Auxilliary na pápá bora lásìkò tí ọlọ́pàá ṣèkọlù sí ilé rẹ̀!

Oríṣun àwòrán, Others
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni alamojuto igbokegbodo ọkọ, PMS n'ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' ti na papa bora.
Eyi ko ṣẹyin ikọlu ti ileeṣẹ ọlọpaa sẹ si ile rẹ ni ọjọ Iṣẹgun.
Awọn ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgọrin ni ileeṣẹ Ọlọpaa ko nile alamojuto igbokegbodo ọkọ, PMS ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' lasiko ti wọn ya wọ ibẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter
Bakan naa ni wọn ba onde, ibọn ati ohun ija ija loriṣirisi ninu ile naa.
Iroyin ni biotilẹ jẹ pe Auxiliary ti na papa bora, ẹmi eeyan kan ba iṣẹlẹ lọ lasiko ti wọn kọju ija si awọn agbofinro.
Lara ẹru ti awọn agbofinro ko ni ile naa ni ọpọlọpọ ibọn, ọta ibọn ti o le ni ẹdẹgbẹrin, ẹrọ ibanisọrọ mẹtalelọgbọ ati owo ti o le ni Milliọnu mẹta Naira.
Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ Auxilliary pẹ̀lú ọgọ̀ọ̀rọ̀ ìbọn àti ohun ìjà olóró - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Twitter/Oyo State Police
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe afihan awọn ọmọlẹyin Auxiliary ti kele ofin gbe ninu ile ti wọn n gbe pẹlu ọga wọn.
Ọpọlọpọ ibọn ati ọta to fi mọ awọn nnkan ihamọra mii ni awọn agbofinro ba lọwọ wọn.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede loju opo Twitter ni wọn ti ni awọn ba igbiyanju awọn ti wọn mu naa lati da alaafia ipinlẹ Oyo ru.
Wọn ni o kere tan eniyan mejidinlọgọrin ni ọwọ awọn tẹ pẹlu ọpọlọpọ ibọn, onde ati owo iyebiye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Saaju ni iroyin jade pe gomina ipinlẹ Oyo, ṣeyi Makinde ti gba gba iṣẹ lọwọ alamojuto igbokegbodo ọkọ, 'Park Management System (PMS)', Alhaji Mukaila Lamide ti ọpọ eeyan mọ si "Auxiliary" ati gbogbo igbimọ rẹ.
Eyi n waye lẹyin iburawọle fun saa ikeji ijọba Gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde lọjọ Aje.
Ninu atẹjade ti olori oṣiṣe tuntun n'ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Segun Ogunwuyi fi lede lorukọ Gomina, o ni, "Mo ti gba aṣẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lati fi ọrọ too yin leti nipa ituka igbimọ to n ṣe amojuto igbokegbodo ọkọ bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023".
Wo ohun tó fa wàhálà láàrín Seyi Makinde àti Auxiliary alága onímọ́tò n’Ibadan tó fi yọọ́ nípò nìyí

Oríṣun àwòrán, twitter/seyimakinde/bbc
Lẹyin iburawọle fun saa ikeji ijọba Gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde lọjọ Aje ni iroyin mii tun jade wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gba iṣẹ lọwọ alamojuto igbokegbodo ọkọ, 'Park Management System (PMS)', Alhaji Mukaila Lamide ti ọpọ eeyan mọ si "Auxiliary" ati gbogbo igbimọ rẹ.
Ninu atẹjade ti olori oṣiṣe tuntun n'ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Segun Ogunwuyi fi lede lorukọ Gomina, o ni, "Mo ti gba aṣẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lati fi ọrọ too yin leti nipa ituka igbimọ to n ṣe amojuto igbokegbodo ọkọ bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023".
Ki ni ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ yii?
Gbogbo wa la mọ wi pe ọrọ kii dede ṣẹlẹ bi ko ba ni idi.
Awọn igun kan ninu ẹgbẹ awakọ meji ọtọọtọ to n ṣe akoso igbokegbodo ọkọ tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, 'National Union of Road Transport Workers(NURTW)', ati 'Road Transport Employers Association of Nigeria (RTEAN)'.
O ni a gbọ pe wọn ṣe abẹwo Ṣeyi Makinde saaju eto idibo ti o gbe Gomina naa wọle fun saa ikeji, wọn si ṣe ileri fun un wi pe awọn yoo baa ṣiṣẹ pọ ki o le de ibi ilepa rẹ.
Bo tilẹ jẹ wi pe ifanfa wa laarin ẹgbẹ mejeeji ati Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Makinde gba lati fun wọn ni aye ki aigbọraẹni ye ti wọn ni tẹlẹri le di ohun igbagbe.
Eyii lo mu ki Gomina ke si alakoso igbimọ to n ṣe akoso awọn ọlọkọ ero n'ipinlẹ Ọyọ, PMS, iyẹn Alaaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si ‘Auxiliary’ wi pe ki o fi aye gba awọn igun ẹgbẹ awakọ ero mejeeji naa lẹyin ti wọn gba lati dara pọ mọ gomina ki alaafia si le tubọ jọba lẹka awọn ọlọkọ ero ni ipinlẹ Ọyọ.
Ṣe wọn ni Oriṣa jẹ n pe meji obinrin ko denu. Igbesẹ yii ko dun mọ Auxiliary ninu, idi si niyii ti o fi kọ eti ọgbọin si aṣẹ ti Makinde pa.
Gbogbo akitiyan lati rii pe iṣọkan jọba laarin ẹgbẹ awọn awakọ ero lo n ja si pabo pẹlu bi Auxillary ṣe faake kọri pe oun ko ni ba awọn ẹgbẹ awakọ ero meji toku, iyẹn NURTW ati RTEAN ṣe
Ohun ti a gbọ siwaju sii ni pe Gomina Seyi Makinde n fi ara daa gbogbo iwa aigbọran ati ti inu mi ni n o ṣe yii pelu erongba wi pe yoo pada fi aye gba wọn, eleyi ti wọn ba wọeto burawọle fun Makinde lati ṣe ijọba fun saa ikeji.
Ki lo ṣẹlẹ lọjọ Aje ti wọn bura fun Gomina Makinde to mu ko juwe ile fun Auxillary?

Lẹyin gbogbo pọpọsinsin ayẹyẹ iburawọle fun saa keji gomina Seyi Makinde ni papa iṣire Ọbafẹmi Awolọwọ, ti ọpọ ṣi mọ si Liberty Stadium nilu Ibadan lọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023 ni awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ ero mejeeji, iyẹn NURTW ati RTEAN ba ni ki awọn sin Gomina de ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ikọlaba lati kii ku oriire. Ni Ibẹ ni a gbọ wi pe Auxiliary ati awọn eeyan rẹ ti pade wọn ti ọrọ si di iṣu ata yan-an-yan-an.
Ọrọ yii lo bi Gomina Ṣeyi Makinde ninu ti o si pa aṣẹ wi pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ Auxiliary ati awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ rẹ.
Lati igba ti ijọba si ti ṣe ikede yii ni ariwo ti n sọ lọtun losi lori iwa ipa ti awọn janduku kan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ ara ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to wa labẹ Auxiliary n hu lawọn agbegbe bii Olodo, Iwo Road ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni gbogbo awọn adugbo yii ni awọn eeyan ti n ke gbajare wi pe awọn n gbọ iro ibọn lakọ-lakọ.
Ninu oṣu karun ọdun 2019 ni Makinde fi ofin de ẹgbẹ awakọ NURTW ati RTEAN nitori wahala ti wọn fa lori ipo adari, lẹyin eyii si ni o ṣe idasilẹ ajọ PMS to n mojuto igbokegbodo ọkọ eleyii ti Auxiliary ati igbimọ rẹ n ṣe akoso fun.












