Trump tún fojú ba ilé ẹjọ́, ó le ojú koko láì le fọhùn

Donald Trump

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump tún kojú ìgbẹ́jọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn.

Ìgbà kejì rèé tí Trump yóò máa fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tó kúrò nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Amẹ́ríkà.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Trump lọ́tẹ̀ yìí ni pé ó kó àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ìjọba sí ìkáwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó ti kúrò nípò.

Wọn kò fi ààyè gba ìlò fóònù, ẹ̀rọ alágbèéká kọ̀m̀pútà àti ẹ̀rọ ayàwòrán ní ilé ẹjọ́ lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ náà fi ń wáyé.

Donald Trump

Adájọ́ gba pé kí Trump máa jẹ́jọ́ láti ilé, tó sì le rìnrìn àjò lọ sí ibi tó bá wù

Trump, pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn ṣe mọ wí pé ó máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa, kọ̀ láti sọ ohunkóhun fún gbogbo bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe wáyé.

Ọ̀kan nínú àwọn agbejọ́rò rẹ̀, Todd Blanche ní àwọn máa ṣàfihàn pé Trump kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.

Trump àti Waltine Nauta, tó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ fẹ̀sùn kàn ni wọ́n jọ jókòó sí ibi kan náà.

Ní nǹkan bí aago mẹ́ta kú ìṣẹ́jú márùn-ún ni ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Adájọ́ Jonathan Goodman wọ ilé ẹjọ́.

Adájọ́ náà gba pé kí Trump àti Nauta máa jẹ́jọ́ láti ilé, tí wọn kò si fi òfin dè wọ́n láti máṣe ìrìnàjò lọ sí ibi tó bá wù wọ́n.

Ilé ẹjọ́ ní ó ṣeéṣe kí àwọn fi òfin de Trump láti máṣe bá àwọn ẹlẹ́rìí tó wà níwájú ilé ẹjọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ náà títí ẹjọ́ fi máa parí.

Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí, Donald Trump tún ń kojú ẹ̀sùn méje mìíràn

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, THE WASHINGTON POST

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump tún ti ń kojú àwọn ẹ̀sùn mìíràn wí pé ó ń tọwọ́bọ àwọn ìwé tó jẹ́ ti ìlú lẹ́yìn tó kúrò nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Ẹ̀sùn méje ni Trump ń kojú èyí tó dá lórí kíkó àwọn ìwé tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè rẹ̀ sọ́wọ́ lẹ́yìn tó ti kúrò ní ìjọba.

Igbákejì rèé tí Trump ń kojú ìgbẹ́jọ́ lẹ́yìn tó kúrò nípò, tó sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Ààrẹ Amẹ́ríkà yóò máa kojú ìgbẹ́jọ́ lẹ́yìn tí sáà wọn bá parí.

Tí Trump bá fi lè jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Trump tún ti ń ṣe ìpolongo láti tún díje du Ààrẹ Amẹ́ríkà lọ́dún 2024.

Àwọn onímọ̀ òfin ní àwọn ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn Trump kò lè ṣe ìdádúrò láti díje dupò Ààrẹ.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnì Truth Social, Trump ní òun kò ní jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà àti pé wọ́n ti ránṣẹ́ sí òun láti yọjú sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀ ní Miami, Florida níbi tí ìgbẹ́jọ́ náà yóò ti wáyé.

Ó kọ sójú òpó náà pé òun kò gbàgbọ́ pé irú nǹkan báyìí le máa wáyé sí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Amẹ́ríkà.

Agbejọ́rò Trump, Jim Trusty sọ fún CNN Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà ti rí ìwé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, tó sì ti kà gbogbo rẹ̀.

Ó ní ara àwọn nǹkan tí wọ́n kọ síbẹ̀ jẹ́ ìlẹ̀dí àpòpọ̀, ọ̀rọ̀ irọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ẹ̀ka ètò ìdájọ́ kọ̀ láti sọ ohunkóhun tí wọ́n kò sì tíì fi àwọn ẹ̀sùn náà léde.

Olùpẹjọ́, Jack Smith ní gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú òun ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò láti ìgbà tí wọ́n ti yan òun bíi agbejọ́rò àgbà fún Merrick Garland nínú kọkànlá.

Ó lòdì sí òfin Amẹ́ríkà kí òṣìṣẹ́ Amẹ́ríkà, tó fi mọ́ Ààrẹ láti fi àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ìjọba sí ìkáwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nípò.