Ìjínigbé,ọ̀wọ́ngógó,gbèsè l'ógun tí Buhari fí sílẹ́ fún Nàíjíríà

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty

    • Author, Nduka Orjinmo
    • Role, Senior Journalist

Nigba ti aarẹ Muhammadu Buhari yoo ba fi gbe ijọba kalẹ lọsẹ to n bọ,awọn araalu yoo wa ni ipo ailaabo to peye,pupọ ni iṣẹ ati oṣi yoo tunbọ yi wọn ka ti gbese orileede naa yoo si pọ ju tatẹyinwa lọ.

Ọgagun nigba kan ri yi jaweolubori lẹyin to gba ipo aarẹ lọwọ Goodluck Jonathan tawọn araalu ni ko ṣiṣẹ to lọdun 2015.

Pupọ lo ṣatilẹyin Buhari ti ireti si wa pe yoo mu iyipada ba ọrọ aje,eto aabo nitori ipo rẹ gẹgẹ bi ọgagun ti ko gba iregbe.

Amọ nigba ti yoo fi ṣe saa ikeji, ọpọ ni inu wọn ko dun si bo ṣe dari ilu toun ti igbagbọ taraalu ni ninu iṣakoso rẹ.

Lootọ ni awọn ologun ribi ṣaṣeyọri diẹ nipa kikoju Boko Haram ati awọn alakatakiti agbesunmọmi mii pẹlu iranwọ nkan ijagun ti Naijiria rigba lọdọ Amẹrika.

Ni afiwe pẹlu tatẹyinwa, awọn agbesunmọmi yi ko ribi gbalẹ bi wọn ṣe gba ilẹ labẹ ijọba to kọja.

Bakan naa la le gboriyin fun Buhari pe o lo ẹyawo lọdọ China lati fi ṣeto reluwe ati ibudoko ọkọ oju omi ni Eko.

Bẹẹ naa lo pari afara 2nd Niger Bridge to is tun buwọlu ofin to de eto idibo Naijiria ati awọn ofin pataki mii lẹka epo rọbi.

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nigba ti Buhari yoo fi wọle, o sọ pe gbogbo iṣoro wa la le da yanju fun ara wa

Aabo ati ẹlẹyamẹya

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tohun tawọn igbiyanju nipa kikoju awọn alakatakiti ni ariwa Naijiria, isọwọ bawọn ikọ agbebọn mi ṣe di egun ẹja mọ ijọba lọrun lawọn agbegbe miran ko jẹ ki araalu mọ iyatọ.

Se ti ikọlu laarin awọn agbẹ ati darandaran la fẹ sọ ni tabi tawọn janduku agbebọn ajingbepawo kaakiri Naijiria lonii.

Aarẹ Buhari to jẹ ẹya Fulani lọpọ fẹsun kan pe o gbe lẹyin awọn ẹya rẹ nipa aba to mu wa pe ki wọn da aaye ijẹko ''Ruga'' silẹ ki awọn gomina ipinlẹ Guusu to tako wipe o fẹ fi ipa gba ilẹ awọn ni.

Ni tawọn ajinigbe taa mẹnu ba, o ti wa di ranto lonii debi pe bi wọn ṣe n ji awọn akẹkọọ gbe bẹẹ naa lawọn oṣiṣẹ ati araalu mii ko moribọ lọwọ wọn.

Se ẹ o gbagbe pe ijinigbe awọn ọmọ akẹkọọ Chibok wa lara nkan ti Buhari fi ṣe ipolongo tawọn araalu fi dibo yọ aarẹ Jionathan kuro lori oye?

Nilẹ oni to mọ yi, araalu ko fẹẹ ri iyatọ laarin ipo aabo Naijiria lonii si ti igba ti Jonathan wa lori oye.

Ọgbẹni Musa Ahmadu,agbẹ kan lati ipinlẹ Katsina to ba BBC sọrọ sọ pe ''Mo ro pe Buhari, ọgagun tẹlẹ ri yoo rẹyin awọn janduku ajinigbe ti yoo si mu opin ba ipenija aabo Naijiria''

Amọ ọrọ ko ri bẹẹ nitori Ahmadu to jẹ ọmọ ilu aarẹ ti sa nile lọ si Kano nitori awọn janduku ajinigbe ti ṣi ọpọ kuro laaye wọn lọ nilu aarẹ.

Gomina Akeredolu ati awọn mii n yẹ aaye ti ikọlu ti waye ni Owo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ipenija IPOB naa ko gbẹyin

Aworan Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ lo ro pe o ku diẹ kaato bi Buhari ko ṣe yanju ọrọ olori ikọ to n pe fun idasilẹ orileede Biafra,IPOB, iyẹn Nnamdi Kanu.

Airi ọrọ naa yanju ti mu ki awọn ikọlu orisirisi maa waye ti ọpọ ẹmi si ti baa lọ.

Ọpọ ni ko kọkọ ka ọrọ Ipob yi kun ṣugbọn nigba ti ọrọ yoo fi de ibi to de lonii,awọn araalu n ṣe eemọ bi ọgagun tẹlẹri yi ko ṣe ribi yanju ọrọ naa.

Ọgagun Hassan Stan Labi to jẹ onimọ nipaa abo ilu sọ pe ''idojuti gbaa ni Buhari mu ba ẹka ologun toun ti gbogbo ileri to ṣe''

''Bawo leeyan ṣe le gba odo nidi iṣẹ ti o jẹ akọṣẹmọṣẹ?''

Ọrọ naa jẹ eleyi ti ọpọ yoo foju wo wipe Buhari kuna nidi rẹ.

Ole jija epo rọbi

Awọn oluwọde ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo ikọlu ati iwa janduku taa mọ agbegbe Niger Delta si dabi ẹni pe o dẹnu kọlẹ diẹ lasiko aarẹ Buhari.

Ṣugbọn idakẹjẹ yi nkan mii ni wọn fi rọpo rẹ tii ṣe ole jija epo rọbi lọbitibiti.

Iwa yi jẹ ipese epo rọbi Naijiria kere si ju tatẹyinwa lọ.

Bi a ko ba gbegbe iroyin aṣiri ole jija yi kan to gbode loṣu Kẹwa ọdun to lọ mu ki awọn onwoye se eemọ pe ko si bi iru ole jjija yi ṣe le waye ti awọn alaṣẹ ko ni mọ si.

Awọn to n jale epo rọbi yi laya debi pe wọn gbe ọpa epo gba aaye tawọn agbofinro maa n sọ ti wọn a si maa gbe epo ti wọn jigbe yi sori ọkọ oju omi lọsan gangan.

Ohun to ba ọrọ jẹ julọ ni pe aarẹ Buhari gaan alara ni Minisista fọrọ epo rọbi ni Naijiria.

Eleyi tunmọ si pe ko ja fafa nidi iṣẹ to yan ara rẹ si ti orileede Naijiria si padanu aimọye

Ọrọ Aje

Aworan awọn to to siwaju ile ifowopamọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bi eeyan ba beere lọwọ ọmọ Naijiria mẹwaa nipa ohun ti wọn yoo ranti nipa ijọba aarẹ Buhari, o daju pe pupọ yoo mẹnu ba eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Eleyi ti yoo ṣi wa lọkan wọn fọjọ pipẹ gẹgẹ bi iṣẹlẹ manigbagbe nio ọrọ owo Naira ti ijọba lawọn ṣe iyipada rẹ.

Ọkẹ aimọye oniṣowo ati aladani lo kerora lasiko eto yi to si mu inira ba ogunlọgọ ọmọ Naijiria to gbẹmi le ipese owo fun lilo ojojumọ.

Akẹkọọ kan ni fasiti Abuja to ba BBC sọrọ fesi bayi pe''Arakunrin yẹn ba awọn iṣe owo kekeeke ta n ṣe jẹ.''

Awọn akẹkọọ nikan kọ, ati oniṣwo obi, arugbo, ọmọde ati agbalagba gbogbo eeyan lo mọ riri inira iyipada owo yi

Lakotan, ọpọ ni ko niṣẹ lọwọ lasiko ijọba Buhari ti owo ọja si gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ.

Owo ti ijọba tun jẹ kalẹ ni gbese naa jẹ nkan tawọn ọmọ Naijiria ri gba gẹgẹ bi ogun manigbagbe lọdọ ijọba Buhari.

Laipẹ yi, bi ijọba rẹ ṣe n kasẹ nilẹ aarẹ Buhari bẹ awọn aṣofin pe ki wọn tara buwọlu ẹyawo $800m kan lati ọdọ Banki agbaye. Bayi taa n sọrọ yi, gbese ti Naijiria jẹ ti kọja $150bn.

Nigba ti aarẹ Buhari de ori oye, diẹ ni gbese Naijiria fi kọja $60bn.