Nigeria election: Àṣírí àwọn èsì ìdìbò tí wọ́n kọwọ́ bọ̀ lójú rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Chiagozie Nwonwu, Peter Mwai & Karina Igonikon
- Role, BBC News
Nigba ti oṣiṣẹ ajọ eleto idibo kan ka esi idibo aarẹ jade fun agbegbe tirẹ ni iha Guusu naijiria, o jẹ iroyin ibanujẹ fun awọn ẹgbẹ alatako si bi wn ṣe kede oludije ẹgbẹ to wa lori alefa, Bola Tinubu.
Ati wipe lẹyin ti wọn ti kede Ọgbẹni Tinubu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lẹyin ọjọ diẹ, awọn oludije to lulẹ ti gun le igbesẹ ofin lati tako esi ati ikede rẹ.
Nibayii, iwadii BBC kan ti ri awọn ẹri to fihan wipe o ṣeeṣe ki awọn esi kan ni ipinlẹ Rivers to jẹ ọkan lara awọn oju ina lasiko idibo jẹ eyi ti wọn ti kọwọ bọ.
Oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, INEC to ka lara awọn esi idibo naa jade, Ọmọwe Dickson Ariaga ko tii fesi si awọn ibeere wa.
Wọnyii ni awọn nnkan ti a ṣawari nigba ti a boju wo eto idibo ọhun to da aawọ silẹ.
Ilana bi wọn ṣe ka esi idibo ni Naijiria
Ni ọjọ karundinlọgbọn Oṣu Keji, awọn ọmọ Naijiria tu jade lọgọọrọ lati dibo jakejado orilẹede.
Ni ibudo idibo kọọkan, ibo to wa fun oludije kọọkan jẹ eyi ti wọn ka sita ni gbangba bẹẹ si ni wọn ko awọn aksilẹ ibo naa lọ fun kikojọ lakkọ ni ipele ti wọdu, lẹyin ni ipele ijọba ibilẹ.
Oṣiṣẹ ajọ eleto idibo lati ijọba ibilẹ yoo wa rinrinajo lọ si olu ilu ipinlẹ naa nibi ti wọn yoo ti kede esi gaan ni ilana ofin.

Fun igba akọkọ ni Naijiria, wọn gbe aworan esi idibo lati awọn ibudo idibo soju opo ajọ eleto idibo.
Eyi jẹ ko ṣeeṣe lati ṣe aropọ gbogbo esi idibo awọn ibudo idibo ati lati gbe wọn yẹwọ sira wọn pẹlu awọn esi idbo ti wọn kede ni ipele ti ipinlẹ.
Ohun ti BBC ṣawari ni ipinlẹ Rivers
Ikọ wa ṣe aropọ awọn aksilẹ iwe esi idibo to jade lati ibudo idibo ẹgbẹrun mẹfa nipinlẹ rivers, eyi to jẹ ibi ti fa ki n fa a awọn ẹgbẹ alatako ti jẹ jade ju.
nigba ti ojulowo esi ti ajọ INEC kede fihan pe Bola Tinubu ti ẹgbẹ All Progressives Congress lo ko ibo to pọ ju, aropọ tiwa fihan pe Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party lo ko ibo to pọ ju ni ipinlẹ naa pẹlu ila to pọ gidi.

A rii wipe ibo kan lọ soke pẹlu ibo 106,000ninu ti Ọgbẹni Tinubu gẹgẹ bi ikede to jade amọ nigba taa gbe e yẹwo pẹlu aropọ tiwa lawọn ibudo idibo, o fẹrẹ to ilọpo meji to fi gbogbo ibo ti o ni ni ipinlẹ naa.
Ni idakeji, ibo ti Ọgbẹni Obi ti ja walẹ pẹlu iye to le ni 50,000.
O ṣe pataki lati jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ wipe a wa a kaakiri gbogbo oju opo eto idibo fun gbogbo ibudo idibo 6,866 to wa nipinlẹ Rivers, a ko ri esi idibo kankan mu jade lọdọ gbogbo wọn.
Awọn mii wa to jẹ pe ọna ti ko tọ ni wọn fi gbe wọn sibẹ.
Fun nnkan bii ida marun ninu ida ọgọrun ibudo idibo, awọn aworan iwe aksilẹ esi idibo ko han daadaa ti eeyan yoo fi rii ka. Ireti ni wipe o yẹ ki ojulowo eyi ti ajọ eleto idibo n ka yoo fi eyi han niwọn igba to jẹ wipe wọn yoo ni ojulowo awọn iwe ọhun lọwọ.
Ni ida mẹtadinlogun miran, ko si esi idibo rara ti wọn gbe sori ayelujara fun awọn ibudo idibo to ṣe koko. Ọpọlpọ eyi ni ko ba jẹ awọn ibudo idibo ti idibo ko ti waye nitori iṣoro aabo tabi bi awọn ohun elo fun idibo ko ṣe tete de ibẹ.
awọn mii ni isọri yii ko ba jẹ pe boya ipenija imọ ẹrọ ni ko jẹ ki awọn oṣiṣẹ ri bi gbe awọn iwe esi idibo naa sori ayelujara.
Nitori naa, o ṣeeṣe ki awọn ibudo idibo mii ṣi wa daadaa ti o yẹ ko hande ninu ojulowo esi idibo to jade nigbẹhin gbẹhin, eyi to tilẹ le ma si ninu iwadii BBC.
Ẹwẹ, aropọ awọn iwe esi idibo yii yẹ ko jẹ pe wọn lo o lati jẹ bii afikun ibo fun ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni kii ṣe lati mu adinku ba wọn.
Ati pe, ohun ti a ri ni pe awọn ibo Peter Obi ti Labour Party ti sare dinku ni ipinlẹ Rivers - eyi jẹ abajade ti ko ṣee ṣalaye nipa titọka si awọn iwe akọsilẹ esi idibo ti ko si ninu awọn ti BBC ka.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibo gaan wa ni awọn iyatọ gboogi ti waye?
Ibi meji pato lo da yatọ
Akọkọ́ ni ijba ibilẹ Oyigbo, nibi taa ti rii pe:
- Iye ibo ti Bola Tinubu fi ilọpo mẹfa pọ sii ninu iwe ti wọn ti ka esi idibo jade bi a ba gbe e yẹwo pẹlu eyi ti BBC ka ni ibudo idibo
- Ibo ti Peter Obi ti di gige ku si àbọ̀

Ijọba ibilẹ keji niubi ti a ti ri magomago ibo ni ijọba ibilẹ alamuleti yii, Obio/Akpor:
- Ojulowo esi idibo Ọgbẹni Tinubu to jade ni 80,239ṣugbọn a ri ibo 17,293nibi aropọ ti a ṣe ni ibudo idibo
- Onka esi idibo ti Ọgbẹni Obi ti wọn ka jade jẹ 3,829amọ BBC rii pe 74,033 lo wa fun un lori aropọ ti ibudo idibo

Báwo ni àwọn ìyàtọ̀ ṣe wáyé?
A fẹ mọ ibi ti kudiẹkudiẹ ti waye to fi wa mu iyatọ ba iye ti awọn alaṣẹ eto idibo kede ati iye ti wọn gbe kuro ni ibudo idibo.
Gẹgẹ bi a ti ṣalaya siwaju, gbogbo awọn esi ibo ibudo kọọkan ni wọn ṣe akojọ rẹ ni oriko ijọba ibilẹ kọọkan.
A ṣawari akọọlẹ esi ibo ijọba ibilẹ Oyibo ti awọn alaṣẹ eto ibo àti awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan buwọlu.

Ọpọ awọn aworan esi ibo ibudo ibo ni ijọba ibilẹ yii ni lo wa ni ori ayelujara.
Awọn esi to wa ninu aworan yii lo wa ni ibamu pẹlu nnkan ti ileeṣẹ wa ṣawari rẹ iyẹn Tinubu ati Peter Obi.
Ọkan lara awọn esi ibo ijọba ninu ijọba ibilẹ mẹtalelogun ni ipinlẹ Rivers ti wọn ka fun gbogbo eniyan niyi.
Ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2022 ni aṣoju INEC fun ijọba ibilẹ Oyigbo, Dokita Dickson Ariaga kede orukọ rẹ to si ni lati ile ẹkọ giga olukọni to wa ni Omoku ni oun n ṣiṣẹ fun.
Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni ka awọn esi ibo bẹrẹ lati ori ẹgbẹ oṣelu A titi de ipari.

Akiyesi ti a ṣe ni pe gbogbo awọn esi ibo ẹgbẹ kọọkan to ka lo jọ ara wọn pẹlu ti iwadii wa amọ́ nigba to dori APC, dipo ko pe 2,731 to wa lori iwe akọsilẹ "16,630" lo pe jade.
Bẹẹ naa lo ri nigba to de ibi ibo Peter Obi, kaka ko pe 22,289 gẹgẹ bi bo ṣe wa ninu akọọlẹ naa, "10,784" lo tun pe ni eyi to fi din ibo Peter Obi ku.
Awọn nnkan to rọ mọ Dickson Ariaga
A beere lọwọ ajọ eleto ibo boya a le ba Dokita Ariaga sọrọ amọ wọn kọ lati fun wa ni ẹrọ ibanisọrọ rẹ tabi ba wa kan si rara.
Bakan naa la tun gbiyanju lati ba obinrin to jẹ oṣiṣẹ INEC to jokoo tii lasiko ibo sọrọ ṣugbọn o ni ajọ awọn ko gba oun laaye lati ba ileeṣẹ iroyin kankan sọrọ.
Eyi lo mu wa ran akọroyin wa kan lọ si ile ẹkọ olukọni Omoku nibi to sọ wi pe oun ti n ṣiṣẹ.
Nigba ti a debẹ, igbakeji ọga agba ile ẹkọ naa ni ko si ẹni to n jẹ bẹẹ ni ile ẹkọ awọn rara.

A gbiyanju lati wa lori ayelujara ti a si ri ẹni kan lori Facebook to n gbe ni Port Harcourt ti orukọ rẹ yatọ si eyi ti Ariaga da.
Nigba ti a ṣe ayẹwo aworan to wa lori atẹ Facebook naa pẹlu aworan ti Ariaga nigba to wa ka esi ibo naa, ẹ̀rọ Amazon Rekognition jẹ ko ye wa pe eniyan kan naa ni awọn mejeeji.
Dr Ariaga ko fun wa lesi si gbogbo awọn atẹjiṣẹ ta kọ ranṣẹ si lori ikanni yii.
A tun kan sawọn ọrẹ rẹ lori ikanni yii ti a si ni anfani lati ba ọkunrin kan to pe ara rẹ ni mọlẹbi Ariaga to si gba lati ran wa lọwọ lori bi a ṣe le ri.
Amọ nigba to ya ọkunrin naa kọ lati dawa lohun mọ, koda ko gbe ipe wa mọ.
Ki ni ileeṣẹ eto idibo sọ?
Nigba ti a ṣe awari awọn ẹri yii, a kan si àjọ INEC lori awọn iwadii wa.
Johnson Sinikiem to jẹ agbẹnusọ INEC ni ẹkun Part Harcourt sọ fun wa pe nitori aisi aaye ati akoko to bẹẹ gẹ, awọn ko ni anfani lati ṣayẹwo gbogbo awọn ti awọn lo fun eto idibo naa.
Nigba to n sọrọ Ariaga, o ni to ba jẹ wi pe Ariaga kii ṣe olukọ ni ile ẹkọ to sọ fun awọn, a jẹ wi pe o parọ fun awọn niyẹn ati pe opurọ ni.
Bakan naa ni a tun kan si INEC ni ilu Abuja lati ṣafihan awọn nnkan ti a ṣe awari rẹ ni ipinlẹ Rivers amọ wọn kọ lati sọ ohunkohun lori rẹ.
Wọn ni awọn ko ni le sọrọ lori rẹ nitori ọrọ ibo naa ti wa ni ile ẹjọ.
Nnkan ti awọn ohun ti a ṣawari le fa fun ibo apapọ
Ọrọ ipinlẹ kan ninu awọn ipinlẹ ẹkun guusu Naijiria niyi, ni eyi to n ṣafihan pe awọn magomago kan waye lasiko ibo aarẹ to kọja.
Esi ibo yii le ma ni ipa kankan lori apapọ esi ibo aarẹ to kọja.
Bola Tinubu lo gbegba oroke ninu esi ibo aarẹ Naijiria tọdun 2023 ti Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP si gba ipo keji.
A gbiyanju lati ṣe iwadii de awọn ipinlẹ miiran ni ẹkun ariwa ati iwọ oorun guusu Naijiria ṣugbọn a o ri ibi ti iyatọ ti pọ bayii bii ti ipinlẹ Rivers.A ṣi n wa Dokita Ariaga lati wa fesi sawọn ẹsun ti a fi kan an ninu ijabọ yii.
Afikun iroyin wa latọwọ Liana Bravo, Jemimah Herd, Jake Horton ati Kumar Malhotra












