NLC, TUC ṣàtìlẹ́hin Obi tó ṣèlèrí láti yọ subsidy, wọn ṣe wa n halẹ̀ mọ́ Tinubu?

Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti kesi aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC pe ki o kọwe fipo silẹ tabi ko si tọrọ aforijin lọwọ ọmọ Naijiria lori bo ṣe n halẹ iyanṣẹlodi lori yiyọ ẹkunwo owo epo taa mọ si subsidy.
Abayomi Arabambi to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lo sọ ọrọ yi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ.
Arabambi sọ pe ko tọ ki NLC tabi TUC maa dunkoko iyanṣẹlodi mọ aarẹ tuntun lẹyin igba ti wọn ko tako awọn oludije ipo aarẹ yoku nigba ti wọn sọ lasiko ipolongo pe awọn yoo yọ subsidy.
Yiyọ ẹkunwo owo epo ti aarẹ Bola Ahmed Tinubu gbe lara awọn igbesẹ akọkọ ijọba rẹ yi tiu mu orisi iriwisi wa.
Bawọn kan ṣe n sọ pe o daa bo ṣe fẹsẹ rinlẹ lori ipinuu yi lawọn miran n sọ pe igbesẹ naa ku diẹ kaato.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria wa lara awọn to tako aarẹ lẹyin ti ipade ti wọn ṣe lati yanju ọrọ naa ja si pabo.
Ni bayii, ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni Ọjọru tii ṣe ọjọ Keje oṣu Kẹfa ti ijọba ko ba da owo epo pada.
Kilode ti alatako fi n gbe lẹyin Tinubu?
Arabambi to jẹ akọwe ipolongo fun ẹgbẹ alatako Labour Party ni ipinnu ẹgbẹ awọn nipa ọrọ subsidy ko yi pada.
O ni awọn ko yi ipinnu yi pada tori pe oludije awọn ko jaweolubori ati pe nkan ti Peter Obi to jẹ oludije ẹgbẹ awọn sọ lasiko to n ba awọn akọroyin fọrọ jomi toro ọrọ ko yi pada.
O ni lasiko ipolongo, Peter Obi sọ pe patapata loun yoo yọ ẹkunwo subsidy ati pe ''ole jija alapapin ni subsidy jẹ''
O tẹ siwaju pe ''Eyikeyi ipinnu ẹgbẹ lasiko ipolongo ko yatọ lẹyin ipolongo.Gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu a o le maa ṣeku ṣẹyẹ ''
''Ẹgbẹ oṣiṣẹ yi kanna lo dakẹ lori ipinnu ti Atiku Tinubu ati Obi lawọn yoo ṣe lori ọrọ yiyọ ẹkunwo.Ki wa lo de ti wọn fi n dunkoko mọ Tinubu?''
O fikun pe ohun to mu ki NLC gbe lẹyin Obi nigba naa lọhun ti TUC ko si jade tako Obi to lohun yoo yọ subsidy, o ni :
''o panilẹrin pe wọn yoo wa gunle iyanṣẹlodi bayii ti Tinubu kede yiyọ subsidy.''
Mo fẹ ki wọn tọrọ aforijin lori atilẹyin ti wọn ṣe fun Obi lati yọ subsidy nigba ipolongo idibo
Lakotan Arabambi sọ pe o yẹ ki ẹgbẹ oṣiṣẹ tọrọ aforijin lọwọ araalu pẹlu bi wọn ṣe ṣatilẹyin fun Peter Obi nigba to lohun yoo yọ ẹkunwo subsidy.
O ni ko yẹ ki wọn ma wa sare tẹle aatrẹ tuntun nitori oun kọ lo yọ subsidy.
''Ọgbẹni Peter Obi sọ fun wa pe wọn ti yọ subsidy lati ipari oṣu Kẹfaa ninu iṣuna ọdun yi.Ati NLC ati TUC ni wko tako eleyi nigba naa lọhun.Torinaa, Ọgbẹni Joe Ajero,o tọ ko kọwe fipo silẹ tabi ko si tọrọ aforijin lọwọ ọmọ Naijiria''
O ni bẹẹ naa lo yẹ ki Comrade Osifo naa kọwe fipo silẹ tabi ko tọrọ afoirijin nitori awọn naa ṣatilẹyin fun wa ''nigba tawa naa sọ pe a o yọ suubsidy''















