Aregbesola: Mi ò gba owó oṣù ní gbogbo ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, @SulaiOdus
Minisita ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti sọ pe oun ko gba owo oṣu fun kankan gbogbo ọdun mẹjọ ti oun fi jẹ gomina ipinlẹ Osun.
Aregbesola lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Sola Fasure fi lede.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe Aregbesola gba owo oṣu ọdun mẹjọ ọhun lẹẹkan ṣoṣo ko to kuro lori alefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ.
- Bí èèrà lásán bá rin Sunday Igboho, ẹ rugi oyin - Oodua Youth Coalition
- Wọ́n ní ọkọ̀ bàálù NAF tó mú ẹ̀mí ọmọ mi lọ l'Abuja ti lo ọdún 49 láyé - Bàbá Flight Sergent Olasunkanmi
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Ẹ leè bẹ̀rẹ̀ sí ni gba afárá Third mainland Bridge padà báyìí, ó ti di ṣísí - Fasola
Fasure ni irọ nla gbaa ni iroyin naa, ati pe Aregbesola fi owo rẹ jin ijọba ipinlẹ Osun ni, ko si gba kobo lasiko to wa lori oye.
Agbenusọ Aregbesola ni "ẹ jẹ ki n sọ ni gbangba lẹẹkan sii pe Aregbesola ko gba owo oṣu kankan ni gbogbo akoko to fi jẹ Gomina ipinlẹ Osun."
"idi ni pe ijọba lo pese ile gbigbe fun un, bakan naa ni wọn fun ni ẹṣọ alabo, ounjẹ ọfẹ atawọn ohun amayedẹrun miran, nitori naa, ko na owo kankan ni apo ara rẹ."
Fasure tẹsiwaju pe "gbogbo awọn ọmọ Aregbesola ti dagba, wọn si ti pari ile ẹkọ, nitori naa ko nilo lati maa wa owo ọmọ ile iwe mọ, idi ree ti o ṣe fi gbogbo owo to yẹ ko gba jin ijọba ipinlẹ rẹ.
O ṣalaye pe ẹni to kọ iroyin pe Aregbesola gba owo oṣu ọdun mẹjọ lẹẹkan ṣoṣo ko fi ẹri ọrọ to sọ lede.
Lẹyin naa lo bu ẹnu ẹtẹ lu iroyin naa, to si sọ pe ẹni to fi ọrọ naa lede kan n wa ọna lati ba orukọ rere Aregbesola jẹ ni.
- Kí ló fa ariwo lórí ìyànsípò Tonto Dikeh gẹ́gẹ́ bí "ambassador" àjọ tó ń rí sí ìrìnà àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì?
- Bukola Saraki ṣe ìpàdé pẹ̀lú gómínà Seyi Makinde, Ayo Fayose lórí ọ̀rọ̀ adarí ẹgbẹ́ PDP
- Arapa re gangan sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò ìpè rẹ̀ tuntun
- Ariwo ẹkún sọ níbi ìsìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja













