Àwọn èèyàn má n pè mí ní Ẹbọra, Amotekun àti Ọ̀wàwà nítorí bí àwọ̀ ara mi ṣe rí - Oluwatosin Ojetola
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
"Mo fẹ sọ fun awọn to ni iru awọ ara mi yii pe kii ṣe nnkan buburu, ẹ o ki n ṣe ẹbọra, ọmọ ni ẹyin naa".
Ọdọlangba ṣi ni Oluwatosin Ojetola jẹ amọ ohun toju rẹ ti ri ti ju ọjọ ori rẹ lọ. Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba, ohun ati iya rẹ kẹnu bọ ọrọ lori ohun toju wọn ri lawujọ nitori iru awọ ara to ni.

Bi awọ ara rẹ ṣe ri nigba ti wọn bii kọ niyi. Iya rẹ ṣalaye fun BBc Yoruba pe: "O jẹ ọmọ to sanra lati kekere... to ba ni alefo, o maa tu, yoo wa di awọ mii lara rẹ, bo ṣe bẹrẹ diẹ diẹ niyẹn titi to fi bo gbogbo ara rẹ bayii".
Bakan naa ni Iya rẹ sọ pe bi oun ba gbe e jade ninu ọkọ awọn mii a maa sọ oniruuru ọrọ.

"Ẹlomiran a ni ki lode ti ẹ n fun un ni iyọ jẹ, ki lode ti ẹ o lo ogun alefọ fun un".
O de ipo kan ti iya rẹ ni oun woye pe ọmọ oun ti n fi ọrọ pamọ fun un. nigba to tẹẹ ninu to sọ ohun toju rẹ ti n ri, o bu sẹkun gidi gan.
"Laarin ero, wọn maa n sọ pe Ẹbọra ni mi tabi Amọtẹkun, o maa n dun mi gan amọ ..."

Oluwatosin ṣalaye pe laarin awọn eeyan pupọ, ọpọ igba ni ohun ti ni ibanujẹ tori oniruuru orukọ ti wọn maa n pe oun bii "Ẹbọra, Amọtẹkun, Ọwawa".
"Mo bẹrẹ si ni sọkun, ni irẹwẹsi ọkan nigba ti awọn ọrẹ mi n sa fun mi nile ẹkọ".
Oluwatosin ni ti pe ọmọ ọdun mẹrinla bayii amọ nnkan toju rẹ ri ti kọja iye ọjọ ori rẹ.




