Ọlọ́pàá pa olórí ikọ̀ adigunjalè, ọwọ́ tún tẹ oníṣòwò tó ń ra ẹrù olè lọ́wọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, ti pa Balogun ikọ̀ adigunjale ti wọn fura si pe o pa ọlọpaa kan niluu Ibadan láìpẹ́ yii.
Àwọn ọlọ́pàá tun mu afurasi mẹta mii.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá fun ipinlẹ Oyo, SP Adewale Osifeso, lo kede ìgbésẹ̀ naa fun àwọn akọ̀ròyìn, lasiko to fi oju àwọn afurasi naa han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleyele niluu Ibadan.
SP Osifeso salaye pe, àwọn afurasi adigunjale naa pa ASP Daniel Ogunleye, lasiko ti wọn yabo ile rẹ ni adugbo Odo-Ona Kekere, niluu Ibadan, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin.
Àwọn afurasí naa, to jẹ márùn-ún yabo agbegbe Orí-Agogo, Odo-Ona, ni bíi aago kan òru, ti wọn si ja ọpọlọpọ àwọn olùgbé ibẹ lólè.
Lara àwọn ti wọn ja lólè ni ASP Ogunleye wa.
"Àwọn afurasi naa pa Ogunleye lẹyin tí wọn ja oun ati ẹbí rẹ̀ lólè tan.
" Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii iwa ọ̀daràn, SCID, ni Iyaganku, ni Daniel ti n ṣiṣẹ́ saaju iku rẹ."
Bákan naa lo ni foonu ti ẹnikan lara àwọn afurasi ọ̀hún gbagbe si ibi ti wọn ti jale, lo ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ wọn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ pe ọwọ́ tun tẹ oníṣègùn ibilẹ to n tọju wọn.
" Lasiko ti wọn doju ìjà kọ awọn ọlọpaa ni ibùba wọn, ni ìbọn pa olori wọn.
Ọwọ́ tun tẹ obinrin oníṣòwò tó ma n ra àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ara lọwọ wọn.
Èèyàn méje dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pé wọ́n lu Ọlọ́pàá pa n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, others
Awọn ọkunrin meje ti wọn fi ẹsun kan wi pe wọn lu ọlọpaa kan, Insipẹktọ Augustine Okoro titi ti ẹmi fi bọ lọrun rẹ ni ibudo ọlọpaa to n bẹ ni opopona Iṣẹyin, ni agbegbe Mọniya niluu Ibadan ti foju ba ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun.
Awọn afurasi naa ni: Sarafa Lateef (ẹni ọgbọn ọdun), Saminu Ibrahim (ẹni ọdun mejidinlọgbọn), Oloso Sikiru (ẹni ọdun mẹrindinlogoji), Fatai Yusuf (ẹni ọdun marundinlaadọta), Moruf Olanrewaju (ẹni ọdun mejilelogoji), Isiaka Rafiu (ẹni ogoji ọun), ati Anuoluwa Akinola (ẹni ọdun mejilelọgbọn).
Agbefọba, ASP Amos Adewale sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn ẹni afẹsun kan naa gbimọ pọ lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹrin ni opopona Iṣẹyin ni agbegbe Mọniya Ilu Ibadan, ti wọn si ṣe iku pa Insipẹktọ Augustine Okoro, ẹni ọdun mẹtalelogoji.
Adewale fi kun ọrọ rẹ pe awọn ẹni afẹsun kan naa lu Okoro, wọn si sọ oko paa lẹnu iṣe ni agbegbe naa.
O ni itapasofin yii tako ofin iwa ọdaran ti ọdun 2000 n'ipinlẹ Ọyọ.
Adajọ agba ile ẹjọ Magistreeti, E. A. Idowu ti ile ẹjọ Magistreeti Iyaganku ti o kọ lati tẹwọ gba ẹbẹ awọn ẹni afẹsun kan naa lo pa aṣẹ pe ki wọn sọ wọn si atimọlẹ ni ọgba ẹwọn Agodi.
Adajọ naa tọka ẹjọ naa si ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si iwa ọdaran fun amọran gẹgẹ bi o ṣe sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa, oṣu keje.















