Àwọn ará ilẹ̀ Sudan sọ ìrírí wọn ĺ́ẹyìn gbèndéke láti dáwọ́ ogun dúró ní Sudan

Aworan

Lẹyin ti gbedeke ọjọ meje bẹrẹ lati dawọ ogun duro ni Sudan, awọn ara ilu ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han.

Awọn araalu ni fun igba akọkọ laarin ọsẹ marun un ti ogun ti bẹ silẹ ni Sudan, awọn eniyan ni alaafia jọba ni ilu Khartoun to jẹ olu ilu orilẹede naa.

Ọjọ meje ni gbedeke yii yoo fi wa, ti ko fi ni si ija laarin awọn ikọ mejeeji ti wọn n koju ara wọn lorilẹede naa.

Amọ awọn agbegbe bii Omdurman ati agbegbe River Nile ni Bahri ti ni awọn gbọ ti ado oloro dun gbamu ni agbegbe naa.

April 15 ni ija naa ba silẹ laarin ikọ ọmọogun Ilẹ Sudan ati ẹsọ alaabo RSF

Awọn ikọ Ologun orilẹede naa ni wọn lo ọkọ ofurufu lati sekọlu ni igba to ku perete ki gbedeke naa bẹrẹ lorilẹde ọhun.

Amọ ikọlu naa ti wọn n se si ikọ ẹsọ alaabo Rapid Support Forces(RSF) ti dawọ duro.

Bakan naa ni awọn eniyan ni awọn si n gbọ bi irọ ibọn se n dun ni agbegbe Khartoum.

Ikọ RSF ni wọn kede pe o ni akoso ọpọ agbegbe naa ni Khartoum ati awọn ilu nla meji miran.

Amọ ko si wahala ni agbegbe El Geneina ati Nyala ni agbegbe Darfur ti wọn ti sekọlu si tẹlẹ.

Ọjọ Karundinlogun, Osu Kẹrin, ọdun 2023 ni ija naa ba silẹ laarin awọn adari ikọ ọmọogun Ilẹ Sudan ati adari ẹsọ alaabo RSF.

Orilẹede Amẹrika ati Saudi Arabia ni wọn ti bẹrẹ si ni sọrọ lati pari ija to bẹ silẹ naa nitori ipalara to jasi fun awọn araalu.

O le ni miliọnu kan eniyan ti ko ni ile lori mọ, ti ọpọ eniyan si ti ku lasiko ti ija naa ti bẹrẹ

Bakan naa ni eto ilera nibẹ ti mẹhẹ, ti awọn eniyan si tik u nitori ija to bẹ silẹ naa.