Ọkọ̀ òfúrufú ìjọba àpapọ̀ Nigeria Air tí padà balẹ́ sílùú Abuja lónìí

Ọkọ ofurufu ijọba apapọ Naijiria Nigeria Air ti ijọba ṣeleri pe yoo de si Naijiria lọjọ Ẹti ti balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni ilu Abuja.
Orileede Ethiopia lo ti gbera lati ti oju si ti wa lọna lati mọ boya ileri yi yoo di mimuṣẹ ki ijọba aarẹ Buhari to kogba sile.
O jẹ nkan ti ọpọ ọmọ Naijiria ti n jaran rẹ lati igbat ti ileeṣẹ ofurufu tẹlẹ Nigerian Airways ti dẹnukọlẹ.
Baalu ẹyọọ kan la ṣi gburo pe o balẹ ti ireti si wa pe awọn meji to ku ti yoo fipe mẹta naa ko ni pe de.
Amọ bi awọn baalu naa ba tilẹ de ko si aridaju pe wọn yoo bẹrẹ iṣẹ ayafi ti ọrọ ẹjọ tawọn ẹgbẹ awọn eleto ọkọ ofurufu pe ijọba Naijiria.
Laipẹ yi ni ẹjọ naa gba ọna mi yọ nigba ti awọn agbẹjọro ijọba beere igbalaye ile ẹjọ lati sun ẹjọ naa lọ si ilu Abuja.
Adajọ gba ẹbẹ wọn wọle ṣugbọn ẹgbẹ awọn eleto ofurufu tako idajọ yi.
Ile ẹjọ pada wọgile itako wọn ti o si jọ pe nilu Abuja ni ẹjọ naa yoo ti maa tẹ siwaju nigba kigba ti wọn ba fẹ gbọ ọ.

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọkọ ofurufu ijọba apapọ, Nigeria Air, yoo balẹ siluu Abuja lonii.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọkọ ofurufu naa wa niluu Addis Ababa, lorilẹ-ede Ethiopia bayii, nibi ti yoo ti gbera wa si Naijiria.
Ṣaaju ni agbẹnusọ Buhari, Bashir Ahmad, ti kọkọ sọ pe ọkọ ofurufu ijọba apapọ naa yoo bẹrẹ iṣẹ titi ipari ọdun 2018 amọ o kuna.
Ẹwẹ, minisita fun irinna ọkọ ofurufu, Hadi Sirika, ni ọkọ ofurufu ọhun yoo bẹrẹ iṣẹ ki saa Aarẹ Muhammadu to pari.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Channels sọrọ, Sirika ni “Lori ọrọ Nigeria Air, ọkọ ofurufu naa yoo balẹ si Naijiria lọjọ Ẹti lara awọn igbesẹ lati bẹrẹ iṣẹ naa.”
“Ọjọ naa ni a o ṣi aṣọ loju eegun baalu ọhun toun ti ami Naijiria lara rẹ, a o da awọn ọkọ ofurufu ijọba pada bọ sipo.”
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, fidio ọkọ ofurufu kan ti wọn kọ orukjọ ‘Naijiria Air’ si lara pẹlu ọda alawọ ewe ati funfun orilẹ-ede Naiiiria si lara ti n tan kalẹ lori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wayi o, ẹgbẹ awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria, Airline Operators of Nigeria (AON) ti pe ẹjọ tako ọkọ ofurufu ijọba Naijiria naa latari awọn to ni ipin ninu ileeṣẹ ọkọ ofurufu ijọba naa.
AON si ti kọ iwe si Aarẹ Buhari, ninu eyii ti wọn ti sọ pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu ijọba ọhun ko ba ofin mu.
Agbẹnusọ Buhari, Bashir Ahmad ti sọ pe ọkọ ofurufu Nigeria Air naa yoo jẹ ohun iwuri nla fun awọn ọmọ Naijiria ati gbogbo olugbe ilẹ adulawọ lapapọ.












