Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun tẹ géndé méjì tó jí ewúrẹ́ 15 gbé ní Osogbo, Ikirun àti Ila Orangun

Osun goat thieves

Oríṣun àwòrán, Yemisi Opalola

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fi ṣikun ofin mu afurasi meji kan lori ẹsun pe wọn ji ewurẹ marundinlo gun kaakiri ipinlẹ naa gbe.

Yatọ si awọn ewurẹ ti wọn ji, ọlọpaa tun sọ pe awọn afurasi ọhun, Naheem Segun ati Suraju Isiaka, ji ọkọ ayọkẹlẹ Lexus RX 300 kan.

Alukoro ileeṣẹ ọhun, Yemisi Opalola, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọroyin niluu Osogbo.

Opalola ni nnkan bii aago mẹta oru kọja iṣẹju mẹwaa ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko ti awọn akọṣẹmọsẹ ikọ Safer Highway Patrol mu wọn loju ọna Odeomu si Sekona.

O ni “Nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju mẹwaa oru ni ikọ Safer Highway Patrol mu wọn loju ọna Odeomu si Sekona pẹlu ewurẹ mẹrinlelogun ati oku ewurẹ kan.”

“Ninu iwadii, wọn jẹwọ pe kaakiri ilu Osogbo, Ikirun ati Ila Orangun lawọn ti ji awọn ewurẹ naa.”

“Wọn ṣalaye pe obinrin kan ti wọn n pe ni Iya Bisola lawọn fẹ lọ ta awọn ewurẹ na fun lagbege Mile-12, niluu Eko.”

“Wọn tun sọ siwaju si pe lati ọdun 2019 lawọn ti n ṣọṣẹ nipinlẹ Osun.”

“Wọn ṣalaye pe aarin aago mẹjọ si Mẹwaa alẹ lawọn maa n ṣọṣẹ ki awọn ọlọdẹ adugbo to bẹrẹ iṣẹ wọn.”

Ẹwẹ, Opalola ti wa kede pe ki awọn ti ewurẹ wọn ba di awati lagbegbe Osogbo, Ikirun, Obagun, Iree, Eripa, Otan-Ayegbaju ati Ila laarin ọjọ kẹsan an si ọjọ kẹwaa, oṣu ti a wa yii ṣabẹwo si olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Osogbo lati wa gba ewurẹ wọn pẹlu ami idanimọ.