Ó dìgbà tí a bá ń lo ọ̀nà ìṣẹ̀ǹbáyé láti fi sèbúra ní àwọn adarí wa yóò tó dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́- Baba Ẹlẹbuibọn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan gboogi lara adari onimọ iṣegun ibilẹ ati imọ ifa ni ilẹ Yoruba, Baba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti rọ awọn adari lorilẹede Naijiria lo ọna iṣẹṣe fun iburawọle lẹyin idibo.

Baba Elebuiobọn lo sọ ọrọ yii lasiko to n dahun si ibeere awọn eniyan to n lọgun pe ki wọn lo ọna iṣẹnbaye fi bura wọle fun awọn adari.

Ninu ọrọ rẹ baba Elebuibọn ni lilo awọn ọna iṣẹmbaye fun iburawọle ni Naijiria ni ọna abayọ si iṣejọba to wuyi lawujọ.

‘’Awọn eniyan kan n bura eke ni.’’

O ni kii ṣe igba akọkọ niyii ti awọn yoo kede fun awọn araalu ki wọn gba iṣẹṣe laaye.

O ni ‘’a ti n ke ati n sọ nipa rẹ amọ wọn kọ eti ikun si wa.’’

‘’Ọkan lara awọn ohun to jẹ ki iwa ajẹbanu wọpọ lawujọ wa ni Bibeli ati Quran ti awọn adari wa fi n burawọle’’

‘’Awọn adari wa n seleri ki wọn to de ipo amọ ti wọn ba ti wọle tan, ọrọ n ba ibomiran lọ.’’

‘’Gbogbo igba ti a ba ti ri pe aiṣedede wa, ti a ma n pariwo sita fun awọn araalu.’’

‘’O diba ti a ba n lo nkan abinibi wa lati fi sebura ni nkan a rọrun fun awọn ara ilu’’

‘’Awọn nkan iṣẹbaye wa kii gbabọde...’’

Baba Elebuibọn ni awọn adari ko lee fi ogun bura, ki wọn ma ri ipa rẹ.

‘’Amọ wọn a ni wọn ki n ṣe ẹlẹsin ibilẹ nitori Kristẹni ati Musulumi ni wọn, wọn ko le bura pẹlu nkan iṣẹbaye’’

‘’Lati igba ti wọn ti n lo Bibeli ati Quran, wọn kan n tan wa jẹ ni’’

‘’Nigba ti wọn burawọle fun Olootu Ilẹ Gẹẹsi, o ni ẹtutu to ṣe si bẹ, ki o to wọle si bẹ’’

‘’Lati igba lailai ni awọn baba nla wa ti fi ilana yii silẹ.’’

Ki awọn Yoruba lo ọna iṣẹmbaye wọn, ki awọn Hausa lo ti wọn , ki awọn igbo naa lo ti wọn.

Bakan naa lo rọ ijọba ki wọn ṣe ofin tuntun ti yoo fi aye gba eto iṣembaye, ki wọn si fi sinu iwe ofin.

‘’Yoo jẹ ki a ni ilọsiwaju, awọn eniyan ko ni ṣe ilẹri ti wọn ko ni lee mu ṣẹ.’’

‘’A ti n gbe igbesẹ ti a n polongo amoọ wọn ko da wa lohun, wọn ko si yasi.

‘’Amọ pe ọjọ kan yoo jẹ ọkan kan, ilọsiwaju yoo deba Niajiria.’’

Ki wọn fi ogun tabi iyẹpẹ bura, yoo jẹ ki awọn eniyan sun ra ki, ki wọn si ṣe ohun to tọ.’’

Yemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, @Yemi Elebuibon

Baba Elebuibọn gbadura fun aarẹ tuntun, Bola Ahmed Tinubu

Bakan naa ni Baba Elebuibọn gbadura fun aarẹ tuntun pe ki Olodumare fun ni ọna ire, pẹlu awọn olubasisẹ to dara.

‘’Awọn alalẹ Yoruba yoo ti leke.’’

‘’Opẹ la da pe iran Yoruba de oke, to si de ipo aarẹ lasiko yii’’

‘’Aṣẹ ko ni ku mọ lọwọ, ilẹ Oodua yoo tii lẹyin o.’’