Àlàyé lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe yí ìdájọ́ padà sí ọdún méjì fún òṣìṣẹ́ Rahman Adedoyin tí wọ́n dájọ́ ikú fún l’Osun

Oríṣun àwòrán, other/dailygistonline.com.ng
Lẹyin to da ẹjọ iku fun oloye Adegoke Rahman to ni ile itura Hilton Hotel ti wọn ti pa akẹkọọ fasiti OAU kan ni ilu Ile Ifẹ,
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to fijoko si ilu Osogbo tun joko l'Ọjọru lati yi idajọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile itura naa pada.
Oṣiṣẹ ile itura naa, Omidan Adedeji Adeṣọla ni alamoju eto ikini kaabọ si ileeṣẹ naa, ti awọn oloyinbo n pe ni ‘receptionist’ lọjọ kẹfa oṣu kọkanla ọdun 2021 ti Timothy Adegoke lasiko sun si ile itura naa.
Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Onidajọ Adepele Ojo ran omidan Adeṣọla si ẹwọn ọdun meji lori ẹsun pe o yi iwe ẹri owo sisan ti wọn kọ fun oloogbe naa lalẹ ọjọ to wọ si ile itura naa.
Bakan naa ni wọn ni omidan naa tun yi iwe ẹri isanwo miran lati fi bo gbogbo afihan pe oloogbe Timothy Adegoke sun si ile itura naa.
Olupẹjọ, Fatima Adesina rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ naa lati fi ọwọ ẹrọ mu idajọ Adeṣọla nitori pe ko si ohunkohun to so o pọ mọ iku oloogbe naa.

Bakan naa ni Olupẹjọ ni igba akọkọ ti Adeṣọla yoo maa hu iwa ọdaran bayii niyi.
Onidajọ Adepele ojo ni ki wọn bẹrẹ si nii ka akoko ẹwọn ọdun meji rẹ lati igba to ti wa lahamọ ọlọpaa.
Eyi fihan pe o ṣeeṣe ki Adeṣọla o gba itusilẹ ki ọdun 2023 to pari.
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun da ẹjọ iku fun Oloye Rahman Adedoyin ati awọn oṣiṣẹ rẹ meta kan ni ọjọ Iṣẹgun fun lilọwọ ninu iku oloogbe Timothy Adegoke loṣu kọkanla ọdun 2021.
Timothy Adegoke jẹ akẹkọọgboye imọ keji ni fasiti OAU, nilu Ile ifẹ.












