Iwoye Ketu taboo: Òrìṣà kò faramọ́ ká gbìn àlùbósà tàbí ká ló aburada

Àkọlé fídíò, Ka nipa awọn eewọ Iwoye Ketu eyi to rọ mọ alubọsa,aburanda ati ẹlẹ́dẹ̀

Ìdálùú kúkú ni ìṣèlú....

Owe Yoruba kan ni 'Bi a se n se ni ile wa, eewọ ibo miiran ni'.

Gbogbo ilẹ Yoruba lo ni eewọ kan tabi meji ti wọn ni igbagbọ pe o le sokunfa ifasẹyin si ilẹ wọn.

Bi wọn ko se ki n jẹ aja ni awọn agbegbe kan, ni wọn ko si ki n jẹ ejo ni awọn agbegbe miiran sugbọn ni ilu Iwoye Ketu, wa ni ijọba ibilẹ Imeko Afon ni ipinle Ogun.

Won wa ni aarin Naijiria ati Orile Ede Republic of Benin ni Iwo Oorun Guusu ni ilẹ Naijiria ni le Adulawo eewọ ti wọn yani lẹnu pupọ.

Oba ilu Iwoye Ketu

Oríṣun àwòrán, Olubusola Afolayan

Àkọlé àwòrán, Oba Sunday ti Iwoye Ketu

Ibo ni Ilu Iwoye Ketu?

Iwoye Ketu je ilu kan to wa ni ala laarin orilẹede Naijiria ati otilẹede Benin. Ilu yii wa labẹ ijọba ibilẹ Imẹkọ Afọn nipinlẹ Ogun.

Olumu ti ilu Imoye Ketu, Oloye Emmanuel Sunday Babatunde ba BBC News Yoruba sọrọ, o ni pe ilu Ile Ife ni awọn baba nla wọn ti sẹwa lati wa di ilu Imoye Ketu silẹ

Olokada ara ilu Iwoye Ketu

Kini awọn eewọ Imoye Ketu?

Olumu ti ilu Imoye Ketu ni Imoye ni eewọ to pọ, to si se koko ki awọn ọmọ ilu yago fun eewo naa.

Lara awọn eewọ ti Olumu sọ ni pe wọn ko ni anfani lati sin Ẹlẹdẹ ni ilu Imoye.

Bakan naa, eewọ ni pe ki awọn araalu lo aburada lati bo ori wọn lasiko ti ojo ba n rọ tabi ti oorun ba ran.

Ikẹta ni Olumu darakọ pe o jẹ eewọ ni pe wọn ko gbọdọ gbin Alubọsa niluu Imoye.

Oloye Emmanuel Sunday to n dari Iwoye Ketu jẹ Olumu, Won ni Orisa Oluwa eyi ti Imoye gbagbọ pe o jẹ alaabo fun Baba nla wọn ko rira ohun idọti, ti pupọ si ri Ẹlẹdẹ gẹgẹ bi ohun idọti.

Olumu salaye, ilẹ kun, ẹ wọ fidio yii lati mọ si nipa Ilu Imoye Ketu ati awọn eewọ wọn.