Kíni ó túmọ̀ sí láti ‘’Devalue’’ Naira?

Oríṣun àwòrán, Others
Ohun ti o tunmọ si lati devalue naira ni ki orilẹede gbe igbeṣẹ lati jẹ iye owo orilẹede naa si ti orilẹede miran lọ silẹ.
Ninu eto ọrọ aje ni wọn ti ma n lo ọrọ yii ati awọn ti wọn n lo owo ilẹ okeere fun eto ẹkọ abi ọja tita.
Eyi tunmọ si pe ijọba yoo kede iye ti wọn yoo maa ta naira kan si owo ilẹ okeere
Eyi ma n mu ki owo orilẹede ti wọn ba devalue rẹ lati maṣẹ niyii tabi ni iye lori bii ti tẹlẹ.
Awọn ijọba orilẹede ma n gbe igbesẹ yii ti ko ba si ọna abayọ miran mọ lati ṣe atunṣe si eto ọrọ aje to ba dẹnukọlẹ.
Idi ti orilẹede kan yoo fi gba ki wọn devalue owo wọn ni lati fi aye silẹ fun gbigbe ọja karakata lati orilẹede naa lọ si okeere, ki wọn le dẹkun rira ọja wọle lati oke okun, ti eyi yoo si mu ki ẹka owo dọgba.
Ohun tí CBN sọ rèé nípa iye pàṣípààrọ̀ owó Naira sí dollar #650/$1

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Banki apapọ orileede Naijiria ti fesi si iroyin to gbode pe banki naa ti sọ iye owo pasiparọ owo Naira si dollar di #650/$1.
Atẹjade ti banki agba naa fi sita ṣalaye pe ko si ootọ ninu iroyin yi ati pe iye owo pasiparọ owo Naira loju opo awọn oniṣowo ati oludokoowo taa mọ si Investors’ and Exporters’ Forex Window ko yẹ ni ₦465 si $1.
Isa AbdulMumin to fi ọrọ yi sita lorukọ banki naa ṣalaye pe irọ lasan ni ileeṣẹ iwe iroyin to gbe iroyin naa jade ko jọ pẹlu awọn ahesọ ọrọ.
O rọ araalu lati yago fun iroyin ẹlẹjẹ yi to sọ pe ''wọn gbero rẹ lati da wahala silẹ lagbo karakata ow Naijiria.''

Oríṣun àwòrán, CBN
Ki lo de ti iroyin yi fi jẹ atẹwọgba faraalu?
Pasiparọ owo Naira Naijiria si dọla jẹ nkan to ṣe pataki si araalu.
Nitori naa eyikeyi iroyin to ba ti rọ mọ ni araalu yoo yara tẹti si.
O ti pẹ diẹ bayii ti owo Nairia ti dẹnukọlẹ ti dọla si ti lọ soke mọ lọwọ lagbo paṣiparọ owo.
Ni ilẹ oni to mọ, ijọba n paarọ owo Naira loju opo I&E ni iṣiro ₦465 si $1.
Iye yi yatọ si ti oju opo awọn alarobọ taa mọ si balck market nibi ti awọn eeyan a maa ra dọla pẹlu iye owo Naira to to N760/$1.
Bi eeyan ba wo iye owo yi si ti ijọba yoo ri pe o jina si ara wọn.
Ohun ti eleyi tunmọ si ni pe gbogbo nkan tawọn ọmọ Naijria ba nilo lati fi dọla ṣe yoo wọn bi oju ni.
Lọpọ igba pasiparọ yi a maa mu ki awọn ọja to n wa lati ilẹ okere tabi to ba niṣe pẹlu lilo owo ilẹ okere a maa wọn gaan.
Idi si ree tawọn eeyan n dunnu pe CBN mu owo naa walẹ si #650/$1 to kere si N760/$1 ti wọn ṣe karakata rẹ bayii.















