Nnamdi Kanu kò lè kú sí àtìmọ́lé – Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe tún sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ sí Òṣù Kẹ́sàn-án

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti sun igbẹjọ adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu siwaju.

Ile ẹjọ kede isunsiwaju yii lẹyin ti agbẹjọro ijọba A. Gazali tako igbẹjọ ẹsun meji to wa niwaju wọn, ekini ni lati gba beeli rẹ, ekeji si ni gbe e kuro ni ahamọ DSS lọ si ọgba ẹwọn Kuje ni Abuja nitoripe ko tii fi idahun rẹ ranṣẹ.

Agbẹjọro ijọba, A. Gazali rọ ile ẹjọ klati fun un di ọjọ Ẹti ọjọ Kejila Oṣu Karun, ọdun 2023.

Agbẹjọro Nnamdi Kanu naa, Mike Ozekhome sọ fun ile ẹjọ pe oun ti ti ṣetan fun ile ẹjọ fun igbẹjọ naa to si sọ fun adajọ pe ki wọn fun wọn deeti to sunmọ ju nitoripe ipo ti Nnamdi Kanu wa ni ahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ko dara rara.

“Oluwa mi, Nnamdi Kanu n ṣaisan, wn si ti buwọlu iwe to yẹ ko lọ fi ṣe iṣẹ abẹ ṣugbọn awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ ko jẹ ko jade.

A n bẹbẹ pe ki wọn jẹ ka gbe e kuro ni ahamọ DSS lọ si ọgba ẹwọn Kuje ko le baa ri iwosan gba bii awọn to ku, ẹru si n ba mi ko ma baa ku sọwọ awọn DSS nitoripe wọn o ṣaa ki n da ẹjọ fun oku”. Ozekhome to fẹrẹẹ bu sẹkun sọ eyi bo ṣe n bẹ ile ẹjọ."namdi

Ki ni esi adajọ lori ilera Nnamdi Kanu?

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Amọ lẹyin ti awọn adajọ wo ilana ti wọn ni silẹ, wọn sọ pe ko si akoko mii fun awọn ayafi ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹrinla Oṣu Kẹsan, ọdun 2023.

“Ile ẹjọ yii ni ọpọlọpọ iṣẹ niwaju, ọpọlọpọ ẹsun nipa eto idibo to si ni akoko tirẹ taa gbudọ ṣe e. Bẹẹ si ni aadọrun ọjọ pere ni a ni lati kede idajọ”.

Ile ẹjọ ṣalaye pe awọn n lọ fun isinmi awọn si ti sun igbẹjọ Nnamdi Kanu di ọjọ Kẹrinla Oṣu Kẹsan.

Wọn ohun ni awn yoo kọkọ gbọ bi awọn ba ṣe n wọle isinmi bẹẹ si ni gbogbo ẹsun ọhun lawọn yoo gbọ lọjọ kan naa.

“Kanu ko ni ku si ahamọ, ọlọrun yoo da abo bo o ko le wa laaye bẹẹ si ni ẹjẹ rẹ ko ni wa lọwọ rẹ”, ile ẹjọ sọ fun Osekhome.

But di Supreme Court Judges afta dem look into dia schedule, tok say time no dey for dem until 14 September, 2023.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ile ẹjọ kotẹmilọrun ni Abuja ti kọkọ da Nnamdi Kanu lare awọn ẹsun naa ti wọn si ni ko ba ofin mu bi wọn ṣi ṣe n ti i mọle tabi tẹsiwaju ninu igbẹjọ rẹ.

Ijọba lo lọ si ile ẹjọ kan naa nibi ti wọn ti gba aṣẹ ti wọn pe ni “Stay of Execution” eyi ti yoo jẹ ki wọn ṣi maa ti Nnamdi Kanu mọle titi ti ile ẹjọ giga yoo ṣe gbọ ẹjọ naa.