Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí gbèsè tí àwọn Alfa sọ pé Adunni Ade jẹ Murphy Afolabi

Adunni Ade ati aworan awọn alfa

Oríṣun àwòrán, Other

Eero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọtọ lori bi Alfa kan ṣe pariwo gbajumọ oṣerebinrin, Adunni Ade, ni gbangba pe o jẹ oloogbe Murphy Afolabi ni gbese.

Nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti awọn akẹẹgbẹ oloogbe Afolabi sẹ fun nipinlẹ Eko, ni awọn Alfa to sẹ waasi nibẹ ti kede pe awọn eeyan kan jẹ oloogbe lowo.

Ninu waasi naa ni ọkan lara awọn Alfa naa ti n ke tantan pẹlu ẹrọ gbohungbohun pe o ṣe pataki, ki awọn to jẹ oloogbe Afolabi lowo san owo naa.

Bakan naa lo sọ pe ki awọn ti oloogbe naa jẹ ni gbese ohunkohun naa yọju si igbimọ to n ṣe amojuto ẹbi oloogbe.

Fidio waasi naa jade sori ayelujara, eyi to fa awuyewuye, ti awọn eeyan si n bu ẹnu atẹ lu Alfa naa, nitori bo ṣe jẹ pe orukọ Adunni Ade nikan lo pariwo ninu fidio naa gẹgẹ bi ẹni to jẹ oloogbe ni gbese N250,000.

Lara oun ti awọn eeyan n sọ ni wi pe o ku diẹ kaato bi Alfa naa ṣe ya Arabinrin Adunni sọtọ, ti ko si darukọ awọn onigbese’ to ku.

Ṣugbọn awọn eeyan kan tun gbagbọ pe ko si nnkan to buru ninu bi awọn alfa ṣe kede orukọ rẹ.

Ẹ wo diẹ lara nnkan ti awọn eeyan n sọ nipa iroyin naa loju opo Facebook BBC Yoruba:

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Diẹ lara nnkan ti awọn eeyan sọ lori Twitter ati Instagram

Ero araalu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ero araalu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

'Mi ò jẹ Murphy Afolabi lówó kó tóò kù, bí N150,000 ṣe dàwápọ̀ rèé'

Adunni Ade ati Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, Adunni Ade/Murphy Afolabi/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oṣerebinrin, Adunni Adewale, ti ọpọ mọ si Adunni Ade ti fesi si iroyin kan to n lọ lori ayelujara pe o jẹ Murphy Afolabi, to di oloogbe laipẹ yii.

Murphy Afolabi ti oun naa jẹ gbajumọ oṣere, dagbere faye ni ọsẹ kan sẹyin lẹni ọdun mọkandinlaadọta.

Ṣugbọn ni ọjọ Aiku to kọja, nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti awọn akẹẹgbẹ rẹ sẹ fun nipinlẹ Eko, ni awọn Alfa to sẹ waasi nibẹ ti kede pe awọn eeyan kan jẹ oloogbe lowo.

Ninu waasi naa ni ọkan lara awọn Alfa naa ti n ke tantan pẹlu ẹrọ gbohungbohun pe o ṣe pataki, ki awọn to jẹ oloogbe Afolabi lowo san owo naa.

Bakan naa lo sọ pe ki awọn ti oloogbe naa jẹ ni gbese ohunkohun naa yọju si igbimọ to n ṣe amojuto ẹbi oloogbe.

O ni eyi jẹ ọkan lara awọn ilana ẹsin Islam.

Fidio waasi naa jade sori ayelujara, eyi to fa awuyewuye, ti awọn eeyan si n bu ẹnu atẹ lu Alfa naa, nitori bo ṣe jẹ pe orukọ Adunni Ade nikan lo pariwo ninu fidio naa gẹgẹ bi ẹni to jẹ oloogbe ni gbese N250,000.

Ọpọ eeyan gbagbọ pe ko bojumu bi wọn ṣe darukọ oṣerebinrin naa nikan, ati pe ko ba ẹ̀sìn Islam mu.

Adunni Ade fi atẹjade sita lori ọ̀rọ̀ naa

Ninu ikede to fi sita lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Adunni Ade ṣalaye pe oun ko jẹ oloogbe Murphy Afolabi ni owo kankan.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ aṣoju rẹ fi sita, lo ti ṣalaye pe oun ko yan Murphy Afolabi jẹ nigba to wa laye, ti oun ko si le yan-an jẹ ni bayii to ti ku.

“Ipo ọ̀wọ̀ ati apọnle ni mo fi oloogbe si nigba aye rẹ.”

Atẹjade ti Adunni Ade fi sita

Oríṣun àwòrán, Adunni Ade/Instagram

O ni, ninu oṣu Keje, ọdun 2021 ni Murphy Afolabi kàn si oun lati ba ṣiṣẹ ninu ere kan to fẹ ṣe.

“O ba mi sọrọ nipa ere naa to fẹ ki n ti kopa. O si ṣalaye fun mi pe oun ko ni le san owo iṣẹ mi, nitori pe lati apo ara oun ni oun ti fẹ ya fiimu naa.

“O ni ṣugbọn oun yoo ra epo si ọkọ̀ ayọkẹlẹ mi, gẹgẹ bi owo irinsẹ. Mo si gba bẹẹ.”

Arabinrin Adunni sọ pe oloogbe Afolabi san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) sinu apo asunwọn oun.

Arabinrin naa sọ pe amọ oun ko le kopa ninu fiimu naa, nitori pe aburo oun kan kú lasiko naa, eyi to mu ko di dandan fun oun lati rinrinajo lọ si ilẹ America fun isinku rẹ.

“Mo ba Murphy sọrọ pe ko jẹ ki n da owo naa pada fun-un, ṣugbọn o ni ki n ma daa pada nitori ma a fi ba oun ṣe fiimu mi.

“Amọ nigba ti o fẹ ya fiimu naa, ọ̀rọ̀ wa ko wọ̀ nitori pe N150,000 naa lo fẹ́ san fun iṣẹ ọjọ mẹrin.

“Mo gba nọ̀mba aka-n-ti rẹ, mo si da owo to ti kọkọ san fun mi ninu oṣu Keje pada sibẹ.”

Arabinrin Adunni Ade ko fi ọ̀rọ̀ rẹ mọ sibẹ, gbogbo awọn iwe to fihan pe o gba owo lọwọ Murphy Afolabi, ati eyi to fihan pe o da owo pada fun, lo fi si ori ayelujara.

Lati igba naa si ni ọpọ eeyan ti n kesi pe o yẹ ko gbe Alfa to fi ẹsun èké kan-an lọ sile ẹjọ fun ẹsun ibani lorukọ jẹ́.