"Ọkùnrin kan pàdánù ìyàwó rẹ̀ méjì àti ọmọ márùn ún sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi Kwara"

Ọkan lara awọn baalẹ ilu ni Patigi, nibi ti ẹmi ọpọ ẹmi eeyan ti sọnu lẹyin ijamba ọkọ oju omi to waye ni Kwara, Liman Umar Muhammed, ti sọ pe mọlẹbi kan padanu eeyan meje nibi iṣẹlẹ naa.
Liman lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.
O ni “ootọ ni pe awọn mọlẹbi kan padanu awọn eeyan to pọ.”
“Awọn mọlẹbi kan tilẹ ti wọn padanu odidi eeyan meje ninu iṣẹlẹ yii.”
“Ọkunrin kan wa to padanu iyawo rẹ mejeji to ni ati ọmọ bii marun un ninu iṣẹlẹ yii, yatọ si iyẹn, idile kan wa to padanu eeyan bii mẹwaa.”
Liman sọ siwaju pe yatọ si ọkunrin naa, ọpọ idile lo wa nibẹ ti wọn padanu eeyan to ju ẹyọkan lọ.

Bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ
Mohammed Hassan, to ṣẹṣẹ pari ile ẹkọ girama wa lara awọn ti ori ko yọ ninu ijamba naa ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ.
O ni “awọn eeyan abule mi ati abule to wa lẹgbẹ wa korajọ lati lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo kan, nigba ti a rin nnkan bi idaji kilomita nigba ti a n pada bọ ni ọkọ oju omi naa dede kọṣẹ.”

“Lẹyin to kọṣẹ tan, a ko mọ ohun to yẹ ki a ṣẹ, awọn agbalagba to wa nibẹ wa sọ fun awọn ọdọ pe ki wọn bẹ sinu odo lati luwẹ.”
O sọ siwaju si pe awọn obinrin to wa ninu ọkọ naa lẹyin ti awọn ọkunrin bẹ sinu odo ko le luwẹ.
O ni “bi ọkọ naa ṣe bẹrẹ si n ri, awọn obinrin kan joko sinu ọkọ naa ni nitori wọn ko le liuwẹ.”
"Ọmọbìnrin mi mẹ́ta tí wọn kò ní pẹ́ lọ sílé ọkọ ló bómi lọ ní Kwara"

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàlá oṣù Kẹfà ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani lọ́kàn jẹ́ gidi wáyé ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Patigi, ìpínlẹ̀ Kwara.
Ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú omi, tí ọ̀pọ̀ sì tún àwátì nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ rì.
Àwọn ènìyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún ni wọ́n ń kúrò láti ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan ní ìpínlẹ̀ Kwara padà sí ìpínlẹ̀ Niger kí ìṣẹ̀lẹ̀ làlúrí náà tó wáyé.
Títí di àsìkò yìí, wọ́n ṣì ń wá àwọn ènìyàn nínú odò tí wọ́n rí sí náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní ọkọ̀ ojú omi náà ya sí inú odò ló ṣokùnfà ìdí tí ọkọ̀ ojú omi náà fi rì.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara, Ajayi Okasanmi ní ènìyàn 106 ló ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ àmọ́ Emir ìlú Patigi, Ibrahim Umar Bologi kejì nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ti ṣáájú sọ pé ènìyàn tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó 150.
"Ọ̀pọ̀ obìnrin ló kú nígbà tí wọ́n ń sáré láti dóòlà ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn"

Ọ̀kan lára àwọn tí orí kó yọ nínú ìjàm̀bá náà, Mohammed Alhassan sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló kú, nígbà tí wọ́n ń sáré láti dóòlà ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn.
Ó ní ẹ̀gbọ́n òun tí àwọn jọ wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà mórí bọ́ àmọ́ ó pàdánù ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún méje.
Aisha Mohammed ní tirẹ̀ ní ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú gbá à ló jẹ́ fún òun nítorí ọmọbìnrin wúńdíá mẹ́ta ni òun pàdánù sínú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí.
Ó ní àwọn ọmọ náà ti ń múra ilé ọkọ kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó wáyé.
Kò ì tíì sí ẹni tó le fi ìdí ohun tó ṣokùnfà ìjàm̀bá ọkọ̀ náà múlẹ̀ títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Gómìnà jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ohun ààbò fáwọn èrò ọkọ̀ ojú omi
Ní ọjọ́rú ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq náà ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Mallam AbdulRazaq ní òun bá àwọn ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn kẹ́dùn tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ẹgbẹ̀rún kan "life jacket" fún àwọn ènìyàn tó ń lo ọkọ̀ ojú omi ní agbègbè náà láti ṣe ìrìnàjò.
Ó ní òun ti ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àjọ tó ń rí sí ètò ìrìnnà ojú omi lórí ọ̀nà tí wọ́n máa tún fi pèsè ààbò tó péye ní agbègbè náà si.
Ṣáájú ni Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu náà ti ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí àwọn ènìyàn náà.
















