Seyi Makinde buwọ́lu òfin tuntun tí yóò yí ètò oyèjíjẹ padà nílú Ibadan

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, seyi makinde/twitter

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti buwọlu atunṣe abala ikejidinlọgbọn ofin oye jijẹ ipinlẹ Ọyọ.

Ni ọjọ Ẹti ni gomina Makinde buwọlu ofin naa lẹyin ti awọn aṣofin ipinlẹ ọyọ buwọlu aba naa eyi ti wọn fi mu atunṣe tuntun ba iwe ofin naa.

Koko atunṣe abadofin yii da lori agbara fun gomina lati gbe ade fun agba oye yoowu to ba ri pe o tọ si, laifiti ẹnikẹni ṣe.

Bi a ko ba ni gbagbe, ọrọ gbigbe ade fun awọnb oloye da wahala silẹ ni ilu Ibadan lọdun diẹ sẹyin nigba ti gomina ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Oloogbe Abiọla Ajimọbi gbe ade fun awọn oloye kan ni ilu Ibadan.

Ọrọ Ade dide da wahala silẹ laarin awọn agba oye ilẹ Ibadan ati olubadan

Ni oṣu kẹjọ ọdun 2017 ni gomina ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi sun awọn agba oloye mọkanlelogun ni ilu Ibadan si ipo ọba, eleyi ti o mu wọn maa de ade gẹgẹ bi Olubadan to jẹ olori wọn.

Eyi da ọpọ awuyewuye silẹ nigba naa pẹlu bi Olubadan igba naa, Ọba Saliu Adetunji atawọn agba oye kan ninu eyi ti gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Rashidi Ladọja ti fariga ti wọn si gba ile ẹjọ lọ.

Gomina Tẹlẹ, Abiọla Ajimọbi atawọn oloye to gbe ga si ipo ade dide nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, other

Ninu oṣù kini ọdun 2018 ni ile ẹjọ giga ni ìpínlẹ Ọyo dájọ pe ìgbésẹ̀ gomina lòdi si òfin, bákan náà ni Gomina náà ti gbe ẹjọ lọ ile ẹjọ kòtẹmilọrun

Lara awọn to ba BBC News Yoruba sọrọ lori ọrọ naa, Ọmọwe Gbade Ojo to jẹ olori awọn oṣiṣẹ ijọba lasiko naa, ṣalaye pe kii ṣe pe Ajimọbi kan dede gbe igbesẹ ọhun nigba naa, awọn agbaagba kan ni ilẹ Ibadan lo ke sii lati wa atunto ati atunṣe ṣe si ilana oye jijẹ ni ilẹ Ibadan.

“Amọ o ba ni lọkan jẹ pe awọn eeyan naa ko fi oju han sita mọ lati gbe lẹyin Ajimọbi” mọ nigba ti ọr naa ba ibomiran yọ.

Awọn abala ti ayipada de ba ninu ofin oye jijẹ ni ipinlẹ Ọyọ

Gomina MAkinde n gbe ọpa aṣẹ fun olubadan, Ọba Lekan Balogun

Oríṣun àwòrán, seyi makinde/twitter

Ni ọjọ kẹfa oṣu karun un ọdun 2023 ni igbimọ ijọba ipinlẹ Ọyọ buwọlu igbesẹ gomina Makinde lati fi iwe ranṣẹ si ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ lati buwọlu atunṣe si ofin oye jijẹ ni ipinlẹ naa.

Agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Oyelọwọ Oyewọ lo kọkọ fi ọrọ naa to araalu leti.

O ni awọn Baalẹ kan atawọn olori ilu kaakiri ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti n sin gomina ni gbẹrẹ ipakọ lori ẹbẹ ati de ado nitori aile joko jiroro igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Ọyọ.

Awọn koko to jade pẹlu ofin tuntun yii niwọnyii:

Gomina ni yoo laṣẹ lati buwọlu igbesoke awọn oloye tabi mọgaji ladi de ade.

Pẹlu atunṣe abala ikejidinlọgbọn ofin oye jijẹ yii, gomina ko nilo aṣẹ tabi ifọwọsi ẹnikẹni lati gbe ade le oloye yoowu tabi Mọgaji lori.