Àlàyé rèé lórí bí ogójì Ọ̀ọ̀ni ṣe ṣekúpa olórí ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀

Aworan ọọni kan ni ibuba wwọn

Oríṣun àwòrán, afp/getty images

Ọkan lara agbẹ to n sin ọọni lo ti ri iku he lẹyin ti awọn ọọni to to ogoji níye pin si wẹwẹ lẹyin to subu sinu ibi tí wọn ko wọn si.

Luan Nam, ẹni ọdun mejilelaadọrin ni o n gbinyanju lati mu ọkan lara awọn ẹranko naa to n yẹ ẹyin lọwọ kuro ninu a amọ nigba ọkan lara awọn ọọni fi ẹnu fa igi to mu lọwọ wọ inu ahamọ.

"Awọn ọọni yooku sure sì, ti wọn si ṣekupa " Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa, Mey Sarvy sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP.

Iṣẹlẹ naa waye niluu Diem Reap lọjọ Ẹti.

Sarvy ni awọn sawari oku ọkùnrin pẹlu awọn ọọni, ti wọn si ti jẹ ọkan lara apa rẹ

Oloogbe naa lo jẹ Aarẹ fun awọn agbẹ to n sin Ọọni.

Wọn n sin awọn ẹranko fun ẹyin ati fún jíjẹ ni ilẹ Asia.

Irufẹ iṣẹlẹ naa waye lọdun 2019 ni agbegbe nigba ti ọọni kọlu ọmọ ọdun méjì kan, ti wọn si ṣekupa

Àwọn aláṣẹ rí òkú pẹjapẹja ọmọ ilẹ Australia lẹnu Ọọni.

Saaju ninu oṣu karun un, awọn alasẹ bin ẹya ara ọmọ orilẹede Australia to sọnu lasiko to tẹlẹ awọn ọrẹ rẹ lọ pa ẹja lẹnu Ọọni.

Wọn rí Kevin Darmody lẹnu Kennedy Bend, to jẹ ilumọka Ọọni ni agbegbe ariwa Queensland lọjọ Satide.

Lẹyin tí wọn wa fun ọjọ meji, awọn Ọlọpaa ri ẹya ara rẹ lẹyin ti wọn ṣekupa ọọni nla meji.

Darmody lo jẹ agba ọjẹ pẹjapẹja, to si tun jẹ ilumọka ni agbegbe Cape York.

Wọn yinbọn lu ọọni meji naa lati ọ kan tí wọn ti rí wọn.

Awọn alasẹ ni ẹnu ọkan lara wọn ní wọn ti rí ẹya ara eeyan sugbọn awọn onimọ nípa imọ ẹranko mejeeji ni.

Pẹjapẹja to wa pẹlu Darmody lasiko naa ni ariwo nìkan ni oun gbọ sugbọn nigba ti oun yoo de bẹ, bata nikan ni oun rí.

"Mo sare lọ sí bẹ sugbọn nko ri nkankan lẹyin bata rẹ tí mo ri lẹgbẹ odo " Ọrẹ John Peiti sọ fun Cape York Weekly.

Ọọni ṣekupa Pasitọ to lọ ṣe iribọmi

Ọọni tí ṣekupa Pasitọ kan to lọ ṣe ìrìbọmi fun awọn ọmọlẹyin rẹ lẹgbẹ odo kan ni apa ariwa lọdun 2018.

Ileeṣẹ Ọlọpaa ati awọn eeyan to n gbe ni agbegbe naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fún BBC Amharic.

O to ọgọrin eeyan to n ṣe ìrìbọmi lasiko Pasitọ Docho Eshete da gbere fun aye lowurọ ọjọ Aiku ni bi odo kan ni ilu Arba Minch ni Merkeb Tabya.

"O se ìrìbọmi fun ẹni akọkọ, ẹni keji. Lati ibi a ko mọ ni ọọni naa ti jáde to si bu Pasitọ so " Ketema Kairo to n gbe ni agbegbe naa so fun BBC

O ni awọn pẹjapẹja ati awọn Ọlọpaa gbinyanju lati dola ẹmi Pasitọ naa sugbọn wọn ko ri ṣe, Eiwnetu Kanko sọ

"Oku rẹ nìkan wọn ri, wọn ko ri ẹmi rẹ dola." Eiwnetu fikun.