Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun pín 'tear gas' fún àwọn ọmọbìnrin nítorí ìfipábánilòpọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kọmisanna fun ọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ogun, Arabinrin Funmi Efuwape, ti sọrọ lori iroyin to n lọ lori ayelujara pe ijọba ipinlẹ Ogun, pin agolo afẹfẹ tajutaju, teargas fun awọn ọmọbinrin .
Owurọ Ọjọbọ ni iroyin naa jade ninu awọn iwe iroyin kan pe, ijọba ipinlẹ naa pin agolo tear gas fun igba ọmọbinrin nipinlẹ ọhun, lati daabo bo ara wọn lọwọ ifipabanilopọ.
Iroyin naa sọ pe oludari ẹka ironilagbara fun awọn obinrin, ni ileeṣẹ ijọba to wa fun ọrọ awọn obinrin, Arabinrin Wonuola Kazeem, lo kede igbesẹ naa.
O ni eyi jẹ ara igbesẹ ti awọn n gbe lati dẹkun ifipabanilopọ ni ipinlẹ Ogun, lẹyin ti iwadii fihan pe o wọpọ nibẹ.
Ṣugbọn ninu ọrọ to ba BBC sọ, kọmisanna fun ọrọ awọn obinrin ni ipinlẹ Ogun, Arabinrin Funmi Efuwape, sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.
O ni lootọ ni awọn n gbero lati ṣe awọn eto ironilagbara fun awọn ọmọ obinrin lati daabo bo wọn lọwọ awọn afipabanilopọ.
“Abẹle, laarin ara wa la ṣi ti n gbero rẹ, kii ṣe awọn nkan ti a ti ṣe.
“Idi ni pe oriṣiriṣi igbesẹ laṣi nilo lati gbe; ijiroro, idanilẹkọ fun awọn ọmọbinrin, ontẹ lati ọdọ gomina, ati erongba araalu.
"Koda, a ko tii ra awọn 'tear gas' ti wọn sọ pe a pin."
Bakan naa ni Arabinrin Efuwape sọ pe iru eto bẹẹ yoo fun awọn ọmọbinrin ni igboya lati sọrọ sita, nigbakuugba ti wọn ba koju ifipabanilopọ.












