Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí méjì tó lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ìkọlù sáwọn ọmọ Amẹ́ríkà ní Anambra

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti ni ọwọ ti tẹ afurasi meji to kopa ninu ikọlu si ajọ Amẹrika to waye ni ijọba ibilẹ Ogbaru.
Iwadii ti awọn ọlọpaa se saaji fihan pe eeyan meje lo padanu ẹmi wọọn. Lara awọn meje ọhun ni a ti ri eeyan mẹta ninu osisẹ ajọ ilẹ Amẹrika ati ọlọpaa mẹrin.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọbọ, Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra, Echeng Echeng ni ileeṣẹ ọlọpaa sisẹ pọ pẹlu awọn ọmọ ologun oju omi lati sawari awọn afurasi naa ninu igbo ti wọn sa wọ ni agbegbe Ugwuaneocha ni ijọba ibilẹ Ogbaru
Gẹgẹ bi Kọmisọna ṣe sọ, bi awọn ologun ṣe balẹ si agbegbe naa ni wọn tu gbogbo ayika naa ka, ti wọn si dana sun igbo ọhun.
Kọmisọna ni ọwọ ti tẹ eeyan meji, ifọrọwerọ ati iwadii si ti bẹrẹ ni ileeṣẹ Ọlọpaa.
Kò si ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kankan tó kú níbi ìkọlù tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Anambra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Amẹrika ti ni ko si ọmọ ilẹ wọn kankan to padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn agbebọn kan se ikọlu ọkọ ayọkẹlẹ, eyi to waye ni opopona Atani ni agbegbe Osamale nipinlẹ Anambra.
Agbẹnusọ ajọ to n ri si idabobo awọn ilẹ Amẹrika, John Kirby lo fi ọrọ naa sita.
“Mo rii pe mo ṣe iwadi, ti mo si ri aridaju ki n to bọ sita lati wa sọrọ fun yin.
“Nnkan ti mo le sọ fun yin ni pe ko si ọmọ Amẹrika kankan to wa nibi ikọlu naa, ti ko si ẹni ro farapa ṣugbọn a gbọ pe awọn ajalu kan waye, ti awọn ẹmi kan si ṣofo,” eyi ni ọrọ to sọ lori opo Ayelujare Youtube rẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Tobechukwu Ikenga naa fidi rẹ mulẹ pe ko si ọmọ iulẹ Amẹrika kankan ninu awọn mẹrin to padanu ẹmi wọn.
“Awọn afurasi agbebọn naa sekupa eeyan mẹrin, ti wọn dana sun oku wọn ati ọkọ ayọkẹlẹ wọn. Bakan naa ni wọn ji Ọlọpaa meji gbe , Dẹrẹba ọkọ ayọkẹlẹ, ti wọn si salọ kete ti gboru pe awọn Ọlọpaa wa layika wọn. Ko si ọmọ ilẹ Amẹrika kankan nibẹ.”
Agbébọn kọlú àwọn òṣìṣẹ́ America ní Nàìjíríà, èèyàn mẹ́rin kú, wọ́n tún dáná sun òkú wọn àti ọkọ̀
O kere tan eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn kan ni ipinlẹ Anambra.
Ninu awọn mẹrin yi la ti ri oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria.
Niṣe lawọn agbebọn yi ṣadede yọ si awọn ọkọ ileeṣẹ yi kan loju ọna Atani Osamale nijọba ibilẹ Ogbaru.
Wọn ṣina bo ọkọ wọn ti wọn si pa eeyan mẹrin. Awọn mii farapa.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra fi idi iṣẹlẹ yi mulẹ bẹẹ si ni wọn sọ pe awọn alaburu yi dana sun oku awọn ti wọn yinbọn pa ati awọn ọkọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaburu tun ji ọlọpaa gbe
DSP Ikenga Tochukwu alukoro ọlọpaa Anambra to fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ yi sọ afikun pe awọn agbebọn yi tun ji ẹsọ ọlọpaa meji to wa lara ikọ yi ati awakọ ọkan lara awọn ọkọ naa gbe salọ.
Tochukwu sọ pe oun abamọ ni pe iru ikọ bayii wọ ipinlẹ Anambra lae jẹ ki awọn agbofinro mọ.
Ṣugbọn o ni awọn ''ikọ alaabo Joint Security Forces ti bẹrẹ iwadii lati ṣawari awọn ti wọn wa nidi iṣẹlẹ yi ati ki wọn si doola awọn ti wọn jigbe''
Njẹ wọn pa ọmọ Amẹrika ninu ikọlu yii?
Ibeere yi ni ọpọ n beere lati igba ti iroyin iṣẹlẹ naa ti lu sori afẹfẹ.
Amọ akọroyin BBC to kan si olu ileeṣẹ Amẹrika to wa ni Naijiria gbọ esi to ṣalaye pe lootọ ni wọn ṣe ikọlu sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yi.
Atẹjade kan ti wọn fi ranṣẹ ni idahun si ibeere BBC sọ pe''A fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni ikọlu waye ni Anambra lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kaarun.Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria ati awọn agbofinro jijọ n ṣe iwadii papọ''
O tẹsiwaju pe awọn ko fi ọrọ aabo awọn oṣiṣẹ awọn ṣere rara.
''Bẹẹ la si maa n ṣe ipalẹmọ to munadoko ki a to jade irinajo''
Atẹjade naa pari pẹlu gbolohun ti ko sọ boya awọn ọmọ Amẹrika tabi ọmọ Naijiria ni oṣiṣẹ wọn to padanu ẹmi wọn.
''A ko ni ọrọ afikun mii mọ lasiko taa wa yi''
Ki ni ikọlu yi tunmọ si fọrọ awọn agbebọn agbegbe yi?
Kii ṣe igba akọkọ ree tawọn agbegbọn ilẹ Igbo a maa ṣoro bi agbọn.
Amọ igba akọkọ ree ti wọn yoo kọlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria.
Unknown Gunmen gẹgẹ bi orukọ ti wọn n pe wọn a maa ko ipaya ba araalu bẹẹ si ni wọn a maa hu iwa jandukyu to mọ ipaniyan ati ijinigbe.
O ti ṣe diẹ ti ijọba Naijiria ti n koju awọn janduku wọnyi ti ko jẹ ki omi alaafia toro lawọn ipinlẹ kan ni ilẹ Igbo.
Yala awọn ọmọ ikọ ajafẹtọ idasilẹ orileede Biafra taa mọ si IPOB tabi Unknown Gunmen ijọba Naijiria koro oju si ihuwasi wọn koda ijọba ti kede IPOB gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi.
Titi di asiko yi ko ti si eeyan kankan to jade pe awọn lo wa nidi ikọlu yi.
Ipenija kikoju awọn agbebọn yi yoo da lori aarẹ ti araalu dibo yan Bola Ahmed Tinubu nigbakigba to ba dori aleefa.
Yatọ si ipenija awọn ti ilẹ Igbo yii, yoo tun koju awọn janduku agbebọn ajinigbe to fi mọ awọn ikọ Boko Haram to n da omi alaafia ru lariwa Naijiria.
Lọjọ ikọlu yi la gbọ pe Antony Blinken to jẹ Minisita fọrọ ilẹ okere Amẹrika pe Tinubu lori ago.
Atẹjade ti agbẹnusọ Amẹrika fi sita sọ pe Blinken mẹnuba itẹsiwaju ajọṣepọ Naijiria ati Amẹrika.
O fi kun pe awọn yoo maa foju sọna nipa itẹsiwaju ajọsepọ tio gunrege lẹka ifọwọsowọpọ lori aabo ati awọn eto mii ti yoo mu agbega ba ọrọ aje.
Ko sọrọ nipa ikọlu to waye yi rara.












