Amúgbálẹ́gbẹ̀ Auxillary ṣàlàyé lórí ìrẹ́jẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ní Auxillary ń jà fún tó fa ọ̀rọ̀ òun àti gómìnà Makinde pẹ̀lú bí Auxillary ṣe bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ọlọ́pàá nílé rẹ̀

Awuyewuye ṣì n lọ laarin gomina ipinlẹ Ọyọ ati olori ajọ amojuto awọn awakọ ero ni ipinlẹ Ọyọ, PMS, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si Auxilary.
Ọrọ naa lo si n fa ọpọ ikayasoke laarin awọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa julọ ilu Ibadan.
Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Auxillary ti ṣalaye lori bi ọrọ náa ṣe bẹrẹ ati ohun to mu ọlọpaa wọle.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba lowurọ Ọjọbọ, ni ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero tẹlẹ naa ti ṣalaye ohun to mọ nipa rẹ.
O ni pe lootọ oun ko si nibi ọpọ ipade laarin Gomina Makinde pẹlu Auxillary;
ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn adari ẹgbẹ awakọ ero NURTW ati RTEAN to fẹ dara pọ mọ PMS n fẹ yẹ aga mọ awọn ọmọlẹyin Auxillary nidii ni.
Awọn yii ni wọn ti jọ jiṣẹ jiya fun ọdun mẹjọ ti awọn adari ti a n sọrọ wọn yii ‘fi n gbadun ijọba to lọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awakọ ero’
Se lootọ ni pe Makinde fẹ rẹ Auxilliary jẹ ni?
O ni irẹjẹ yii ni Auxillary n tako to fi di aigbọra-ẹniye laarin oun ati gomina Makinde.
“Ọga ni rara o, pe ẹ jẹ ọdun mẹjọ ti yin, ẹ tun wa fẹ bẹrẹ ọdun mẹjọ miran ki awọn tun wa sun awọn ọmọ to jiya ọdun mẹjọ yẹn si ẹyin fun yin.
Ọga ni oun le gba wọn wọle o, kii ṣe pe awọn ko le ba wọn ṣe.”
O ni ohun ti Auxillary duro le lori ni pe ẹyin awọn ọmọlẹyin oun ni wọn maa to si, eleyi ti awọn adari ẹgbẹ awakọ naa ko fẹ gba.
‘Ọjọ meji ni awọn ọlọpaa fi wa kọlu ile Auxillary wọn si pa eeyan kan lasiko naa’

Oríṣun àwòrán, others
‘Ọjọ meji ni awọn ọlọpaa fi wa kọlu ile Auxillary wọn si pa eeyan kan lasiko naa’
Ninu ifọrọwerọ naa pẹlu BBC, ni amugbalẹgbẹ fun Auxillary naa ṣalaye wi pe ọjọ meji ọtọọtọ, “Ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru” ni awọn ọlọpaa fi wa kọlu ile alaga ẹgbẹ awakọ ero naa.
Se lootọ ni Awọn ọlọpaa n parọ ni?
O ni irọ ni ọrọ ti ọlọpaa n sọ lori ikọlu naa pe awọn ọmọlẹyin aṣiwaju ẹgbẹ ọlọkọ ero naa ṣina ibọn lasiko ti wọn lọ.
Amugbalẹgbẹ fun Alagba Mukaila Auxillary naa, to ṣalaye pe oun wa ni ile naa lasiko ti awọn ọlọpaa kọlu ibẹ, ṣalaye pe tajutaju 'tear gas' ni awọn ọlọpaa kọkọ yin si awọn olugbe ile naa ki wọn to bẹrẹ si ni ṣe ohunkohun.
O ni gbogbo awọn eeyan wọnyii ni afẹfẹ tajutaju ti ko si loju ti wọn ko si ni ohun meji ju wi pe ki wọn ju ọwọ silẹ fun awọn ọlọpaa naa lọ.
“Ṣe eeyan 78 jẹ nnkan ti agbofinro mẹwaa tabi ọgbọn le mu?
Ko si tasi mi ki n ta si ọ kankan.
Ka ni tasimi tasi ọ wa gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ, ti eeyan kan si ku ni iha Auxillary, ṣugbọn ko si nnkankan to ṣe ọlọpaa kankan. Eyi fihan pe ko si taasimi ki n taa si ọ kankan larin awọn ati ọlọpaa.”
Nibo ni Auxillary wa bayii?

Oríṣun àwòrán, others
Amugbalẹgbẹ Alagba Auxillary naa ṣalaye pe gbogbo wọn lo ni lati sa asala fun ẹmi wọn, titi kan adari ẹgbẹ ọlọkọ ero naa.
O ni nigba ti gbogbo nnkan di iṣu ata yan an yana an, ko si ẹni to lee duro, gbogbo wọn, titi kan Auxillary funra rẹ, sa asala fun ẹmi awọn ni.
“Ẹmi naa funrarami naa sa asala fun ẹmi mi ni. Emi gan o tii mọ ibi ti ọga wa mi o si le sọ boya wọn tilẹ ti pe gomina lori ọrọ yii.”
‘Awọn ọmọ Auxillary ko da wahala silẹ nilu Ibadan’
Amugbalẹgbẹ fun Auxillary naa ṣalaye pe ir patapata ni ọrọ yii ati pe awn to ba n lọ kaakiri igboro ilu Ibadan yoo ri pe alaafia to jọba laarin igboro ibadan jinna ketekete si ariwo wahala wa ti awọn eeyan n sọ kiri ati pe alaga awọn awakọ ero naa ati awọn ọmọlẹyin rẹ ko fi igba kankan da wahala silẹ.
Bawo ni wahala laarin Gomina Makinde pẹlu Auxillary ṣe jẹ?

Lẹyin gbogbo pọpọsinsin ayẹyẹ iburawọle fun saa keji gomina Seyi Makinde ni papa iṣire Ọbafẹmi Awolọwọ, ti ọpọ ṣi mọ si Liberty Stadium nilu Ibadan lọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023 ni awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ ero mejeeji, iyẹn NURTW ati RTEAN ba ni ki awọn sin Gomina de ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ikọlaba lati kii ku oriire. Ni Ibẹ ni a gbọ wi pe Auxiliary ati awọn eeyan rẹ ti pade wọn ti ọrọ si di iṣu ata yan-an-yan-an.
Ọrọ yii lo bi Gomina Ṣeyi Makinde ninu ti o si pa aṣẹ wi pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ Auxiliary ati awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ rẹ.
Lati igba ti ijọba si ti ṣe ikede yii ni ariwo ti n sọ lọtun losi lori iwa ipa ti awọn janduku kan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ ara ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to wa labẹ Auxiliary n hu lawọn agbegbe bii Olodo, Iwo Road ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni gbogbo awọn adugbo yii ni awọn eeyan ti n ke gbajare wi pe awọn n gbọ iro ibọn lakọ-lakọ.
Ninu oṣu karun ọdun 2019 ni Makinde fi ofin de ẹgbẹ awakọ NURTW ati RTEAN nitori wahala ti wọn fa lori ipo adari, lẹyin eyii si ni o ṣe idasilẹ ajọ PMS to n mojuto igbokegbodo ọkọ eleyii ti Auxiliary ati igbimọ rẹ n ṣe akoso fun.












