Ṣe lootọ? Albino: Tolani Ajayi: Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti fi tọ́jú ọmọ àfín

Àkọlé fídíò, Ṣe lootọ;Njẹ́ o ní nkán tí èèyàn lè ṣe tí kò bá fẹ bí ọmọ àfín

Njẹ́ o ní nkán tí èèyàn lè ṣe tí kò bá fẹ bí ọmọ àfín?

Lori eto wa ''Ṣe lootọ?'' lọsẹ yii, awọn orisi ahesọ ọrọ nipa ibalopo ati iru ọmọ ti yoo fi bi ati iru itọju to yẹ wọn la gbe yẹwọ.

Yatọ si awọn eleyi ti o ṣeeṣe ki ẹ ti gbọ nipa iru ọmọ ti eeyan le bi to ba ni ibalopọ lọsan ti oorun mu tabi lowurọ kutu, a tun bi akọṣẹmọṣẹ onimọ wa nipa afin ati ohun ti o rọ mọ ki eeyan bi afin.

Idahun si ibeere na wa ninu fidio yii.

Se looto Aafin Albino

Oríṣun àwòrán, BBC / Jason

Iru ọmọ wo ni a n bi ti a ba sun oorun wọn ni ọsan gangan, idaji tabi ni iyalẹta?

Arabinrin Tolani Ajayi to jẹ akọṣẹmọsẹ nipa ọrọ ọmọ bibi ati itọju oyun ṣalaye kikun lori awọn iru awọn igbagbọ ti kii ṣe ootọ lori afin.

Bakan naa lo mẹnuba irọ to wa ninu ọrọ ati igbagbọ pe obinrin jẹ eewọ tabi rin irinkurin lo ṣe bi aafin lọmọ.

Ẹ wa nkan fidi le lati gbadun awọn alaye ti dokita wa ṣe ni paapa iru nkan ti o le ṣokunfa ki eeyan bi ọmọ afin ati iru itọju ti wọn nilo taa ba bi wọn tan.