‘Ẹ ṣe ìwádìí adarí àjọ EFCC, Abdulrasheed Bawa fún ẹ̀sùn jẹgúdújẹrá’

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Zamfara, Mohammed Bello Matawalle ti fi ẹsun kan adari ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, Abdulrasheed Bawa fun lilu owo ilu ni ponpo.
Eyi n waye lẹyin ti adari ajọ EFCC kede pe wọn fẹ sewadii awọn gomina kọọkan ni Naijiria fun ẹsun lilu owo ilu ni ponpo, ti wọn si ni gomina Zamfara wa ninu wọn.
Ẹsun ti wọn fi kan gomina naa ni pe o lu owo ilu to le ni aadoje biliọnu naira ni ponpo.
Amọ nigba ti Gomina Matawalle n ba BBC sọrọ, o ni ki Bawa fi ipo rẹ silẹ ki wọn wa sewadii rẹ.
O ni o da oun loju pe orisirisi ẹsun ni wọn yoo ri pe o jẹbi rẹ, paapaa lilu owo ilu ni ponpo.
‘’Mi o ni ki wọn ma sewadii, iwadii dara, amọ gbogbo w ani wọn gbọdọ se iwadii naa fun.’’
‘’Awa gomina nikan kọ lani apo isuna, ki wọn sewadii gbogbo awọn alẹnulọrọ ni awujọ’’
‘’Afẹ ki alaga ajọ EFCC naa fi han agbaye iwe ẹsun ti o fi kan awọn gomina, bakan naa ni ko si fi akọsilẹ to wa ninu iwe nipa awọn ti o n ba a ṣiṣẹ naa lede pẹlu, ki gbogbo aye rii.’’
Ti Bawa ba fi ipo silẹ ki wọn sewadii rẹ, ọpọlọpọ ẹlẹri ni yoo jade, ti aṣiri rẹ yoo si han si gbangba.’’
Gomina Matawalle ni idi ti Bawa fi n gbogun ti awọn gomina ni wipe nitori o mọ wi pe awọn ni ẹri iwa jẹgudujẹra to n hu.
Bakan naa ni ajọ EFCC ti ni ki gomina naa fi ẹjọ alaga ajọ naa sun ileeṣẹ ọlọpaa, pẹlu ẹsun ti o fi kan an to ba da loju.
Ninu esi rẹ, alaga Ajọ EFCC sọ fun BBC pe ko si ẹda to mọ lai si kudiẹ-kudiẹ kankan, amọ awọn ẹsun lasan ti ko ni ẹsẹ nilẹ ni gomina naa fi kan oun.
EFCC ń ṣèwádìí gómìnà Zamfara, Bello Matawalle fún màkàrúrà ₦70bn

Oríṣun àwòrán, Collage
Àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC ní àwọn ti ń taná wádìí gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara, Bello Matawalle fẹ́sùn wí pé ó kó bílíọ̀nù àádọ́rin náírà tó jẹ́ owó ìlú gboko ibòmíràn lọ.
Bákan náà ni àjọ ọ̀hún tún Mínísítà fọ́rọ̀ ohun àmúṣagbára tẹ́lẹ̀ rí, Sale Mamman ṣì wà ní àhámọ́ àwọn fẹ́sùn ṣíṣe màkàrúrù bílíọ̀nù méjìlélógún náírà nígbà tó wà ní ọ́fíìsì.
Alága EFCC, Abdulrasheed Bawa ló fi ọ̀rọ̀ náà léde níbi ìpádè èyí tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́bọ̀, tó sì rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti kọ etí ọ̀gbọ̀in sí àwọn tí Matawalle sọ.
Ṣaájú ni gómìnà Matawalle ti fi àwọn ẹ̀sùn kan kan Bawa, tó sì ní kó taná wádìí àwọn mínísítà àtàwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba àpapọ̀ dípò wíwádìí àwọn gómìnà nìkan.
Bawa nígbà tó ń gba ẹnu adarí ẹ̀ka tọ ń rí sí ọ̀rọ̀ ará ìlú, Osita Nwajah ní gómìnà Matawalle fọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí gbé owó náà jáde lórúkọ àwọn agbaṣẹ́ṣe tí kò ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wọn.
Wọ́n ní ìwádìí àwọn fi hàn pé iléeṣẹ́ tó tó ọgọ́rùn-ún ló gba owó nínú akoto náà láìsí ẹ̀rí iṣẹ́ kankan tí wọ́n fi àwọn owó náà ṣe fún ìpínlẹ̀ Zamfara.
Ó fi kun pé àwọn ti ránṣẹ́ sí àwọn kan lára àwọn agbaṣẹ́ṣe náà ti àwọn sì ti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn tí àwọn ti fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ọ̀hún ló ti ń ṣàlàyé bí gómìnà Matawalle ṣe pa á ní dandan fún àwọn láti dá àwọn owó náà padà fún òun gba ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣẹ sí dọ́là tán.
Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo nǹkan tí Matawalle sọ kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ bí EFCC ṣe ń ṣàmójútọ àwọn ohun ìní àwọn ènìyàn tí wọ́n bá gbà fẹ́sùn ìwà àjẹbánu.
Bawa ṣàlàyé pé gbogbo àwọn nǹkan tí àwọn ń gbà yìí ni àwọn máa ń kó sínú akoto ìjọba àpapọ̀ padà kó le jẹ́ ìwúlò fún àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀.















