Ẹ̀yin aráàlú, ẹ gba àlááfíà láàyé, kí ẹ sì tẹ̀lẹ́ òfin lásìkò ìbúrawọlé – Peter Obi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ṣaaju iburawọle fun Bola Tinubu gẹgẹ bi aarẹ ti wọn dibo yan, oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ti gba awọn ololufẹ ati alatilẹyin rẹ ni imọran.

Peter Obi rọ awọn alatilẹyin rẹ lati gba alaafia laaye, ki wọn si tẹle ofin nitori ileẹjọ nikan lo le sọ ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo aarẹ to waye ni Naijiria ni Osu Keji, ọdun 2023.

Obi sọ ọrọ yii ni ilu Kaduna pẹlu igbakeji rẹ, Sẹnetọ Datti Baba-Ahmed.

O ni awọn araalu gbọdọ gba alaafia, iṣọkan laaye ki eto aabo le gbooro ni Naijiria.

Bakan naa lo ni idagbasoke orilẹede Naijiria gbọdọ jẹ gbogbo awọn eniyan logun ju ohun ti wọn fẹ lọ.

‘’A gbọdọ tọ ipasẹ alaafia, ifimọṣọkan lori ọrọ ẹsin, ibasepọ to dan mọran laarin awọn ẹya lo ṣekoko lasiko yii.

Ẹ jẹ ki a ri orilẹede Naijiria ti yoo wa ni alaafia, ti ijọba yoo si si ṣe awọn ohun ti araalu n fẹ lai, ki aye le dara fun awọn araalu.

O ni bio tilẹ jẹpe ibeere wa lọkan awọn eniyan lori eto idibo to kọja naa, Obi ni awọn araalu gbọdọ gba alaafia laaye lati le jẹ ki ijọba ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

O ni iṣoro to n koju Niajiria lọwọ bii eto ẹkọ to mẹhẹ, ai si eto aabo to muna doko, to fi mọ iya ati iṣẹ ni ijọba gbọdọ boju to.

Bakan naa lo ni ijọba to wa lode gbọdọ pese iṣẹ fun awọn ọdọ to pọ yanturu ati eto aabo to dẹnukọlẹ ni iha ariwa orilẹede Naijiria.