Ireti ti pada fun Naijiria – Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/twitter
Ninu ọrọ akọkọ to ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọ gẹgẹ bvi aarẹ Naijiria, Bọla Tinubu ni iṣejọba oun yoo jẹ aṣoju ọmọ Naijiria ni nigba gbogbo ati pe awọn yoo maa gba imọran kaakiri lori igbesẹ gbogbo ti awọn ba fẹ gbe.
O ni oun ko ni fi ọna kọna yan awọn to ba oun dije du ipo aarẹ ni pọṣin nitori pe ẹtọ kan naa ni awọn jumọ naa, ifẹ orilẹede Naijiria kan naa lawọn jijọ n ja a fun. O fi kun un pe ẹtọ wọn ni igbesẹ ati tọ ile ẹjọ lọ ti wọn gbe, oun si fara mọ ọ.
Tinubu ni iṣejọba oun yoo mu idagbasoke to yẹ ba ihuwasi ati igbayegbadun gbogbo ọmọ Naijiria nipa mimojuto ọrọ aje, aparo kan ko ga jukan lọ.
Ileri wo ni Aarẹ Tinubu tún ṣe?
O ni laipẹ awọn ilana eto ọrọ aje ti ijọba oun fẹ gunle yoo bẹrẹ si ni jade sita faraalu lati ri.
Aarẹ Buhari ni iṣejọba oun yoo maa bọwọ fun ofin ni igba gbogbo, yoo si daabo bo Naijiria lọwọ ikọlu gbogbo
Bakan naa lo ni ọwọ yoo kan eto ọrọ aje pẹlu idaniloju lati mu idagbasoke ba ipese iṣẹ ati didopin iṣẹ ati iya.
O ni awọn obinrin atawọn ọdọ yoo kopa to jọju ninu iṣejọba tuntun yii.
Aarẹ Tinubu ni iṣẹ kiaknkikan yoo waye lori eto abo nitori ko si bi eto ọrọ Aje ati ibọwọ fun ofin ṣe lee fi ẹsẹ rinlẹ laarin abo to mẹhẹ.
O ni atunto ilana ati eto abo pẹlu ipese koriya fun awọn oṣiṣẹ alaabo yoo moke.
O ni iṣjọba oun yoo tun mojuto ọrọ idaleeṣẹ silẹ, eyi to ni yoo le mu ki iye ọja ti a n ko lọ ta loke okun pọ ju iye ti wọn n ko wa ta lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, bola ahmed tinubu/twitter
Lori ọrọ ipese ina, o ni eto yoo kalẹ fun ipese ina o ni oun yoo ṣe eto ipese ina fun idagbasoke ọrọ aje araalu ati pe oun yoo ṣe koriya fun awọn ijọba ipinlẹ lati ṣe idasilẹ ileeṣẹ amunawa aladani tiwọn.
Bakan naa lo fi da awọn ileeṣẹ ati oludokoowo loju pe iṣejọba oun yoo ṣe agbyẹwo gbogbo ẹsun sisan owo ori lọna pupọ ati gbogbo awọn nnkan ipenija miran to n koju idokoowo silẹ.
O ni ileri oun lati pese iṣẹ miliọnu kan nipasẹ ẹka imọ ẹrọ ṣi duro dingbi.
Lori eto ọgbin, Aarẹ Tinubu ni awọn awujọ igbalode fun idagbasoke eto ọgbin yoo wa kaakiri orilẹede Naijiria lati lee mu ki iye ọgbin to n jade lorilẹede yii tubọ yanranti ki ounjẹ le pọ lọpọ yanturu faraalu.
O ni oun yoo tun tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ribiribi ti ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari gbe ṣe lẹka ipese ohun elo amayedẹrun.
Lori ọrọ owo iranwọ ori epo, Aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria ṣalaye pe inu oun dun pe wọn ti yọ sisan owo iranwọ epo, subsidy ninu iṣuna ọdun yii eyi to fihan pe owo iranwọ ori epo ti rokun igbagbe.
Lori ọrọ paṣipaarọ owo ilẹ okeere, Aarẹ Tinubu sọ pe ko ni si ọja paṣipaarọ olojumeji mọ nitori pe banki apapọ labẹ iṣejọba oun yoo wọgile












