Timothy Adegoke: Mọ̀lẹ́bí Timothy Adegoke ṣàlàyé ìhà tí wọ́n kọ sí ìdájọ tí ilé ẹjọ́ dá fún Ramon Adedoyin
''Awọn ara ṣọọṣi mi ri mi ti mo n dunnu, wọn ko mọ idi ti inu mi fii n dun. Wọn ni boya mo gba alaati ni''.
Iyawo oloogbe Timothy Adegoke tawọn kan ṣeku pa nile itura Hilton arabinrin Bolatito Victoria Adegoke lo ṣalaye yi fun BBC nigba taa ba sọrọ nipa idajọ ile ẹjọ lori iṣekupani ọkọ rẹ.
Akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ni Timothy Adegoke jẹ ki wọn to ṣadede ri oku rẹ lẹba ile Itura Hilton ni Ile Ife.
Arabinrin Bolatito sọ pe inu oun dun bẹẹ naa si ni ayọ oun kun nigba toun gbọ idajọ ile ẹjọ giga.
- Èlò ní ''Celebrity'' n gbà tí ẹ fi ní kín sàn owó orí N18m - Iyabo Ojo sí ìjọba Èkó
- Ẹ jẹ̀bùrẹ́, ìyanṣẹ́lódì kò lè so èso rere kankan - Sanwoolu rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí NLC - BBC News Yorùbá
- Asáko wá ti padà wálé; A ṣetán láti yánjú aáwọ̀ láàrín ara wa –Makinde
- NLC, TUC ṣàtìlẹ́hin Obi tó ṣèlèrí láti yọ subsidy, wọn ṣe wa n halẹ̀ mọ́ Tinubu-
O fikun pe ''O tun jẹ ki igbagbọ mi kun si wi pe Ọlọrun alaaye ni mo n sin''
Bolatito sọ pe oun ti sọ ireti nu lori iku ọkọ rẹ to si ni idajọ yi fihan pe ''Oba kan tun wa to le gbeja eeyan''
O ni oun kọ orin idun bẹẹ si ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Naijiria to ṣe atilẹyin lati ri pe idajọ ododo rinlẹ.
Ọrọ arabinrin Bolatito ko fi bẹẹ yatọ si eleyi ti Adebola Olakunle to jẹ olori ọdọ gbogbo ni ilu Eruwa to jẹ ilu abinibi Timothy.
Oun naa dupẹ fun idajọ ododo to si kete ti ọrọ iku Timothy ṣẹlẹ lawọn ọdọ ati ilu patapata ti dide si ọrọ naa.
O ṣe iranti bi awọn ọdọ ṣe ṣe iwọde kaakiri lati beere idajọ ododo fun Timothy.
O ni awọn kọkọ n foya wi pe idajọ naa ti n pẹ nilẹ ati pe awọn le ma ri idajọ ododo gba.
O lawọn dupẹ pe adajọ fi igboya gbe idajọ naa kalẹ.
Idajọ taa n wi yi sọ pe ki wọn yẹgi fawọn kan ki awọn afurasi mii ti wọn fẹsun kan si ṣe ẹwọn lori iku Timothy.
Yatọ si eleyi adajọ ni ki wọn san owo gba ma binu fun mọlẹbi Timothy ki ijọba si ṣeto ẹkọ fun awọn ọmọ rẹ.
Iyawo Timothy ni oun dunnu si awọn ohun ti idajọ yi gbe kalẹ amọ o ni o ṣi jẹ ọgbẹ ọkan pe Timothy ko si laye lati ṣe baba fawọn ọmọ rẹ.