'Ìbínú ló jẹ́ kí n da omi gbígbóná lé ìyá "láńlọọ̀dù" mi lórí, ẹ ṣàánú mi'

Beeyan ba wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun l’Ọjọru ọsẹ yii, to ri bi ọmọbinrin arẹwa kan, Busayọ John ṣe n fi omije sọrọ, yoo mọ pe ika abamọ lo n fi sẹnu sọrọ, nitori pe ohun ti ko ronu rẹ ni.
Ọrọ awọn Yoruba to sọ pe ‘inu bibi mi o fi iṣẹ ran ọ, ẹdọ fufu mi o bẹ ọ lọwẹ’, ko wa si iranti Busayọ nigba to maa da omi gbigbona ati iyọ le iyaale ile kan ti a fi orukọ bo laṣiri lori l’ọsẹ to kọja yii niluu Abẹokuta.
Akọroyin BBC Yoruba to wa ni agọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa fi oju obinrin naa han tori ẹsun iwa aburu to hu jabọ lori ohun to ṣẹlẹ.

Ki ni iya onile ṣe ti ayalegbe fi binu?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni lọsẹ to kọja ni ọmọdekunrin, ọmọ ọdun meji kan ṣere wọnu ṣọọbu ti Busayọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to n ta ọja, ti ọmọ naa si da awọn ọja rẹ nu.
Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe Busayọ, iya ọlọmọ kan fi gbe ọmọ naa ti a gbọ pe o ni ipenija ara sita, to si tun lu u. Eyi ni wọn lo bi iya ọmọ naa ninu to fi lọ sọrọ buruku si Busayọ, ti ọrọ naa si di yanpọn-yanrin.
Nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii la gbọ pe obinrin naa ti bẹrẹ sii sọrọ buruku si Busayọ pe iwa agbere ti mama Busayọ hu, to fi bii, loun naa tun hu toun naa fi bimọ ti ko ni baba. Eyii lo bi Busayọ naa ninu, to fi sọ pe irin oṣi toun naa rin to fi bimọ abirun niyẹn, eyi ni ọmọ to ṣeeṣi da ọja Busayo nu ninu ṣọọbu rẹ.
Ọrọ yii di ija laarin wọn amọ awọn to wa nibẹ pẹtu si awọn mejeji ninu.

Busayo gbe omile lati da a le iya onile rẹ lori
Owurọ ọjọ keji la gbọ pe ọrọ tun bẹyin yọ, nigba ti wọn lawọn mejeeji ti tun bẹrẹ sii tahun sira wọn, to mu ki Busayọ lo gbe omi kana, to si da a si obinrin naa lori pẹlu iyọ.
Loju ẹsẹ nibẹ ni wọn sọ pe ara obinrin naa ti bo kọja sisọ, eyi ti wọn lawọn ẹlẹyinju aanu ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu fun lati doola ẹmi rẹ.
Busayọ nigba to n sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa, nibi ti ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọlanrewaju Yọmi Ọladimeji ti foju rẹ han f’awọn akọrọyin, o ni oun ko le sọ iru ẹmi buruku to gbe oun wọ lọjọ naa, ati pe igba toun ṣiṣẹ buruku naa tan ni oju oun too ṣẹṣẹ la.
“Emi ati obinrin kan ti a jọ gba ṣọọbu sitosi ara wa la jọ ja l’ọsẹ to kọja, mo wa fi ibinu da omi gbigbina ati iyọ lee lori. Idi ni pe o wọ inu ṣọọbu mi, o si wa lu mi mọbẹ, awọn to wa la wa ko jẹ ki n raaye lati luu pada, eyi lo mu inu bi mi, ti mo fi da omi gbigbona lee lori lọjọ keji."
“Mi o le sọ bo ṣe ṣẹlẹ rara, mi o mọ ẹmi to gbe mi wọ"
Busayo ṣalaye pe o ti ṣẹlẹ tan ki oun to mọ wi pe ohun ti oun ṣe ko dara.
"Latigba ti nnkan yẹn ti ṣẹlẹ, awọn eeyan mi ti dide lati tọju obinrin yẹn, wọn si jẹ ki n mọ pe ara rẹ maa pada bọ s’ipo.
“Aanu ni mo n bẹbẹ fun. Mi o tii l’ọkọ. Nigba ti mo ri obinrin yẹn lẹyin ti mo da omi gbigbona sii lara, o ba mi lọkan jẹ gidi, nitori pe o ti kọja nnkan ti mo ro. Ara obinrin naa ti bajẹ gidi, mi o si ro o pe bo ṣe maa ri niyẹn.
Busayo ni oun ko ronu pe ọrọ yii le di ọrọ ọlọpaa rara, to si n bẹ ijọba pe ki wọn foju aanu wo oun.
Ọga ọlọpaa naa, Ọlanrewaju Yọmi Ọladimeji ti wa f’idi rẹ mulẹ wi pe iwa ọdaju ni Busayọ hu, to si ni yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin t’awọn ba pari iwadii, lati le gba idajọ to tọ sii.
O wa rawọ ẹbẹ s’awọn araalu lati ma ṣe bo iwa ọdaran mọlẹ lagbegbe wọn, tabi ki wọn tete maa fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bi wọn ba ko firi oju ajeji lagbegbe wọn.















