Ṣé bó ṣe yẹ kí ọmọlúàbí Yorùbá tọrọ àforíjìn ní Aregbesola tọrọ àforíjìn rẹ̀? -Agbẹnusọ Oyetola

Aworan Gomina tẹlẹ ri Isiaka Oyetola ati Rauf Aregbesola

Gbolohun aforijin ti Minisita fọrọ abẹle tẹlẹ loun tọrọ lasiko to n ba awọn alatilẹyin sọrọ ni ilu Osogbo ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Bi awọn kan ti ṣe n gboriyin fun un pe o fi pana aawọ lawọn mii ni aforijin ti ko denu ọkan rẹ ni.

Lara awọn to fesi lori ọrọ yii taa ba sọrọ ni agbẹnusọ Gomina ana nipinlẹ Osun arakunrin Ismail Omipidan.

Omipidan sọ pe Gomina ana Gboyega Oyetola ko ni ija kankan pẹlu Rauf Aregbesola ṣugbọn o ni aforijin to tọrọ kii ṣe bi ogidi ọmọ Yoruba ṣe yẹ ko tọrọ aforijin.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lori ago ipe, Omipidan sọ pe gbogbo ọmọ Yoruba ati agba Yoruba to ba gbọ ọrọ aforijin naa yoo mọ wi pe kii ṣe bo ṣe yẹ ki eeyan tọrọ aforijin lo ṣe tọrọ rẹ.

Omipidan ni ''Ọmọ Yoruba ni gbogbo wa, Yoruba la dẹ fi n sọrọ. To ba jẹ wi pe nkan ti Minisista ana sọ lori afẹfẹ to ba ṣe pe bẹẹ ni wọn ṣe n tọrọ aforijin nilẹ Yoruba, gbogbo awọn to gbọ ọ ki wọn ba mi da si i.''

Omipidan ṣalaye pe ko si ija laarin Gomina tẹlẹ Oyetola ati Rauf Aregbesola.

O ni gbogbo igba ti awọn alatilẹyin Aregbesola ba n kọ orin eebu tabi ọrọ eebu si si ọga oun Oyetola, niṣe ni Oyetola kii fesi kankan.

''Lati ilẹ wa, wọn ti sọ fun gbogbo araye pe awọn ko ba ẹnikankan ja. Ninu iṣesi wọn, ninu iwa wọn wọn fi han daju pe awọn ko ba ẹnikankan ja.''

''Lati ọdọ ọga temi awa ko hu iwa aida kankan si Minista ana. Awọn lo gbe awọn eeyan dide ni gbogbo ọjọ alamisi pe ki wọn maa kọrin bu Gomina tẹlẹ Oyetola ti wọn o si fesi pada fun wọn.''

Aworan Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, RaufAregbesola

Bawo ni Aregbesola ṣe tọrọ aforijin to da awuyewuye silẹ?

Lasiko to n ba awọn to jẹ alatilẹyin rẹ sọrọ ni Rauf Aregbesola ti sọ ọrọ aforiji yii.

Ninu alaye rẹ nibi apejọ awọn alatilẹyin rẹ o ni oun ko ṣe eeyan kankan ṣugbọn bi awọn kan ba lero pe oun se wọn, oun tọrọ aforijin.

O tẹsiwaju pe igba ikẹhin ree ti oun yoo tọrọ aforijin lọwọ ẹnikẹni to ba le ro pe oun ṣe wọn.

''Lẹẹkan sii a o ni bẹ ẹnikankan mọ, Ọlọrun ni kan la o bẹ''

Fidio ree nibi to ti tọrọ aforijin naa:

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ija Oyetola ati Aregbesola ko ṣẹṣẹ bẹrẹ

Minisita tẹlẹ ri Rauf Aregbesola lo da bi oloore fun Gomina tẹlẹ ri Isiaka Oyetola.

Awọn mejeeji jijọ ṣe ijọba pọ ni lasiko ti Aregbesola ṣe Gomina ipinlẹ Osun.

Kikuro ti Aregbesola yoo kuro lori oye, Oyetola lo polongo idibo fun ti o si wọle gẹgẹ bi Gomina lẹyin rẹ.

Nkan fi igba diẹ dun laarin wọn ki ogiri to lanu ti alangba si wọ aarin wọn.

Ija naa to kọkọ bẹrẹ diẹdiẹ pada kangun si pe Aregbesola ko ṣatilẹ́yin fun Oyetola to si ṣe akoba fun un lasiko idibo Gomina to waye.

Titi di asiko yii, a ko tii ri ipade kankan tabi ijoko ti wọn ti pari aawọ aarin wọn.

Ikede ita gbangba ti Aregbesola ṣe yii lẹyin to pada si Osun lati Abuja ni akọkọ iru rẹ.

O ku boya awọn alẹnulọrọ yoo ba wọn da si ọrọ ti yoo fi ni iyanju.

Amọ bayii, Aregbesola ti sọ pe lẹyin aforijin eleyi, oun ko ni bẹ ẹnikankan mọ ayafi Ọlọrun.