Ìyàtò ńláǹlà yóò bá ìpínlẹ̀ Ọyọ ni ṣáá kejì tí mò bẹrẹ .. Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Ọyọ Onimo ẹrọ Seyi Makinde kete lẹyin ibura rẹ sipo gomina fun igba ẹẹkeji ṣalaye wi pe,gbogbo opopona to wa labẹ nu nipinlẹ Oyo ni oun yo se abojuto.
Seyi Makinde ni iṣejọba ohun fun igba ẹẹkeji ti o bẹrẹ lonii ko ni tẹti lati pari awọn akanṣe iṣẹ opopona ti oun lọ lọwọ nipinlẹ Oyo.
Makinde ni ninu iṣejọba tuntun ohun gbogbo ajẹẹlẹ owo awọn oṣiṣẹ fẹyinti ni ohun o ri wipe awọn sa ń tan kí ijọba ohun to pari,ti ko si ni da ṣiṣan owo awọn oṣiṣẹ ati awọn oṣiṣẹ fẹyinti duro.
Gomina ipinlẹ Oyo ṣeleri lati mu adinku ba bi awọn ogo weere ipinlẹ Oyo ti ko si ni ile ẹkọ ku,
pẹlu bi ọmọ to to ọkẹ meji aabo ti pada si ile ẹkọ laarin ọdun mẹrin akọkọ rẹ,o ṣeleri lati ri wi pe ile eko alakọbẹrẹ àti ti girama ipinlẹ Oyo yo wa ni ṣiṣe, ti yoo si jẹ ọfẹ fun gbo awọn to n lọ si ile ẹkọ.
Pẹlu bi ipinlẹ Oyo ti n fi ida ọgọrun-un si ogun bọ bukata eto ẹkọ ipinlẹ Oyo,o ṣeleri lati ko ile ẹkọ sì kí wọn si mu atunṣe ba awọn ile ẹkọ ti o ni lọ atunṣe jakejado ipinlẹ Oyo.
Pẹlu bi idọti ti gba oju awọn opopona Ipinlẹ Oyo,Makinde ni iṣejọba tuntun ohun yo ri wi pe ẹka to risi ilani loye ni ohun yo da silẹ,láti ṣamojuto ọja tita lẹgbẹ opopona kí wọn si mojuto igokegbodo ọkọ ni ipinlẹ Oyo.
Makinde ṣeleri lati fi gbogbo ọkan rẹ ṣiṣẹ kí ipinlẹ Oyo lè gunke agba.
Iye dúkìá mi báyìí ti dínkù sí iye tí mo kó wọ ìṣèjọba lọ́dún 2019 – Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti sọ pe iye dukia ti oun ni ti dinku si ju ti igba ti oun kọkọ gori alefa lọ.
Makinde lo sọ ọrọ naa lọjọ Ẹti lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to kede iye dukia to ni ni ọọfisi ajọ to n yẹ iye dukia ti awọn oloṣelu ni wo, CCB, niluu Ibadan.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lọdun 2019 ni Makinde kọkọ kede iye dukia to ni ko to bẹrẹ saa rẹ gẹgẹ bii gomina, ti iye gbogbo ohun to ni si le diẹ ni biliọnu mejidinlaadọta.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe dandan ni oloṣelu kede iye dukia to ni, amọ o tọna ki wọn ṣe bẹẹ.
O ni “Gẹgẹ bii alakalẹ ofin, o yẹ ki eeyan kede iye dukia to ni ko to gori alefa ati lẹyin saa rẹ, niwọn igba ti saa wa akọkọ ti n lọ sopin, mo gbọdọ kede iye dukia mi ki a to tun bẹrẹ saa mii.”
“Idi ree ti mo fi wa sibi lati kede iye dukia ti mo ki a to bẹrẹ saa keji.”
“Mo mọ ope gbogbo yin ni ẹ mọ iye dukia ti mo ni ki a bẹrẹ saa akọkọ, amọ fẹ sọ fun yin pe laarin ọdun mẹrin, dukia mi ti dinkun ju ti tẹlẹ lọ nitori mi o ri aye lati bojuto awọn okowo mi.”
“Ọrọ bi ipinlẹ Oyo yoo ṣe dara ni a gbajumọ, nitori naa ko yami lẹnu bi nnkan ṣe ri amọ ko sewu.”
Ti ẹ ko ba gbabe, ọdun 2019 ni agbẹnusọ Makinde, Taiwo Adisa kede gbogbo dukia gomina ọhun ti iye rẹ si jẹ ₦48b.
₦48b naa jẹ apapọ owo to ni lọwọ, ni banki, to fi mọ awọn ile loriṣiriṣi atawọn ohun to wa ninu ile naa.
Lara awọn dukia naa tun ni awọn ohun idokowo oniruru lawọn ile ifowopamọ to jẹ ti gomina ọhun, iyawo rẹ atawọn eyii to jẹ ti awọn ileeṣẹ rẹ.
Lara awọn ileeṣẹ to jẹ ti Makinde ti Adisa kede ni Makon Engineering and Technical Services Limited; Energy Traders and Technical Services Limited; ati Makon Oil and Gas Limited.
Oun naa lo tun ni Makon Group Limited, Makon Construction Limited ati Makon Power System Limited












