Tinubu yóò gbà ọ̀pá àṣẹ lónìí: ẹ wo àwọn nǹkan tó ti là kọjá ṣáájú

Oríṣun àwòrán, @Tinubu
Ààrẹ tuntun naa, Bola Ahmed Tinubu, ni ilu dibo yan ninu eto idibo to waye lọjọ kej, oṣu Kẹta, ọdún 2023.
Bola Tinubu ni aarẹ karun-un ti yoo jẹ, lati igba ti Naijiria ti pada si iṣejọba awaarawa lọdun 1999.
Sugbọn saaju ko to dije fun ipo aarẹ, Tinubu ti jẹ gomina nipinlẹ Eko laarin ọdun 1999 si 2007 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ oselu Alliance for Democracy (AD).
Bakan naa lo jẹ sẹ́nétọ̀ ni ọdun 1992 sí 1993 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party (SDP). Lẹyin to kuro ni ipo gomina, lo di ẹni ti a le pe
Irinajo Tinubu gẹgẹ bi oloṣelu ni agbo oṣelu Naijiria ko ṣe e fi ọwọ́ rọ́ ṣeyin rara.
Ọ̀pọ̀ ti ẹ ma n sọ pe odindi ile ẹ̀kọ́ oṣelu ni Tinubu, ti àwọn kan tun n pe ni Jagaban, jẹ́.
Bo ṣe kuro ni ipo gomina ipinlẹ Eko, lo ti di afọbajẹ oloṣelu, to bẹẹ ti ko si ẹnikẹ́ni to fẹ de ipo pataki lagbo oṣelu ni ilẹ̀ Yoruba, paapaa ninu ẹgbẹ́ oṣelu rẹ̀ tí ko ni fi ti Tinubu ṣe.
Diẹdiẹ ni agbara oṣelu ti Tinubu ní, tàn de awọn agbegbe miran ni Naijiria - Gusu, Ariwa, Ila Oorun ati Ìwọ oorun.
- Iye dúkìá mi báyìí ti dínkù sí iye tí mo kó wọ ìṣèjọba lọ́dún 2019 – Makinde
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajìjàgbara ‘Yoruba Nation’ làwọn jàǹdùkú tó kọlú iléeṣẹ́ rédíò Amuludun n’Ibadan - Ọlọ́pàá
- Ẹ̀yin aráàlú, ẹ gba àlááfíà láàyé, kí ẹ sì tẹ̀lẹ́ òfin lásìkò ìbúrawọlé – Peter Obi
- Ààrẹ Buhari tọrọ àforíjì ní ọwọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀
- Àlàyé rèé lórí bí ogójì Ọ̀ọ̀ni ṣe ṣekúpa olórí ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀
- ''Mi ò kábámọ̀ nípa ohunkóhun''– Wike
Kini Tinubu ti ṣe sẹyin lagbo oṣelu?
Lara àwọn ipa rẹ ni agbo oṣelu, ni ṣíṣe agbatẹru bi ẹgbẹ́ oṣelu AD to pada di Action Congress of Nigeria (ACN) ṣe di ọkan ṣoṣo pẹlu ẹgbẹ́ oṣelu All Nigeria Peoples Party (ANPP), Congress for Progressive Change (CPC), àti àwọn díẹ̀ to yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP àti All Progressives Grand Alliance (APGA).
Àpapọ̀ wọn lo di ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC) lọ́dún 2013, tí wọ́n sì gba ìjọba mọ ẹgbẹ́ Peoples Democratic Party (PDP) lọwọ, lẹ́yìn ọdun mẹrindinlogun ti wọn ti wa nipo isakoso.
Idapọ wọn lo gbe Ààrẹ Muhammadu Buhari wọlé lọdun 2015, lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti n gbiyanju lati di aarẹ Naijiria.
Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ ti pẹ ti iroyin ti n jade pé Tinubu fẹ dije du ipo aarẹ Naijiria, ọdún 2022 lo to o fi ẹnu ara rẹ kede.
Lati ọjọ kini to ti kede si ni atako ti dide si, ninu ẹgbẹ́ oṣelu APC, laarin ẹ̀yà Yorùbá, agbo ẹ̀sìn, ati laarin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ.
Idi ree ti mo se fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria:
Ninu alaye rẹ, Tinubu ni oun fẹ pese ọjọ ọla to duro re silẹ fun iran to n bọ, ni oun se fi ara oun silẹ lati dije fun ipo aarẹ.
Bakan naa ni asaaju ẹgbẹ APC yii salaye pe Naijiria nilo asaaju rere ni kiakia, ti yoo mu irẹpọ pada saarin awọn ẹya ati ede to wa lorilẹede yii.
"A ti yan isejọba awa ara wa, a ko si gbọdọ kuna ninu ojuse wa. Mo fẹ dije lati sọ ireti awọn ọmọ Naijiria ninu orilẹede yii dọtun.
- Ẹ̀yin tẹ́ẹ fẹ́ máa ṣe -prank- pa owó bíi tèmí, ẹ má dán an wòo torí adúrú ìyà tó ń jẹ mi yìí - Trinity guy
- 'Ọdún 500 sẹ́yìn ni ọmọ Ọba Aláàfin Oyo tẹ ìlú Ondo dó'
- Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá -Part 2 Ti Oluwa Nile- dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande
- 'Ọ̀rá tó tó 35,000 ni mo ṣà jọ láti fi kọ́ ilé mi yìí'
- Ìpọ̀njú àti ikú ọkọ mí ló sún mí dé ìdí bàtà ṣíṣe- Monsurat Oyedeji
- Kí ni ìwọ mọ ''Perfume'' sí lédè Yorùbá
Bakan naa ni mo tun fẹ ki ọjọ ọla rere to dara wa fawọn ọmọ wa.
A ko nii ṣe alaimẹnuba díẹ̀ lara awọn ìdojúkọ ati ipenija ti Tinubu ba pade, ko to o di aarẹ.
Kò sí àrídájú ìlú tí Tinubu ti wá, kí ni ọjọ́ orí rẹ̀ àti ìdí ọrọ̀ rẹ̀?
Lára àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu tún dojú kọ ni ìbéèrè àti awuyewuye nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò hàn sí àwọn ènìyàn nípa Tinubu, pàápàá bíi ìlú abínibí rẹ̀, iye ọjọ́ orí rẹ̀ àti bó ṣe kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ.
Tinubu náà kò sì fi ìgbà kankan fèsì sí àwọn ìbéèrè yìí rí.
Fún ìgbà pípẹ́, ṣáájú ìdìbò àti lẹ́yìn ìdìbò, ní àwọn èèyàn kan ń fi ẹ̀sùn ṣíṣe owó òògùn olóró kan Tinubu.
'Ìkùnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC'
Lára àwọn ìpèníjà tí Tinubu tún dojú kọ ni pé, àwọn ènìyàn kan gbàgbọ́ pé gbogbo àdéhùn tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣaájú ètò idibo ọdún 2015 pàápàá lórí ètò ààbò, ìwà ìbájẹ àti ọrọ̀ ajé ni wọn kò mú ṣẹ.
Níwọ̀n ìgbà tí Bola Tinubu sì jẹ́ pàtàkì irinṣẹ́ tó gbé ẹgbẹ́ òṣèlú náà dé ipò, àwọn èèyàn kan ní òun náà ní ẹ̀bi ninu ikuna wọn, tí kò sì tọ́ fún láti di aarẹ Naijiria.
Owo Naira tuntun
Nínú oṣù ni bánkì àgbà Naijiria, CBN, pàárọ̀ awọn owo Naira kan - N1000, N500 àti N200.
Gómìnà CBN, Godwin Emefiele, ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ dandan láti le fi ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ ajé múlẹ̀, àti láti le dènà bí àwọn olóṣèlú kan ṣe n gbèrò láti ra ìbò.
Ọ̀pọ̀ eeyan ti ẹ gbagbọ pe nitori ti Bola Tinubu gan-an ni CBN ṣe gbe igbesẹ naa.
Tinubu paapaa fi ẹdun ọkan rẹ han lori eyi.

Oríṣun àwòrán, @Tinubu
Àtakò láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
Yorùbá ní tí ikú ilé kò bá pani, tóde o lè pa ni.
Àwọn gomina kan, awọn aṣòfin, ati awọn ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu APC tako Tinubu nigba to kede erongba rẹ.
Koda, awọn kan ti aye n wo gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ninu òṣèlú fun Tinubu, àwọn to ti yàn sípò rí nigba tó fi jẹ gómìnà, àti àwọn mii to ti ipasẹ rẹ de ipo oṣelu lo dide ogun si i.
Àwọn kan ti ẹ dije lati gba tikẹẹti oludije sipo aarẹ, pẹlu rẹ.
Àwọn mii sọ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ burúkú nípa rẹ̀.
Àwọn àtakò yìí mú kí Tinubu sìrègún 'oore' tó ṣe fún púpọ̀ nínú wọn, tó fi mọ́ Ààrẹ Buhari pàápàá.
Àsìkò náà ló bí gbajúgbajà ọ̀rọ̀ àṣamọ̀ 'Emi lo kan' tó di ṣajẹ báyìí.
Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
Bi Bola Ahmed Tinubu ṣe kéde hómìnà ìpínlẹ̀ Borno nígbà kan, Kashim Shettima, gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀, tún fa awuyewuye.
Èyí kò sẹ́yìn bó ṣe jẹ́ pé ẹlẹ́sìn Islam ni àwọn méjèèjì.
Àwọn èèyàn kan àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ló pariwo takò ó.
Igbàgbó àwọn èèyàn kan ni pé ọ̀nà láti sọ Naijiria di ti ẹ̀sìn islam ni.
Bí Bola Ahmed Tinubu ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ tó kọjá, kò dáwọ́ àtakò dúró.
Ìlera rẹ̀, àti orísun owó tó ní, ní aago on alátakò rẹ̀ ṣì ń bu ẹnu àtẹ́ lù.
Pátákì jùlọ, ẹgbẹ́ alátakò gbòógì méjì, Labour Party àti PDP, tí pé ẹjọ́ takò èsì ìbò tó gbé e wọlé.
Àwọn èèyàn kan ti ẹ̀ ṣe ìwọ́de, tí èèyàn bí méjì sí mẹ́ta sì pe ẹjọ́ takò bíbura fún un gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tuntun.




















