'Ọmọ mẹ́tàlá tí mo bí ni àgbàrá òjò gbé lọ'

Arakunrin Tulinabo Lumumba ti salaye bi ibanujẹ ṣe gba ọkan r, lẹyin to padanu gbogbo ọmọ mẹtala to bi sinu iṣẹlẹ omiyale to ṣọṣẹ ni orilẹede DR Congo.
Pẹlu ibanujẹ ọkan ni arakunrin naa fi sun si ilẹ lori ẹni nibi to ti sọ iriri rẹ fun BBC Yoruba.
Ninu ọrọ rẹ baba to padanu awọn ọmọ rẹ mẹtala naa ni ‘’Ibanujẹ gba ọkan kan nitori gbogbo mọlẹbi mi lo ti padanu ẹmi wọn.’’
‘’Omi gbe ọmọ mi mẹtala lọ, emi ati iyawo mi loku si inu ibanujẹ.’’
Bakan naa ni wọn ko ri ounjẹ jẹ nitori agbara ojo naa ti ba gbogbo ere oko wọn jẹ.
‘’A ko ni ohunkohun lati jẹ, gbogbo ere oko wa ni to fi mọ ẹgẹ ni agbara ti hu lọ tiditidi.
Nigba ti Ọlọrun ti gba awọn ọmọ mi mẹtala bayii, oun ti mo n bẹbẹ fun ni ki n ri ile sun si, gbogbo rẹ ti su mi.”
Arabinrin Tumani Byanmungu to tun sọ iriri rẹ ni oun padanu ọmọ oun ninu iṣẹlẹ ojo arọrọda naa.
Arabinrin naa sapejuwe bi omi se gbe oun ati ọmọ ọwọ oun lọ.
‘’Mo ṣẹṣẹ de lati ọja ti mo si n ba awọn ọmọ mi ṣere, ti ọkan ninu wọn si n mu ọyan lọwọ.’’
Bẹẹ ni ojo bẹrẹ si ni rọ, sadede ni ogiri kan wopalẹ, ogiri miran tun wo le wa lori, ni agbara ba gbe gbogbo wa wọ inu odo. Bi mi o se ri awọn ọmọ mi mọ niyẹn.’’
Iroyin sọ pe ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni wọn ṣi n wa lẹyin ti ojo arọrọda to lagbara waye nibẹ, ti awọn odo si kun akunwọsilẹ.
Bakan naa ni eniyan to le ni irinwo ti ba iṣẹlẹ ojo aroroda ati ilẹ riri naa lọ ni agbegbe ila oorun DR Congo.
Abule meji, Bushushu ati Nyamukubi, to wa ni ẹgbẹ adagun odo Kivu, lo rì sinu omi patapata lẹyin ti awọn odò to wa ni ila oorun DR Congo kún kọja bèbè wọn.
Iroyin sọ pe o le ni ida mẹta ninu mẹrin ile, to wa ni awọn abule naa, ti omi gbe lọ patapata.
Iṣẹlẹ omiyale yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti iru rẹ ti kọkọ ṣẹlẹ ni awọn abule kan to wa ni odikeji adagun odo Kivu, ni orilẹ-ede Rwanda to mule ti DR Congo.
Eeyan 130 lo ku nibẹ.












