Ninalowo kópa nínú fíìmù ilẹ̀ òkèrè, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kan sárá síi

Oríṣun àwòrán, Ninalowo
Ọpọ awọn ololufẹ oṣere tiata Yoruba, Bolanle Ninalowo, lo ti bẹrẹ si n kan sara si bayii fun ipa to ko ninu fiimu kan to jade nilẹ Amẹrika.
Awọn ọhun ni ohun iwuri lo jẹ fun awọn pe oṣere tiata Yoruba ọhun ko ipa to jọju ni fiimu Hollywood.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii ni fiimu naa yoo di agbelewo amọ oniruru ipolongo fiimu ọhun lo ti n milẹ titi lori ayelujara.
Ninalowo, ti apẹle rẹ n jẹ Makanaki ti fi awọn fidio kan sita loju opo instagram rẹ, nibi to ti ṣafihan asiko ti wọn n ya fiimu naa.
Makanaki sọ pe inu oun dun gidi lati jẹ ọkan lara awọn to kopa ninu fiimu ọhun.
O ni “Inu mi dun lati kopa ninu fiimu yii.”
“Ọpọ faaji ni a ṣe lasiko ti awọn ololufẹ fiimu naa wa pade awọn oṣere to kopa ninu rẹ.”
Ta ni Bolanle Ninalowo?
Ninalowo jẹ ọkan pataki lara awọn oṣere tiata Yoruba ti awọn araalu fẹran, o si gbajumọ fun bo ṣe maa n sọ ede Gẹẹsi ninu fiimu.
Ilu Chicago, ni Illinois, nilẹ Amẹrika ni makanaki gbe fun nnkan bii ọdun marundinlogun ko to pada wa si Naijiria.
Ọdun 2010 ni Ninanlowo kọkọ kopa ni nu fimu ko to ilu mọọka oṣere.
O kopa ninu oniruru fiimu Yoruba ki irawọ to bẹrẹ si n tan lọdun 2014.
Lara awọn fiimu ti Ninalowo ti kopa ni Oko Bange, Iran mi, Iyawo, Ale, Ojo nbo apa kinni ati apa keji, The Man is Mine, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












