Wo àwọn gómìnà tí wọ́n tú ìgbìmọ̀ ìṣàkóso wọn ká l'oṣù yìí

Makinde, Ganduje, Obaseki

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn Gomina mẹrin ọtọọtọ ni a ti ṣe akiyesi wi pe wọn ti da awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ wọn silẹ saaju iburawọle fun ijọba tuntun ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun yii.

Gomina to gbe igbesẹ naa gbẹyin ni Ọnimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ.

Laipẹ yii ni Makinde kede ituka igbimọ iṣakoso ati wiwọgile iyansipo awọn to di ipo oṣelu mu.

Ikede yii wa ninu iwe ti ijọba kọ lọjọ kẹtalelogun oṣu karun un ọdun yii, eleyii ti olori awọn oṣiṣẹ fun Gomina ati alaga igbimọ to n mojuto iburawọle fun saa ikeji, Otunba Segun Ogunwuyi buwọlu.

Iwe naa ti wọn kọ pẹlu aṣẹ Gomina ipinlẹ Ọyọ ke si gbogbo awọn ti Gomina yan si ipo wi pe iṣẹ wọn ti pari. Bakan naa ni iwe naa paa laṣẹ fun wọn lati ko gbogbo ẹru ijọba to n bẹ ni akata wọn silẹ fun ẹni to jẹ olori ni ẹka ti wọn ti n ṣiṣẹ bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun oṣu karun ọdun yii.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Iwe naa tun tọka rẹ wi pe igbesẹ naa ko ni ṣe ipalara fun awọn eeyan kan ti wọn da ya sọto ninu awọn to di ipo oṣelu mu.

Igba ikeji niyii ti Gomina Ṣeyi Makinde yoo da awọn alabṣiṣẹpọ rẹ silẹ. Igba akọkọ waye ninu ọdun 2021 ti o jẹ ọdun meji akọkọ ninu saa akọkọ ti Makinde ṣe. Awọn Kọmisana kọọkan ati awọn eeyan mii ti ijọba yan sipo lo fi ara gba ninu igbesẹ naa.

Abdullahi Ganduje

Abdullahi Ganduje

Oríṣun àwòrán, Dr. Abdullahi Umar Ganduje OFR

Saaju igbesẹ ti Makinde gbe ni Gomina ipinlẹ Kano naa, Abdullahi Ganduje ti ke si igbimọ iṣakoso rẹ, paapaa julọ awọn ti saa iṣẹ wọn ko tii pari wi pe eyii ti wọn ṣe to gẹ saaju iburawọle fun ijọba tuntun ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun yii.

Akọwe fun ọfisi Gomina ipinlẹ Kano, Bilkisu Maimota ṣe alaye wi pe, "O pọn dandan fun gbogbo ẹni ti ijọba yan sipo lati da gbogbo ohun to n bẹ ni ikawọ wọn pada ni ibamu pẹlu ilana antẹẹle ijọba.

Nitori idi eyii, mo ti gba aṣẹ lati ke si gbogbo awọn to di ipo oṣelu mu bii Kọmisana, alamọran pataki, oluranlọwọ pataki, ati igbimọ alakoso iṣẹ ijọba ipinlẹ Kano pe ki wọn fi gbogbo dukiya ijọba to n bẹ lọwọ wọn ṣọwọ awọn alakoso agba ni ẹka ti wọn ti n ṣiṣẹ, o pẹ ju titi di ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023."

Maimota ni aṣẹ yii yọ awọn ti saa wọn ko tii pari silẹ ni ibamu pẹlu awọn ofin ati ilana ẹka ti wọn ti n ṣiṣẹ.

Abdulrahman Abdulrazaq

Abdulrahman Abdulrazaq

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman Abdulrazaq

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq naa pẹlu awọn Gomina ti o da igbimọ iṣakoso wọn silẹ.

Ninu ipade idagbere kan ti o waye saaju iburawọle fun saa ikeji Gomina naa ti wọn o ṣe lọjọ kọkandinlọgbọn, Gomina naa dupẹ lọwọ igbimọ iṣakoso rẹ fun ipa ribiribi ti wọn ko lojuna aṣeyọri rẹ fun saa akọkọ.

Abdulrazaq dupẹ lọwọ wọn fun ipa ti wọn ko lati mu ki oun ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) wọle ninu eto idibo ti o kọja.

Ninu ọrọ tiẹ nibi ipejọpọ naa, Kọmisana fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Aliyu Kora Sabi ti o sọrọ lorukọ awọn akẹgbẹ rẹ dupẹ lọwọ Gomina fun anfani lati darapọ mọ igbimọ iṣakoso rẹ.

O ni ohun iwuri lo jẹ wi pe awọn naa le kopa ninu aṣeyọri ijọba rẹ.

Godwin Obaseki

Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, Godwin Obaseki

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki wa lara awọn Gomina ti o kọkọ gbe igbesẹ lati da awọn igbimọ iṣakoso silẹ lai tii pe ọdun meji ti wọn de ori ipo.

Ninu atẹjade ti Gomina ipinlẹ naa gbe jade lati ọwọ alamọran pataki lori akanṣẹ iṣẹ igbohunsafẹfẹ, Crusoe Osagie, Gomina naa gba iṣẹ lọwọ gbogbo oluranlọwọ pataki ati awọn oluranlọwọ pataki agba.

Obaseki dupẹ lọwọ awọn aṣoju igbimọ iṣakoso naa fun iṣẹ ti wọn ṣe fun ijọba ati awọn eeyan ipinlẹ Edo.