
Bola Tinubu: Báyìí ni afọbajẹ ní Nàìjíríà ṣe jọba
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì nínú ètò òṣèlú Ààrẹ tuntun Nàìjíríà
Ní ọjọ́ kìíní oṣù Kẹta, wọ́n kéde Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò ààrẹ tó tí ọ̀pọ̀ gbà pé òhun ló fẹ́ ẹ̀ lágbára jù láti ìgbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti padà sí ìjọba àwaarawa láti ọdún 1999.
Onírúurú awuyewuye ló ti ń wáyé láti ìgbà tí wọ́n ti kéde rẹ̀ bí ààrẹ tí ìlú dìbò yàn, tí àwọn olùdíje méjì sì ti wọ lọ sílé ẹjọ́. Àmọ́ fún àwọn alátìlẹyìn Tinubu, ìjáwé olúborí rẹ̀ jẹ́ àfihàn àti ìkórè gbogbo ipa Tinubu sí òṣèlú Nàìjíríà láti ọjọ́ pípẹ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn lámèyítọ́ ló tún ti fi ìkọnilóminú wọn hàn lórí ìlera àti ọrọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kan gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ rí ọ̀hún ṣùgbọ́n tó jiyàn gbogbo ẹ̀sùn náà.
Lára àwọn ìpèníjà tí ìjọba Tinubu máa gbà lọ́wọ́ ìjọba tó ń lọ ni ètò ọrọ̀ ajé tí kò ra jaja àti orílẹ̀ èdè tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ àmọ́ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ní ó le lo ìrírí rẹ̀ nígbà tó ṣe gómìnà láti fi mú àyípadà ọ̀tun bá Nàìjíríà.













2023
Ìdá mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kejì ni Tinubu ní. Iṣẹ́ ńlá ló wà níwájú Tinubu bí orílẹ̀ èdè tó tóbi jùlọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ ṣe ń kojú ìpèníjà ètò ààbò, ọ̀wọ́n gógó àti àìsíṣẹ́. Tinubu ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri dájú pé Nàìjíríà wà ní ìṣọ̀kan àti pé òun máa mú àyípadà ọ̀tun bá ètò ọrọ̀ ajé.



2022
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, Tinubu kéde èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò ààrẹ. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan awuyewuye ló wáyé lásìkò tó ń ṣe ìpolongo ìbò lórí ọjọ́ orí rẹ̀, ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu àti lórí ẹni tó yàn gẹ́gẹ́ bí igbákejì - Mùsùlùmí láti ẹkùn àríwá - èyí tí àwọn kan ní ó lòdì sí bí àwọn olóṣèlú ṣe máa ń yan ẹlẹ́sìn méjéèjì.



2021
Ṣáájú ni Dapo Apara, tó jẹ́ olùṣirò owó àti ọ̀gá àgbà ní ilé iṣẹ́ Alpha-Beta, iléeṣẹ́ tó ń rí sí pípawó lábẹ́ lé fún ìpínlẹ̀ Eko. Ó fi ẹ̀sùn kan gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Eko náà pé ó ń fi ilé iṣẹ́ náà hùwà jìbìtì, Pa owó ìlú ní póńpó. Ó fẹ̀sùn kàn pé Tinubu lówó nínú ilé iṣẹ́ náà àmọ́ ó ń lo ènìyàn kan ni. Wọ́n padà gbé ẹjọ́ náà kúrò nílé ẹjọ́ láti lọ yanjú rẹ̀ láàárín ara wọn lẹ́yìn ọdún kan ni.

Ní alẹ́ tí ètò ìdìbò ààrẹ ku ọ̀la, fídíò ọkọ̀ tó máa ń gbé owó tó ń wọ ilé Tinubu ní Eko gba orí ayélujára, tí àwọn kan sì ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ fi owó náà ra ìbò ni. Ààrẹ Muhammadu Buhari ló wọlé fún sáà ìkejì níbi ètò ìdìbò ọdún náà.

Wọ́n dìbò yan Ààrẹ Buhari èyí tó mú òpin dé bá ọdún mẹ́rìndínlógún tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti fi ṣe ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Tinubu fọwọ́ àtìlẹyìn tó ṣe fún ìjáwé olúborí Buhari gbáyà nígbà tí òun náà ń wá ipò yìí lọ́dún 2022.
Àtẹ̀jáde kan tí ilé iṣẹ́ ìròyìn AIT gbé jáde tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní 'The Lion of Bourdillon' ni wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà àjẹbánu àti pé òun ló ń ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Eko. Tinubu gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́ fẹ́sùn ìbanilórúkọ jẹ́, tó sì ní kí wọ́n sàn mílíọ̀nù àádọ́jọ náírà fún òun, kí wọ́n sì yọ fídíò ọ̀hún kúrò lórí afẹ́fẹ́. Wọ́n padà parí ẹjọ́ náà kúrò nílé ẹjọ́.

2013
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò mẹ́rin tó tóbi jùlọ darapọ̀ láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) láti kojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP níbi ètò ìdìbò ọdún 2015. Tinubu wà lára àwọn tó ṣe ìdúnàádúrà níbi tí wọ́n ti panupọ̀ láti yan ọ̀gágun Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ wọn.

2011
Tinubu kojú àjọ 'Code of Conduct' fún ìgbà kejì àmọ́ ó yege.



2007
Tinubu parí sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Eko ṣùgbọ́n ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí 'bàbá ìsàlẹ̀' tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé kò juwọ́ ètò ìsúná ìpínlẹ̀ Eko sílẹ̀. Bákan náà ni wọ́n ní òun ló ń yan àwọn gómìnà tó ti ń jẹ lẹ́yìn rẹ̀.
Code of Conduct ti kọ́kọ́ fi òfin gbé wí pé ó ń ṣe àmúlò akoto owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́ lásìkò tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà. Ó jiyàn ẹ̀sùn náà.

2003
Tinubu jáwé olúborí sípò gómìnà Eko fún sáà kejì. Wọ́n ní ó mú ìgbòrò bá owó tó ń wọ akoto ìpínlẹ̀ Eko latara ìdókoòwò ilẹ̀ òkèrè, tí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ní àwọn òpópónà ni wọ́n tún ṣe títì tó já gaara sí. Àmọ́ àwọn lámèyítọ́ ni àwọn ohun amáyédẹrùn ní ìpínlẹ̀ Eko kò dára tó àti pé àkànṣe iṣẹ́ ojú irin tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tó ti wà nípò kò I tíì parí lẹ́yìn ogún ọdún tó ti fipò náà sílẹ̀.


1999
Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà sí ètò ìjọba àwaarawa. Olusegun Obasanjo ni wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, tí wọ́n sì dìbò yan Tinubu gẹ́gẹ́ bí gómìnà Eko lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance Democracy. Láàárín oṣù kejì ọdún 1976 sí 1979 ni Obasanjo kọ́kọ́ tukọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ológun.

1998
Ìṣèjọba ọdún márùn-ún Sanni Abacha wá sópin nígbà tó papòdà nínú oṣù Kẹfà. Tinubu padà sílé láti ibi tó sálọ lẹ́yìn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

1994
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń jà fún ìṣèjọba àwaarawa tó fi mọ́ Tinubu sá kúrò ní Nàìjíríà lọ sí ìlú òyìnbó láti bọ́ lọ́wọ́ ìyà Abacha.


1993
Ní ọdún 1993 ni wàhálà bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀gágun Ibrahim Babagida wọ́gilé ètò ìdìbò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbà wí pé òhun ló dára jùlọ ní Nàìjíríà. Sani Abacha gba àkóso Nàìjíríà lọ́wọ́ ìjọba fìdí ẹ lẹ́yìn ètò ìdìtẹ̀gbàjọba kan. Ìṣèjọba rẹ̀ ló kún fún títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ àti ìwà ìbàjẹ́. Wọ́n sì sọ Moshood Abiola tó jáwé olúborí ètò ìdìbò náà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe àkójọ àwọn ẹ̀sùn kalẹ̀ pé láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1988, wọ́n ṣí àwọn akoto owó kan lórúkọ Bola Tinubu lèyí tí wọ́n ń kó èrè egbògi heroin funfun sí. Wọ́n ní Tinubu ṣiṣẹ́ fún afurasí gbòógì lórí ẹ̀sùn náà, Adegboyega Akande. Ilé ẹjọ́ ní àwọn gbàgbọ́ pé àwọn owó tó wà nínú akoto náà ló jẹ́ èrè egbògi olóró àmọ́ wọn ò ní Tinubu jẹ̀bi ẹ̀sùn náà. Dípò bẹ́ẹ̀ ó gbà láti juwọ́ owó $460,000 kalẹ̀ fún ìjọba Amẹ́ríkà.

1992
Nígbà yìí ni ìrìnàjò òṣèlú Tinubu bẹ̀rẹ̀ bí wọ́n ṣe dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ láti ṣojú ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Eko lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party. Òun ló ṣe alága ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé ìfowópamọ́, ìsúná àti owó.

1980
Tinubu ní òun ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ Amẹ́ríkà kan, Deloitte gẹ́gẹ́ bí "Auditor" fún Mobil oil kí òun tó padà sí Nàìjíríà.


1979
Ọ̀pọ̀ ló máa ń wádìí Tinubu pàápàá lásìkò ìbò àmọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Chicago State University fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Tinubu kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́dọ̀ àwọn nínú ìmọ̀ ètò káràkátà ìyẹn Business Administration lọ́dún 1979.

1970
Kò sí ìròyìn tó bẹ́ẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìgbésí ayé àti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí Tinubu lọ àmọ́ ọ̀pọ̀ ló gbà pé ní àárín ọdún 1970 ló kó lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

1952
Gẹ́gẹ́ bí ìtàkùn ojú òpó ayélujára ìpolongo kan ṣe sọ, ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ọdún 1952 ni wọ́n bí Tinubu ní ìpínlẹ̀ Eko, Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀ ni kò gba ọjọ́ orí Tinubu yìí gbọ́, wọ́n ní ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Bola Ahmed Tinubu: Wo ǹkan tó yé kí o mọ̀ nípa Bola Ahmed Tinubu, ààrẹ tuntun ní Nàíjíríà
Nigeria Presidential elections 2023: Wo èsì ìbò ààrẹ fún Tinubu, Atiku, Kwankwaso, Obi
Nigeria election: Àṣírí àwọn èsì ìdìbò tí wọ́n kọwọ́ bọ̀ lójú rèé