Buhari gbọdọ̀ ṣàlàyé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ná $460m tó yá lọ́wọ́ China láti fi pèsè CCTV sílùú Abuja - Ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari ko ṣalaye bo ṣe na $460 miliọnu ti ijọba rẹ ya lọwọ orilẹ-ede China.
Owo naa ni ijọba sọ pe oun yoo fi so ẹrọ ayaworan CCTV kaakiri ilu Abuja fun awọn araalu amọ iṣẹ naa fori ṣọpan.
Adajọ Emeka Nwite lo paṣẹ ọhun lasiko to n da ẹjọ kan ti ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP, pe ijọba.
Nwite paṣẹ fun ijọba apapọ lati kede gbogbo iye owo to san fun awọn ileeṣẹ to jẹ ti ilẹ China ati awọn ileeṣẹ abẹle to gbe akanṣe iṣẹ naa fun.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Oṣu kejila, ọdun 2019 ni SERAP pe ẹjọ ọhun tako minisita fun eto iṣuna, Zinab Ahmed, lori ẹsun pe o kọ lati kede iye owo pato ti ijọba san fun awọn agbaṣẹṣe lara $460 miliọnu ti ijọba Buhari ya lọwọ China lọdun 2010 lati fi so CCTV ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣaaju ni Ahmed ti kọkọ sọ pe ijọba ti n san gbese naa pada amọ ko ṣalaye ibi ti wọn ba iṣẹ ọhun de.
Ninu idajọ rẹ, Nwite ni SERAP lẹtọọ lati bere bi ijọba ṣe na owo naa, o si lẹtọọ lati pe ijọba lẹjọ.
O ni “O yẹ ki awọn araalu mọ bi ijọba ṣe na $460m owo ti ijọba ya lọwọ China, yoo si jẹ ohun itiju ti ile ẹjọ yii ba kọ lati yẹ ọrọ naa wo.”
“Minisita eto iṣuna lo wa ni ikawọ owo Naijiria, ko si le sọ pe oun ko mọ iye owo ti wọn san fun awọn agbaṣẹṣe lati fi so CCTV si awọn ibi to ṣe pataki niluu Abuja....”
Adajọ Nwite wa paṣẹ ki ijọba apapọ, lati ọwọ minisita eto iṣuna ṣe afihan gbogbo iye owo to san fun awọn agbaṣeṣe.
O tun sọ pe ki ijọba darukọ gbogbo awọn agbaṣeṣe to gbe iṣe naa fun ki gbogbo araalu le mọ bi o ṣe na owo ọhun.












