Tuwo ni mo kọ́kọ́ jẹ lẹ́yìn tí ogun lé mi dé láti Sudan

Fatima Sanusi Musa, ẹni to jẹ ọmọ ile ẹkọ fasiti apapọ ilẹ adulawọ to wa ni orilẹede Sudan sọ iriri rẹ fun ileeṣẹ BBC lẹyin to pada de sọdọ awọn mọlẹbi rẹ niluu Kano lọjọ Ajẹ.
Akẹkọọ ọhun to wa ni ipele kẹrin ni fasiti naa wa lara awọn akẹkọọ ti ijọba gbe kuro lorilẹede Sudan lọ si Egypt ki wọn to de si orilẹede Naijiria lẹyin ti ogun bẹ silẹ lorilẹede Sudan.
“Omi je bọ loju mi nigba ti mo ri awọn mọlẹbi nitori ka n mo ku si orilẹede Sudan ni, ki a ba ma wi bayii.”
O ni kete ti awọn de si ile ni oun kọkọ bere fun ounjẹ ti oun nifẹ julọ, ti oun si ti safẹri rẹ pupọ.
“Tuwo ni ounjẹ ti mo kọkọ bere fun nitori mo safẹri rẹ gan.”
Fatima ni oun ko fẹ pada nitori ọdun kan loku fun oun lati pari ẹkọ rẹ.
“Ni bayii, pipada si Sudan ko si ni ọkan mi rara ayafi ti gbogbo nnkan ba walẹ.
“Ni Khartoum ti ile awón akẹkọọ wa sumọ ibudo awọn ọmọ ologun, eyi jẹ ki ẹru ma ba wa pupọ.
“O ni igba kan ti awọn ọmọ ologun kan wọle ti wa, ti wọn si ni ki a doju bole, ti wọn naa ibọn si wa pe awọn yoo sina bolẹ
Ti Ogun Sudan ko ba pari, ma mu ọmọ mi kuro- Baba Fatima

Baba Fatima, Sanusi Musa naa sọ bi inu rẹ se dun pe o ri ọmọ rẹ , to si pada si Kano, ti wọn si n se suuru lati wo bi nnkan yoo se lọ lori ọrọ ogun Sudan.
“Ni bayi, a ni lati se suuru wo ibi ti ọrọ naaa yo yọri si, boya wọn yoo pe awọn akẹkọọ pada nigba to jẹ pe ọdun kan lo ku fun lati pari ẹkọ rẹ.”
“Sugbọn bi ogun yii ba tẹsiwaju, ma bere fun awọn esi idanwo ọmọ mi, eyi ti yoio fun anfani lati tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ lorilẹede Naijiria.
Baba ọhun ni o nira fun oun ati Iya Fatima lati sun lasiko ti ọmọ wọn si wa ni orilẹede Sudan.
“Lẹyin igba ti a ba sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ, o salaye oun ti awọn lakọja, o ni nira fun wa gan nitori ironu rẹ gba ọkan wa gan an.
“Nigba to de, inu mi dun, ayo mi tun kun.”















