Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ṣe ìpàdé pọ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí àjọ ìgbòkègbodò ọkọ̀, PMS ìpínlẹ̀ Ọyọ

Akanṣe ipade apero ti wọn pe lati wa ojuto si iṣoro to n koju ajọ to n ṣe amojuto ibudokọ n'ipinlẹ Ọyọ, PMS waye lonii ni gbọngan nla 'House of Chiefs’ to n bẹ ninu ọgba ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ ni agbegbe Agodi nilu Ibadan.
Alaga ipejọpọ naa, Ọjọgbọn Duro Adeleke ti o ba awọn eeyan sọrọ nibi ipejọpọ naa ṣe alaye wi pe
eeyan maa n tan, ṣugbọn itan kii tan.
O tẹsiwaju wi pe ko yẹ ki iranti ẹnikẹni jẹ baalẹ ṣa ada-ṣa ada tabi iwa ipanle mii.
Adeleke parọwa si gbogbo ọmọ ẹgbẹ awakọ lati ṣe rere ki ile aye le daa.
Lara awọn alejo pataki to ba awọn eeyan sọrọ nibi ipejọpọ naa, ti o tun kọ iwe nipa ọna abayọ si iṣoro igbokegbodo ọkọ n'ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Duro Ogunẹsan ṣe alaye wi pe ọkọ ero to n ṣiṣẹ lo mu ki agbekalẹ wa fun ajọ to n mojuto ibudokọ, PMS.
O ni o ṣe pataki ki amojuto to peye wa fun ajọ naa, nitori aabo fun awọn awakọ ero ati awọn ero ti wọn n gbe ṣe pataki pupọ.
O tẹsiwaju wi pe lati gba de igba lo yẹ ki ayẹwo awọn alamojuto igbokegbodo ọkọ maa waye,
ki a le mọ bi awọn eto ti wọn gbe kalẹ ṣe n lọ si, bẹrẹ lati onka iye ọkọ ero, maruwa ati ọkada to n ko ero.
Lai si eleyii, o ni aṣilo agbara yoo maa waye lati ọwọ awọn alamojuto ti ijọba yan sipo.
Ogunẹsan ni akọsilẹ gbudọ wa fun awọn oṣiṣẹ awakọ ero ati awọn alamojutọ ajọ igbokegbodo ọkọ, ki ijọba le mọ wọn dele dele.
"Amojuto gbudọ wa fun awọn to n ja iwe fun ọkọ ero lati le mọ bi wọn ṣe n ṣiṣẹ si ati ifojusun wọn, nitori ko yẹ ki ijọba na owo tabua lori ibudokọ ki awọn eeyan kan si maa baa jẹ.
Ẹka naa si gbudọ maa pawo wọle fun ijọba lai ni araalu lara."

O ke si ijọba lati ṣe agbekalẹ igbimọ igbokegbodo ọkọ, ki gbogbo ẹgba awakọ si ni aṣoju nibẹ.
Bakan naa lo ni awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si imototo ayika, igbokegbodo ọkọ, ẹka to n mojuto ọrọ ilẹ ati ato ilu, ẹka ileeṣẹ ijọba to mojuto ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ, ẹka to n mojuto lilọbibọ ọkọ, OYTMA, ajọ to n yẹ iwe ọkọ wo ati ẹka eto ẹnawo gbudọ ni aṣoju ninu igbimọ yii.
O ni eleyii yoo mu ki alafia jọba ninu ilu, awọn olugbe ilu naa yoo si maa lọbọ lai si wahala.
Awọn aṣoju ẹka iṣẹ ode ati igbokogbo ọkọ, ọrọ ilẹ ati ileigbe, ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ naa ba awọn eeyan sọrọ nibi ipade naa, gẹgẹ bi wọn ṣe n kan sara si Gomina Ṣeyi Makinde fun awọn agbekalẹ ti o ṣe lati mu ni ki ara tu gbogbo ara ilu.
Wọn parọwa si gbogbo eeyan ilu lati fi aye gba alaafia ki wọn si fi agbajọwọ ṣe atilẹyin fun ijọba ki idagbasoke ati itẹsiwaju le de ba ipinlẹ Ọyọ.
Kọmisana Ọlọpa ipinlẹ Ọyọ, Adebọwale Willams
ti Adejọbi Akinade ṣoju fun nibi ipade naa fi ọrọ lede. O ni aabo ati itọju awọn eeyan ilu ni iṣẹ akọkọ ti ijọba ni gẹgẹ bi ojuṣe.


Labẹ eleyii sini ileeṣẹ Ọlọpaa naa yoo ti ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati riidaju wi pe eto aabo fi ẹsẹ mulẹ ninu ilu, gẹgẹ bi awọn eeyan ilu naa ṣe ni ipa lati ko ki alaafia le jọba.
O ka awọn ofin ti wọn ko gbudọ ta ipa si;
*Ẹnikẹni ko gbudọ ni ibọn, ada tabi ohun ija mii lọwọ tabi ninu ile. O ni ki ẹni to ba ni ibọn lọwọ lọ koo silẹ ni agọ ọlọpaa ki wọn si pada si ile wọ
*Ofin ti de tita egbogi oloro ati ọti ni ibudokọ ti di eewọ. O ni ẹni ti ko ba mu ogun oloro ko ni fa wahala.
*Olori ti wọn ba fi jẹ adari ibudokọ ni yoo dahun fun gbogbo wahala ti o ba ṣẹlẹ ni ibudokọ. O ni awọn adari ibudokọ ni ẹtọ lati ke si ijọba ti wọn ba kofiiri awọn oniwa ipanle ni ayika wọn.
*Ẹnikẹni ko ni agbara lati gba ẹmi ẹlomii. Ti wọn ba ri ọlọpaa to ṣe ohun ti o tako ofin, ki wọn fi ẹjọ rẹ sun ni aagọ ọlọpaa dipo ki wọn maa pa ọlọpaa ti wahala ba ṣẹlẹ.Aṣoju ileeṣẹ Ologun, Uk Egbo ni erongba rere ni agbekalẹ PMS ti o si lagbara lati mu itẹsiwaju wa, bi wọn ba loo daadaa. O fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹnikẹni ko lẹtọ lati ni nnkan ijagun ninu ile.
O ni awakọ ero ko nilo nnkan ijagun lati ṣe iṣẹ wọn.
O dupẹ lọwọ Gomina Ṣeyi Makinde ti o fi aye gba iru ipade apero bayii pẹlu adura wi pe Ọyọ ko ni bajẹ o.
Awọn aṣoju ikọ Amọtẹkun, ilẹẹṣẹ Ọtẹlumuyẹ, ẹṣọ aabo oju popo, ọkanojọkan ẹgbẹ awakọ bii NURTW, RTEAN, ATTAN, ati ACOMORAN naa ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.












