Àwọn ǹnkan tó ṣe pàtàkì kí o mọ̀ nípa Dangote Refinery

Dangote refinery

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY

Oni, ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni wọn o ṣe ifilọlẹ ẹbu ti wọn ti n fọ eporọbi(refinery), ti ileeṣẹ Dangote nipinlẹ Eko.

Ẹbu naa to jẹ ti gbajugbaja olokoowo, Aliko Dangote, ni wọn kọ si agbegbe Ibeju-Lekki, ni iroyin ní o tobi julọ nilẹ Africa.

Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn olori orilẹ-ede mii ati èè[kàn ilu ni yoo peju sibi ayẹyẹ naa.

Ireti wa pe àgbá eporọbi to to 650,000 ni wọn o ma a fọ̀ nibẹ lojumọ fun awọn onibaara lati Africa, Asia ati America.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe ẹbu naa yoo pese iṣẹ fun eeyan bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un.

Ẹbu ifọpo naa ni akọkọ iru rẹ to jẹ ẹbu nla lati ọwọ eeyan kan ṣoṣo.

Àwọn ǹnkan tó ṣe pàtàkì kí o mọ̀ nípa Dangote Refinery

Dangote refinery

Oríṣun àwòrán, Other

  • Agbegbe Ibeju-Lekki ni ẹbu ifọpo naa wa, o si gba to 2,635 eeka ilẹ ti wọn kọ ọ si
  • Gẹgẹ bi nnkan ti awọn alaṣẹ ilee\ọ̀ẹ Dangote ṣe sọ, ẹbu ifọpo naa ni iru rẹ, to tobi julọ ni agbaye ti yoo ma a pese odinwọn eporọbi to pọ
  • To ba n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ, ireti wa pe ibẹ ni wọn o ti ma a fọ gbogbo eporọbi ti Naijiria nilo, ti yoo si tun ni ọpọ yanturu lati tà si ilẹ okeere
  • Àgbá eporọbi 177 lo wa ni Dangote refinery, eyi to le gba 4.742 billiọnu lita epo
  • Ẹbu ifọpo Dangote ni ibudokọ ori omi tirẹ, lati maa ko awọn ohun elo wọle sibẹ taara, ati kiko eporọbi ti wọn ba fọ̀ jade lọ silẹ okeere

Ẹ fojusọna loju opo yii fun ẹkunrẹrẹ bi ifilọlẹ naa yoo ṣe lọ.