránṣẹ́ pè é láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.
Ìròyìn ní alẹ́ pátápátá lọ́jọ́rú ni Bawa balẹ̀ sí àgọ́ àwọn DSS náà.
Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya, nínú àtẹ̀jáde kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bawa ti wà ní àhámọ́ àjọ àwọn.
Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ti ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Bawa lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
"DSS ti ránṣẹ́ pé alága EFCC tí Ààrẹ ní kó lọ rọ́kún nílé."
"Bawa ti wà ní àgọ́ wa báyìí, àwọn nnkan tí a torí rẹ̀ pe Bawa kò ṣẹ̀yìn àwọn ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ nípa rẹ̀." Afunanya sọ nínú àtẹ̀jáde náà.
Tinubu fọwọ́ òsì júwe ilé fún alága EFCC, Abdulrasheed Bawa
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn EFCC, Abdulrasheed Bawa.
Tinubu ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé fún àìní gbèdéke ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ààrẹ ní nítorí à ti fún àwọn tó ń ṣe ìwádìí Bawa láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni òun fi ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lọ́kan-ò-jọ̀kan, èyí tó lágbára kan Bawa.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbenusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní Ààrẹ ní kí Bawa kó gbogbo àkóso àjọ náà lé adarí ètò gbogbo lọ́wọ́ títí tí wọ́n máa fi parí ìwádìí Bawa.

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ta ni Abdulrasheed Bawa?
Abdulrasheed Bawa ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí wọ́n máa yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC láti ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀ lọ́dún 2003.
Ọmọ ogójì ọdún ni Bawa wà nígbà tó fi máa gba ipò náà nínú oṣù Keje ọdún 2020 lẹ́yìn tí Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari yọ Ibrahim Magu lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.
Láti ọdún 2005 ni Bawa ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ́físà ní EFCC.
Òun ni ó ṣe ìwádìí ẹ̀sùn màkàrúrù owó tabua tí wọ́n fi kan Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ epo rọ̀bì, Diezani Alison-Madueke.
Ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, kó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.















