Àwọn òṣèré tíátà tó lọ́ ń fi arúgbó ara kàwé síì, ohun tí wọn yóò mú bá agbo sinimá nìyí – Tunde Kelani

Àkọlé fídíò, Tunde Kelani: Àwọn òṣèré tíátà tó lọ́ ń fi arúgbó ara kàwé síì, ohun tí yóò mú bá agbo sin

"Kí n tó ṣe fíìmù nígbà míì, ó le tó bíi ọdún méjì tí màá ti máa ṣewàdìí nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe".

Agba ọjẹ ninu iṣẹ yiya sinima lede Yoruba ati Gẹẹsi yii mu wa rirnirinajo lọ si aye atijọ ti ko tii si ọlaju.

“Lode oni, pẹlu foonu lọwọ, ko si nnkan teeyan o le wo kaakiri agbaye”.

Tunde Kelani
Tunde Kelani

O sọrọ nipa alebu ati anfani ti awọn nnkan igbalode ti mu ba yiya sinima paapaa anfani ibẹ lo sọ ju lati fibẹẹ tabuku imọ ẹrọ igbalode.

O ni bi gbogbo nnkan ba ṣe ri, tibi tire naa ni amọ o gba a ladura pe ire ibẹ ni ko maa ba wa.

TK Opomulero tun fi idunu rẹ han si bi awọn oṣere fiimu Yoruba ṣe n lọ si ile ẹkọ sii.

Agba adari ere naa ni anfani nla ni yoo mu ba iṣẹ fiimu ṣiṣe ni Naijiria.