10th NASS: Kà nípa ìlànà tí wọ́n fí n yan àwọn aṣáájú ilé aṣòfin ní Nàìjíríà

Aworan ijoko ile aṣofin agba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Tope Brown

O ṣeeṣe ki ẹ ti maa ka awuyewuye nipa yiyan awọn ti yoo dije ipo aṣsaju nile aṣofin Naijiria.

Eyi kii ṣe ohun tuntun lagbo oṣelu paapa bi awọn aṣofin orileede Naijiria mi ṣe n gbaradi lati bẹrẹ saa wọn.

Ninu oṣu kẹfa ọdun 2023 ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ ile aṣofin tuntun ni Naijiria.

Eleyi ni yoo jẹ ile ikẹwaa lati igba ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa.

Ni Naijiria, ile meji lo parapọ taa n pe ni ile aṣofin. Ile Aṣojuṣofin ati ile aṣofin agba.

Aṣoju 360 lo wa nile aṣojuṣofin nigba to si jẹ pe awọn 109 lo wa nile aṣofin agba.

Awọn aṣoju yi tawọn eeyan wọn dibo yan lati ipinlẹ ati ẹkun idibo ni yoo parapọ yan awọn ti yoo dari eto ile ni saa tuntun yi.

Awọn ti ile aṣjouṣfin yoo yan olori wọn ti awọn ti ile asofin agba naa yoo yan ẹni ti wọn fẹ.

Bi wọn ṣe n gba a yan awọn adari ile

Lọjọ tawọn aṣofin ba kọkọ wọle,wọn yoo parapọ lati ṣe iburawọle sipo.

Ninu alakalẹ, awọn to ba n pada sile gẹgẹ bi aṣofin ni igbalaye wa fun lati kọkọ dije dupo aṣaaju tabi adari ile.

Ko tunmọ si pe awọn aṣofin to n wọle ni igba akọkọ naa ko le du ipo.

Lẹyin igba naa, aṣoju le fi orukọ ẹnikẹni to ba fẹ ko dije ipo aarẹ sọwọ si ile.

Ti awọn to ba n du ipo yi ba pọ, akọwe ile yoo ṣeto idibo.

Asoju to ba ni ibo to pọ julọ ni wọn yoo kede pe o jaweolubori,

Ipo awọn olori ile gangan leleyi tawọn aṣofin maa n foju si lara pupọ.

Idi ni pe ẹni ba jẹ aarẹ ile aṣofin agba tabi olori ile aṣojuṣofin ni yoo ṣe atọna iru ibaṣepọ ti yoo wa laarin ile ati awọn ẹka ijọba to n pa aṣẹ.

Awọn ipo miran mi naa wa yatọ si awọn eyi ti oju maa n wa lara wọn ta darukọ ṣaaju.

Awọn ipo mii yatọ si ti aarẹ ati olori ile aṣojuṣofin

  • Igbakeji aarẹ ile aṣofin agba
  • Igbakeji olori ile aṣojuṣofin
  • Olori ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile
  • Igbakeji ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile
  • Olori ọmọ ẹgbẹ to kere julọ nile
  • Igbakeji olori ọmọ ẹgbẹ to kere julọ ni ile
  • Akojanu ile
  • Igbakeji akojanu ile
  • Akojanu fawọn ọmọ ẹgbẹ to kere julọ
  • Igbakeji fun akojanu awọn ọmọ ẹgbẹ to kere julọ.