Kí ló mú ayàwòrán ẹ̀ni ọdún 31 pokùn so nínú yàrá rẹ̀ ?Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to de eti igbọ wa lati ipinlẹ Jigawa sọ pe wọn ti ba oku arakunrin kan to pokun so ninu yara rẹ nilu Babura.
Awọn araadugbo ati mọlẹbi rẹ n ṣe eemọ idi ti nkan bayii fi ṣẹlẹ si ẹni ọdun mọkanlelọgbọn Usman Sani to jẹ ayaworan.
Agbẹnusọ ọlọpaa DSP Lawal Shi'isu fidi ọrọ naa mulẹ to si ni ''lootọ ni a ri oku arakunrin kan ẹni ọdun mọkanlelọgbọn to pokun so sinu iyara rẹ''
Lawal Adam sọ pe iwadii ibẹrẹ tawọn ṣi ṣe tọka si pe o ṣeeṣe ki arakunrin naa gbẹmi ara rẹ ni nitori awọn ko tii ri apẹrẹ pe eeyan kankan lọwọ ninu iku rẹ.
Awọn agbofinro lawọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to le mu arakunrin yi hu iruiwa bẹẹ.
Bẹẹ naa lawọn araadugbo n sọ ero ọkan wọn lori iṣẹlẹ yi.
Bawọn kan ṣe n sọ pe o dabi pe arakunrin naa ni ipenija aarun ọpọlọ lawọn mọlẹbi sọ pe ko si nkankan to ṣe Usman.
Iwadii wa fi han pe Usman ni iyawo ti iyawo rẹ si loyun sinu.
Koda oyun naa ti n sunmọ ibi bayii.
Iṣẹlẹ aburu yi ti sọ mọlẹbi ati awọn araaddugbo sinu ibanujẹ ohun iporuru ọkan.
Iwadii tawọn kan gbe jade lori iroyin iṣẹlẹ iṣekuparaẹni ti awọn iwe iroyin gbe jade ni Naijiria ṣafihan pe laarin 2010 si 2019 iroyin eeyan 350 to ṣeku pa ara wọn ni wọn gbe jade.
O ṣeeṣe ki iye eeyan yi ju bayi lọ nitori awọn mii le maa de ori afẹfẹ.
Ida 80.6% ninu awọn to ṣeku pa ara wọn lasiko akojọpọ iroyin yi jẹ ọkunrin tawọn to ti lọkọ tabi iyawo ninu wọn si jẹ ida 51.8%.
Awọn to pokunso ninu wọn jẹ ida 48.6% tawọn to si gbe manjele jẹ si jẹ ida 32.2%.















