Ẹran jíjẹ ti dèéwọ̀ o! Mọ̀ nípa ààrùn Anthrax tó kógbá ẹran wọlé lọ́jà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eeyan kan ati ẹranko ọgbọn lo gbẹmi mi nitori bi aarun Anthrax ṣe n ja kiri bayii.
Awọn Alasẹ to gbe iroyin naa sita sọ pe eeyan mẹtala lo ti lugbadi aarun naa.
Ajọ eleto ilera orilẹede Ghana ni awọn ti gba awọn nnkan ayẹwo, ti awọn si ti fi sọwọ si ẹka ayẹwo Ghana fun iwadii kikun.
Wọn ni wọn ti ri apẹẹrẹ pe o ṣeeṣe ki awọn to ba ni ibasepọ tabi to ba sumọ awọn to ni aarun naa fara kasa.
Iwadi wọn fihan pe awọn eeyan ko aarun yii lati ara ẹran maluu to ni aarun lara ti wọn jẹ.
Lati wa tọwọ aarun naa bọsọ, ijọba orilẹede Ghana ti gbegi dina pipa, jijẹ ati tita ẹran fun odidi oṣu kan.

Oríṣun àwòrán, Thainkstock
Asẹ ọhun ko tun fi aye silẹ fun awọn to n da ẹran bii aguntan, ewurẹ, ẹlẹdẹ and awọn miiran lati gbogun ti itankalẹ aarun naa.
Ijọba ti wa pese eto abẹrẹ ajẹsara ọfẹ fun awọn ẹranko ni agbegbe ti aarun ti n ba wọn ja.
Lafikun, Ijọba ni awọn ti pese owo lati fi ra ogun sii fun awọn ẹranko lati le mu u dinkun pa itankalẹ aarun naa.
Ọpọlọpọ lo ti n bẹru pe o ṣeeṣe ki aarun naa ti bọ si apa ibo miiran lorilẹede Ghana .
Ki ni a n pe ni Aarun Anthrax?

Oríṣun àwòrán, AFP
Anthrax jẹ aarun kan to to se ijamba fun awọn ẹranko, to si le bọ sara eeyan pẹlu.
Gẹgẹ bi ajọ to n risi didẹkun aarun lorilẹede Ghana ṣe sọ, aarun nla ni Anthrax jẹ to si ni ikapa lati da nnkan run lago ara.
Apẹẹrẹ Aarun Anthrax
Aarun ti a nu sọ yi pin si ọna mẹrin, ti gbogbo wọn si ni apẹẹrẹ ọtọọtọ
Cuteaneous Anthrax
Ago ara ni okoro bacteria aarun yii ma gba wọlẹ to si ma fa ara yunyun, ori fifọ, iba ati awọn apẹẹrẹ iba miiran.
Gastrointestinal Aanthrax
Aarun ma n jẹyọ lẹyin ti ẹranko tabi eeyan ba jẹ ẹran to ni aarun naa ti wọn se rara
Apẹẹrẹ aarun yii ni; ọna ọfun didun, ebi, ailejẹun, iba, inu kikan
Inhalation Anthrax
Aarun yii ma waye latari ohun ti eeyan ba fa simu to jẹ ti Bacteria.
Eyi lo ni okiki ju ninu gbogbo awọn aarun naa, to si tun jẹ eyi to buru ju lọ
Aya riro, iba, igbona, ailemi dada
Injection Anthrax
Awọn onimọ sẹsẹ se iwadi lori aarun yii ni, to si jẹ pe ilẹ Europu ni wọn ti sawari rẹ
Iwadii fihan pe latara lilo ogun oloro abẹrẹ gungun lo fa aarun yii.

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library















